Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Nitori pe wọn dara pọ mọ SWAGA, iyẹn ẹgbẹ to n ṣepolongo fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ẹgbẹ APC ipinlẹ Ekiti ti fi ọwọ osi juwe ile fun meji ninu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu wọn, Ọgbẹni Kayọde Adetifa ati Jide Ọṣọ, lati Wọọdu kẹsan-an laduugbo Owaye, niluu Ayede-Ekiti, nijọba ibilẹ Ọyẹ.
SWAGA lorukọ ẹgbẹ kan ti wọn da silẹ lati ṣe ipolongo fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lọdun 2023, ti wọn si ṣabẹwo sipinlẹ Ekiti laipẹ yii, ni pataki ju lọ, awọn ọmọ ẹgbẹ APC.
Ẹ oo ranti pe ahesọ kan ti n ja ranyin pe Gomina Kayọde Fayẹmi naa n gbero lero lati dije dupo aarẹ lọdun 2023 yii kan naa.
Ṣaaju ni ẹgbẹ naa ti kọkọ yọ alaga Wọọdu kẹjọ nijọba ibilẹ Ado-Ekiti, Ọgbẹni Clement Afọlabi, nipo lori ẹsun kan naa.
Iwe idaduro yii lo wa ninu lẹta meji ọtọọtọ ti Abejide Ṣọla, Alaga APC Wọọdu kẹjọ atawọn oloye ẹgbẹ mi-in buwọ lu.
Lẹta naa, ti wọn kọ lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun-un, ọdun yii, ka lapa kan pe: “A ri i ninu iṣe ati ihuwasi rẹ pe o n ṣiṣẹ ta ko ibaṣepọ ẹgbẹ wa, ni pataki ju lọ, nipinlẹ Ekiti, eyi to buru ju ni pe o da ẹgbẹ kan silẹ to o pe ni “SWAGA” laarin Wọọdu kẹsan ni ilu Ayede-Ekiti.
“Latari eyi, gbogbo igbimọ olori ati alaṣẹ wọọdu yii ti fọwọ si i lati juwe ọna ita fun ẹ ninu ẹgbẹ APC, tori pe o ṣiṣẹ ta ko ilọsiwaju ẹgbẹ wa.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Alukoro fun eto iroyin ẹgbẹ APC nipinlẹ Ekiti, Ọnarebu Ade Ajayi, sọ pe awọn meji naa ti ẹgbẹ le danu ṣẹ sofin ni, igbesẹ wọn si le fa iyapa ati ẹlẹyamẹya laarin ẹgbẹ naa. Ṣugbọn o ni ki i ṣe nitori SWAGA lawọn fi le wọn.