Oluṣẹyẹ Iyiade, Akure
Ijọba ipinlẹ Ondo ti kede ofin konilegbele oni wakati mẹrinlelogun latari rogbodiyan to n lọ lọwọ niluu Ikarẹ Akoko nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko.
Ikede yii waye ninu atẹjade ti kọmisanna feto iroyin nipinlẹ Ondo, Donald Ọjọgo, fi sita l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ta a wa yii.
Ofin yii lo ni ijọba ṣe lati tete fopin si ija ajakuakata tawọn araalu ohun n ba ara wọn ja lọwọ nitori ọrọ oye, o ni ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o tẹ ofin tuntun naa loju yoo ri pipọn oju ijọba.
Ọjọgo tun fi asiko naa sọ fawọn eeyan Ikarẹ pe ijọba ti gbẹsẹ le gbogbo akitiyan to ni i ṣe pẹlu ọrọ oye Olokoja, eyi ti wọn n tori rẹ ba ara wọn ja.
O ni ko sẹni to gbọdọ pe ara rẹ ni oloye mọ ninu awọn mejeeji to n du kinni ọhun mọ ara wọn lọwọ.
A fidi rẹ mulẹ ninu iwadii ta a ṣe ni pe Ọwa Ale tilu Ikarẹ Akoko ti kọkọ fi Idowu Ogunye jẹ oye Olokoja ki Olukarẹ ti Ikarẹ, Ọba Akadiri Momoh too rọ ẹni ọhun loye, to si fi ẹlomi-in ti wọn pe ni Sunday Bada rọpo rẹ.
Ẹsun ti wọn ni Olukarẹ ka si ọkunrin naa lẹsẹ to fi yọ ọ bi ẹni yọ jiga ni aigbọran si i lẹnu, aijẹ oloootọ ati kikuna lati maa wa ipade deedee.
Igbesẹ yii lo da rogbodiyan nla silẹ laarin ilu lati ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ninu eyi tawọn eeyan bii mẹfa ti ku, ti ọgọọrọ awọn mi-in si wa nile-iwosan ijọba to wa niluu Ikarẹ, nibi ti wọn ti n gba itọju.