Nitori owo ina ijọba to gbẹnu soke, awọn araalu fẹhonu han ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Latari bi ileeṣẹ to n pin ina ka (Ibadan Electricity), ṣe fowo kun owo ina oṣu kẹwaa, nipinlẹ Kwara, awọn onibaara niluu Ilọrin, fẹhonu han, wọn ni owo naa ti fẹẹ ju agbara awọn lọ.

Niṣe ni awọn onibaara ọhun ya bo agbegbe Muritala, niluu Ilọrin, ti wọn si n pe fun ki wọn din owo naa ku tori pe ina ti wọn n mu wa ko yatọ si tatẹyinwa, ki waa lo mu ki owo gbẹnu soke si i. Awọn onibaara ọhun sọ pe iye ti wọn n san lowo ina losoosu ni naiara mejidinlaaadọta ati kọbọ mọkandinlogoji (N58.39k), ṣugbọn ni osu kẹwaa yii, o ti fo fẹrẹ si ọgọta naira ati naira mọkandinlogoji (60.39k), ti ina ọhun si fi bẹẹ duro ire. Iwadii fi han pe ni awọn ipinlẹ bii Ọsun, Ọyọ, Ogun, Ekiti ati bẹẹ bẹẹ lọ, ni ileesẹ apinaka IBEDC ti fi kun idiyele owo wọn.

Ọkan lara awọn onibaara to ba awọn oniroyin sọrọ lorukọ awọn ẹlẹgbẹ wọn, Arabinrin Aisat Bello, bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa pẹlu bi ileeṣẹ naa ṣe sadeede fi owo kun un lai fi to awọn onibaara leti tẹlẹ. Bello tẹsiwaju pe ileeṣẹ ọhun ko wo ipo ti eto ọrọ aje de duro bayii, wọn kan ṣa a fowo kun ina ni tiwọn ni. O wa pe fun iwadii to nipọn lori bi wọn ṣe fowo kun un lai sọ fun awọn onibara.

Leave a Reply