Nitori owo Korona, awọn aṣofin fiwe pe kọmiṣanna meji l’Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Awọn aṣofin Ogun, labẹ akoso abẹnugan Taiwo Ọlakunle Oluọmọ, ti ranṣẹ pe awọn kọmiṣanna meji, Ọgbẹni Dapọ Okubadejọ to wa fun eto iṣuna atl Dokita Tomi Coker to n ṣakoso eto ilera nipinlẹ yii lati waa ṣalaye iye owo to wọle sapo ijọba ipinlẹ Ogun lasiko Korona ati bi wọn ṣe na an.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinlelogun, ti ile naa jokoo l’Oke Mosan, l’Abẹokuta, ni wọn sọ eyi di mimọ.

Wọn ni to ba di lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an yii, kawọn mejeeji yọju laago mọkanla aabọ aarọ lati waa ṣalaye lori awọn owo to wọle nígbà Korona ati bi wọn ṣe na an.

Gẹgẹ bi abẹnugan ile-igbimọ yii, Oluọmọ, ṣe wi, pipe ti ile n pe awọn kọmiṣanna meji yii wa ni ibamu pẹlu biliọnu meji aabọ (2.5b), owo iranwọ ijọba apapọ ti ijọba ipinlẹ yii n beere fun. Wọn ni awọn n fẹ alaye ati akoyawo lori owo Koro to ti wọle, ko too di pe ile yoo buwọ lu owo iranwọ asiko yii, eyi ti wọn ni wọn fẹẹ lo lẹka ilera ipinlẹ yii, fun ilera kikun to peye.

Tẹ o ba gbagbe, ṣáájú ni ijọba Gomina Dapọ Abiọdun ti gbe iwe lọ sọdọ awọn aṣofin lati buwọ lu biliọnu meji aabọ owo iranwọ ijọba apapọ ti banki agba ilẹ wa n ṣagbatẹru ẹ lọ́wọ́lọ́wọ́, ti wọn ni kile yẹ ẹ wo, ki wọn fọwọ si i ki eto ìlera ipinlẹ Ogun le dara si i.

Alaye awọn kọmiṣanna iṣuna ati ilera lori owo Korona yii yoo si ṣatọna lori ti ijọba apapọ to n lọ lọwọ.

Leave a Reply