Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ iwadii lori ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin oniṣowo kan, Kelechukwu Onuka, pe o lu iyawo rẹ, Nnena Kelechukwu, pa nitori Miliọnu mẹwaa Naira.
Onuka ni wọn lo fi ibinu lu iyawo rẹ pa nile wọn to wa laduugbo Aratusin, Oke Aro, l’Akurẹ, lọsẹ to kọja lori ẹsun pe ko sọ foun nipa owo ti ẹgbọn rẹ kan to wa niluu Oyinbo fi ransẹ si i lati ba a fi kọle si ilu abinibi wọn nilẹ Ibo.
ALAROYE gbọ, iṣẹ okoowo kan naa ni Onuka ati iyawo rẹ n ṣe, ti wọn si ni ṣọọbu nla kan sinu Ọja Ọba to wa l’Akurẹ, nibi ti wọn ti n ta awọn ohun eelo iṣaralọsọọ.
Ọrọ pe iyawo rẹ ko sọ fun un pe wọn kowo kan fun un lati fi ba wọn kọle lo bi ọkunrin ẹni ọdun mejilelogoji ọhun ninu to bẹẹ gẹ to jẹ ni kete to hu ọrọ owo naa gbọ lati ita lo lọọ ba iyawo rẹ nile pẹlu ibinu, to si gbeja nla ko o loju.
Asiko ti tọkọ-taya naa jọ n gba ọrọ ọhun bii ẹni gba igba oti laarin ara wọn ni Onuka fi ibinu fọ nnkan mọ obinrin naa lori, eyi to ran abilekọ yii sọrun ọsan gangan.
Ẹnikan to sun mọ tọkọ-tiyawo ọhun pẹkipẹki, Ọgbẹni Chukuka Obinna, sọ fun akọroyin wa pe kayeefi patapata ni iṣẹlẹ naa ṣi n jẹ foun nitori pe oniwatutu loun mọ Nnuka si lati bii ọdun mẹjọ ti oun ti mọ oun ati ọkọ rẹ.
O ni loootọ lawọn mejeeji maa n ja, ṣugbọn awọn funra wọn naa ni wọn saaba maa n pari rẹ laarin ara wọn. Igba kan wa to ni Onuka lu iyawo rẹ daku, to si jẹ pe oun wa lara awọn ti ọkunrin naa bẹ lati ba a sare gbe e lọ si ọsibitu.
Obinna ni gbogbo awọn ti awọn wa nitosi lawọn n gbọ ariwo kikankikan lati inu ile ti tọkọ-tiyawo ọhun n gbe, ṣugbọn lojiji lariwo naa dakẹ, ti ko si tun ṣeni to gbọ ohunkohun mọ. Eyi lawọn fi ro pe wọn ti yanju aawọ naa laarin ara wọn niyẹn.
O ni ori ibi ti ọkunrin oniṣowo ọhun ti n gbiyanju ati ji iyawo rẹ dide nibi to sun silẹ si lẹyin to ti fi ibinu la nnkan mọ ọn lori lawọn pada ba a nigba ti awọn wọle.
Ninu alaye ti aladuugbo mi-in, Abilekọ Grace Adebọwale ṣe fakọroyin wa loun naa ti fidi rẹ mulẹ pe gbogbo bi ariyanjiyan ṣe n waye laarin Nnuka ati ọkọ rẹ lawọn n gbọ, ti awọn si ro pe wọn ko ni i pẹẹ yanju rẹ funra wọn gẹgẹ bii iṣe awọn mejeeji ni, laimọ pe iku ni yoo pada ja si fun un.
O ni oloogbe ọhun ti figba kan waa ba oun lati ba oun wa agbasẹṣe to le ṣe agbatẹru ile ti ẹgbọn oun fowo rẹ ransẹ si oun lati ba oun kọ si ilu wọn.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, ni afurasi naa ti wa ni ikawọ awọn, awọn si ti n fi ọrọ wa a lẹnu wo.
O rọ gbogbo tọkọ-tiyawo lati wa ọna ati maa yanju ede aiyede to ba n waye laarin ara wọn lai mu wahala ati ipalara lọwọ.