Monisọla Saka
Lati mu ki irọrun de ba awọn araalu, paapaa ju lọ awọn oṣiṣẹ ijọba, pẹlu bi gbogbo nnkan ṣe gbowo lori nitori owo iranwọ epo ti wọn yọ, Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki, ti ṣafikun owo-oṣu awọn oṣiṣẹ to kere ju lọ, bẹẹ lo tun din iye ọjọ ti wọn yoo fi maa wa sibi iṣẹ ku.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni Obaseki fi atẹjade yii lede fawọn oniroyin.
Ni bayii, owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju lọ tijọba ilẹ Naijiria fọwọ si, ti wọn si n lo, to jẹ ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira (30,000), ni Ọbaseki ti fi ẹgbẹrun mẹwaa kun, to ni lati ipinlẹ oun, ogoji ẹgbẹrun (40,000), ni oṣiṣẹ to n gbowo to kere ju lọ yoo maa gba.
Bakan naa lo tun din ọjọ marun-un tawọn oṣiṣẹ fi n wa si ẹnu iṣẹ ku si ọjọ mẹta, nitori wahala owo mọto to n waye latari bi epo mọto ṣe ti wọn si i.
O waa ṣeleri pe ijọba oun yoo duro ti awọn oṣiṣẹ gbagbaagba lasiko ipenija yii.
Obaseki ni, “Gẹgẹ bii ijọba to n figba gbogbo ṣiṣẹ, a ti gbe igbesẹ bayii lati fi kun owo-oṣu awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Edo, lati ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira to wa nilẹ kaakiri ilẹ Naijiria, lọ si ogoji ẹgbẹrun.
‘‘Nilẹ toni to mọ yii, eyi ni yoo jẹ owo-oṣu oṣiṣẹ to pọ ju lọ ni Naijiria. Nitori idi eyi naa la ṣe din iye ọjọ tawọn oṣiṣẹ ijọba yoo fi maa wọ ọkọ lọ sibi iṣẹ wọn ku, lati ọjọ marun-un si mẹta lọsẹ, titi a oo tun fi ṣe ikede mi-in. Lati ile lawọn oṣiṣẹ yoo ti maa ṣiṣẹ bayii fawọn ọjọ meji yooku.
“Pẹlu bijọba apapọ ṣe yọwo iranwọ ori epo, epo ti gbowo lori gegere, gbogbo nnkan lo si ti di ọwọngogo, eyi to n mu ki igbe-aye awọn eeyan fẹẹ maa nira.
Ijọba ipinlẹ Edo n ba yin jẹ ninu irora yin, a si fi n da awọn eeyan loju pe a wa pẹlu yin lasiko ti nnkan le yii.
“A mọ pe inira ti owo iranwọ yii ti fa ti ṣakoba fun owo mọto, teyii si n gbọn owo-oṣu awọn oṣiṣẹ lọ. Fun tawọn olukọ atawọn obi ọmọleewe, ọkọ wiwọ tiwọn naa lọ sileewe yoo dinku, bẹẹ la si ti n ṣiṣẹ lori eto ẹkọ ayelujara ta a pe ni EdoBEST@Home Initiative, ti i ṣe kilaasi ori afẹfẹ, ti yoo si din owo tawọn obi, olukọ atawọn ọmọleewe yoo maa na lori mọto wiwọ ku. Laipẹ rara lawọn ileeṣẹ eto ẹkọ nipinlẹ Edo, Edo SUBEB, yoo fi atẹjade sita lẹkun-un-rẹrẹ lori eyi”.