Nitori owo olowo ti wọn ji mọ ọn lọwọ, Abraham binu bẹ somi n’Ilọrin

Aderohunmu Kazeem

Ọpẹlọpẹ awọn eeyan ti wọn ri baba agbalagba kan, Abraham Ọlayinka, nigba to binu bẹ s’odo n’Ilọrin, ti wọn ko jẹ ki omi odo Asa gbe e lọ patapata.

Ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin ni wọn pe ọkunrin to feẹ tori ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira para ẹ danu n’Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe agbegbe Abdul-Wahab Fọlawiyọ, ni Unity Road, niluu Ilọrin, niṣẹlẹ ọhun ti waye.

Wọn ni nibi ti baba naa ti n wọtun-wosi ko too bẹ sodo lawọn obinrin kan ti ri i, tawọn yẹn si fariwo bọnu nigba ti wọn ri i pe ṣe ni Abaham mọ-ọn-mọ fẹẹ para ẹ danu.

Ọkunrin ọlọkada kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Mohammed Abubakar ni wọn lo gbe baba naa jade. A gbọ pe loju ẹsẹ ni wọn ti pe awọn panapana, ti wọn si gbiyanju titi lati mọ ohun to mu un bẹ sodo, ṣugbọn to kọ lati sọ ohunkohun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ panapana, Adekunle Haasan, sọ pe bi wọn ṣe yọ ọ tan ni wọn ti gbe e lọ si ọsibitu kan, nibi ti ara ẹ ti balẹ daadaa.

Ṣa o, awọn araadugbo baba naa lo sọ fawọn onIroyin pe awọn eeyan kan ni wọn ja baba naa lole ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira.

Wọn ni owo yẹn gan-an lo ko ironu ba a, nitori oun kọ lo ni in, ọrẹ ẹ kan lo ni in, ibanujẹ owo naa lo si fẹẹ mu un gbẹmi ara ẹ.

Leave a Reply