Nitori Sunday Igboho, Gumi sọko ọrọ sawọn aṣaaju ẹsin ilẹ Yoruba

Faith Adebọla

Ilumọ-ọn-ka aṣaaju ati olukọ ẹsin Islam l’Oke-Ọya nni, Sheik Ahmed Abubakar Gumi, ti takoto ọrọ sawọn agbaagba ẹsin ilẹ Yoruba lori ọrọ Oloye Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, o ni ko daa bawọn ojiṣẹ Ọlọrun ko ṣe ri nnkan kan ṣe nipa ijijangbara ti ọkunrin naa n gbe pẹlu ijọba Naijiria, ko si daa bi wọn ko ṣe wo awokọṣe oun ti oun n pẹtu saawọ laarin awọn janduku agbebọn atawọn oluṣakoso agbegbe Oke-Ọya.

Apilẹkọ jan-anran jan-anran kan to buwọ lu, eyi to fi lede lori opo ayelujara fesibuuku rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, nibẹ lọkunrin naa ti ni bawọn aṣaaju ẹsin ilẹ Yoruba ko ṣe da si ọrọ Sunday Igboho, tawọn aṣaaju ẹsin ilẹ Ibo naa ko da si ọrọ Nnamdi Kanu, fihan pe wọn ko ṣe ohun tawọn eeyan reti pe ki wọn ṣe.

Diẹ ninu apilẹkọ naa ka pe:

“Titi doni ni iwa ayiri tawọn janduku agbebọn yii n hu ṣi n ṣọṣẹ lagbegbe Ariwa/Ila-Oorun lati bii ọdun mejila sẹyin. Ti a ba jẹ ki  ifẹmiṣofo tun jọba lọkan awọn eeyan ti ko dakan mọ yii, ko sigba ti wọn o ni i run agbegbe Ariwa/Iwọ-Oorun raurau.

Ba a ṣe n sọ yii, awọn ajijangbara IPOB n ba Guusu/Ila-Oorun jẹ, awọn Igboho naa ti gbe omi yanpọnyanrin kana ni Guusu/Iwọ-Oorun. Ko ṣoro fawọn ti wọn n wa bi agbegbe Ariwa/Iwọ-Oorun ṣe maa parun, ko kọja ki wọn sọ awọn janduku yii agbaweremẹsin lọ, o tan. Ki lo tun maa ṣẹku ni Naijiria?

Emi ti bẹrẹ si i ran awọn janduku paraku yii lọwọ lati yipada ninu iṣoro wọn, ṣugbọn o dun mi, pe iwọnba lawọn to fẹẹ ran mi lọwọ, awọn alatako lo pọ lọ jara.

Mo reti pe ki awọn aṣaaju ẹsin nilẹ Ibo naa lọọ ba awọn ọmọ IPOB sọrọ, ki wọn sọ ododo ọrọ fun wọn. Ki pasitọ ilẹ Oduduwa (ilẹ Yoruba) naa gbera lati ba awọn ẹgbẹ ajijagbara Sunday Igboho sọrọ ki wọn jawọ ninu ipolongo iyapa wọn, ki wọn mu awọn eeyan to ni laakaye, ti wọn si fẹran Naijiria lẹyin, ki wọn jẹ kawọn eeyan mọ pe ṣiṣe ara wa loṣuṣu ọwọ lapapọ lo le jẹ ka lominira, idajọ ododo ati anfaani ọgbọọgba. Ọrọ ẹsin lo le wọnu awọn janduku tọkan wọn ti le bii akọ okuta yii, ki ọkan naa si rọ, dipo ọwọ lile tijọba n lo.

Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe niṣe lawọn eeyan wulẹ jokoo tẹtẹrẹ, ti wọn kan n sọ oriṣiiriṣii ọrọ to le tapo sina ogun ẹlẹyamẹya yii. Nibi taye laju de yii, ko ṣi jẹ awọn alaabọ ẹkọ atawọn ajijangbara ẹya ti wọn o loore kan lati ṣeeyan ni yoo maa polongo ija ẹya ni Naijiria.

Ẹya to wa lorileede yii ju ojilerugba lọ, koda to ba tiẹ jẹ ẹya kan tabi ẹsin kan ni wa, ko si aṣeyọri kan to le waye ti ko ba si alaafia ati iṣọkan.

Leave a Reply