Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Fatai Salami, pa ara ẹ si ileeṣẹ ajọ TRACE to n ri si lilọ-bibọ ọkọ nipinlẹ Ogun, lanaa ode yii ti i ṣe Mọnde, ogunjọ oṣu keje.
Oogun aṣekupani Sniper lo da mu lọdọ awọn ajọ naa, nitori mọto rẹ ti wọn mu ti ko si ri owo itanran ti wọn ni ko san ko kalẹ.
Ẹgbẹrun lọna igba ati mẹẹẹdogun (N215,000) la gbọ pe ajọ TRACE ni ki Fatai san lati fi gba tirela rẹ ti wọn mu l’Ọjọbọ ọsẹ to kọja, ohun ti wọn tori ẹ mu mọto naa ni ofin Korona ti wọn lo ru. Wọn ni awakọ to wa tirela ọhun lọjọ naa ko lo ibomu, o si tun tapa sawọn ofin mi-in to de Korona.
Eyi la gbọ pe wọn ṣe da mọto naa duro si olu ileeṣẹ wọn to wa ni Ibara Housing Estate, l’Abẹokuta.
A tilẹ gbọ pe Salami ti n bẹ awọn ẹṣọ naa titi pe ki wọn jẹ koun maa gbe mọto oun lọ, ṣugbọn wọn ko gba. Ẹyin igba naa ni wọn lo bẹrẹ si i sọ fun wọn pe bi wọn ko ba jẹ koun maa gbe ọkọ loun lọ lẹrọ, oun yoo pa ara oun si wọn lọrun ni.
Ojiji ni wọn lo mu kinni ọhun jade lapo ẹ, lo ba da a sẹnu, aṣe Sniper ni. Bo ti mu un tan lo bẹrẹ si i japoro, gbogbo igbiyanju TRACE lati doola rẹ ko si bọ si i.
Ṣugbọn Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, sọ pe Fatai ki i ṣe dẹrẹba, bẹẹ ni ko ni mọto. O ni ọkunrin naa kan waa jokoo silẹẹlẹ ninu ọgba awọn ni. O ni ọga awọn lo ri i nilẹẹlẹ to si ni ko dide, igba naa lo si mu kinni kan jade lapo ẹ to n rọ ọ sẹnu, nigba tawọn yoo si sun mọ ọn lawọn ri i pe Sniper ni.
Akinbiyi sọ pe awọn pada mọ pe maneja lọkunrin naa lọdọ ẹnikan to ni mọto pupọ, o ni ọkan ninu awọn ọkọ to n mojuto naa lo ṣẹ ti ajọ awọn si fofin de e.
Ṣugbọn ohun to ṣaa foju han ni pe Fatai Salami gbe majele jẹ lọgba awọn TRACE l’Abẹokuta.