Adewale Adeoye
Gbajumọ olorin taka-sufee nni, Tiwa Savage, ti sọ pe pẹlu bọrọ ọwọngogo epo bẹntiroolu ṣe tun gba ilu kan bayii, to si jẹ pe ko sẹnikankan to le sọ ni pato igba tabi akoko ti ọrọ naa yoo kasẹ nilẹ, o loun n pada sorileede Brazil, nibi toun ti wa lati ọjọ bii meloo kan sẹyin, nibi to ti lọọ fun ara rẹ nisinimi.
ALAROYE gbọ pe yatọ si tọrọ ọwọngogo epo bẹntiroolu to n bi i ninu yii, awọn ohun mi-in to tun n bi Tiwa Savage ninu nipa ọrọ orileede yii ni bi ki i ṣee si ina NEPA, to si jẹ pe ṣe lawọn eeyan maa n tan jẹnẹretọ nigba gbogbo.
Tiwa Savage ni, ‘Ko sigba ti mi o ni i pada silẹ Brazil nibi ti mo ti n bọ o, gbara ti aarẹ tuntun ti wọn yan sipo olori nilẹ wa ti kede pe ijọba oun yoo yọ owo iranwọ ori epo bẹnitiroolu ni awọn kan ti n lo ikede naa lati maa fi jẹ awọn araalu niya bayii, ọwọn gogo epo bẹntiroolu si ti yaa de niyẹn. Ko yẹ ko ri bẹẹ rara, aimọye idaamu ni awọn araalu yii n koju o, aisi epo bẹntiroolu wa lara rẹ, bẹẹ ni ko sina NEPA laarin ilu, inu okunkun lawọn araalu maa n wa, oju ọna wa paapaa ko daa rara, ojoojumọ si ni taya mọto maa n bajẹ nipasẹ ọna ti ko daa yii.
‘‘Ko sigba ti mi o ni i pada sibi ti mo ti n bọ, ko rọrun rara lati maa gbe niluu yii. Ko ju wakati kan pere lọ ti mo de si Naijiria, oju ọna wa ti ba taya ọkan lara mọto mi jẹ, nigba ti ikeji wa nileepo, nibi to ti n to lati ri epo bẹntiroolu ra. Mo n pada si Brazil, nibi ti mo ti n bọ.