Adewale Adeoye
Ileeṣẹ ọlọpaa kan to wa nijọba ibilẹ Yola North, nipinlẹ Adamawa, ti sọ pe ọdọ awọn ni Omidan Blessing ati ọkọ rẹ, Ọgbẹni Luka Iliyasu wa, tawọn mejeeji si ti n ran awọn lọwọ ninu iwadii awọn lori ẹsun ti ọn fi kan wọn pe Blessing gbẹmi ọmọ ikoko to bi lọjọ Abamẹta, Satidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, to si lọọ ju oku ọmọ ọhun sinu ile idalẹnu, ko too di pe ọwọ tẹ ẹ.
ALAROYE gbọ pe Blessing to jẹ ọmọ ogun ọdun, to n gbe lagbegbe Jambatu, nijọba ibilẹ Yola North, ni wọn sọ pe ọdọ ẹgbọn rẹ kan lo n gbe, ṣugbọn tiyẹn ko mọ pe Blessing ti loyun, afigba to bimọ inu rẹ.
Sao, ọmọbinrin yii ti sọ pe ki i ṣe pe oun deede ju oku ọmọ ikoko ọhun sinu ile idalẹnu gẹgẹ bi wọn ti ṣe fẹsun rẹ kan oun. O ni oku loun bimọ naa, toun si tọju rẹ fun ọjọ meji pẹlu ireti pe boya o le ji saye pada, ṣugbọn nigba ti ko ji saye mọ loun lọọ gbe oku ẹ sọnu, ko too di pe awọn ara agbegbe ibi toun gbe e ju si ri oun, ti wọn si fa oun le ọlọpaa lọwo.
Ninu ọrọ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Suleiman Nguroje, lakooko to n foju awọn ọdaran tọwọ tẹ han awọn oniroyin lo ti sọ pe ọdọ awọn ni Blessing ati ọkọ afẹsọna rẹ wa, ti wọn si ti n ran awọn lọwọ lati mọ ipa ti wọn ko lori bi ọmọ ikoko naa ṣe ku.
O ni, ‘‘Awọn kan lo waa ta wa lolobo nipa iṣẹlẹ naa, ta a si lọọ fọwọ ofin mu Blessing ati ọkọ rẹ. Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, ni wọn sọ pe Blessing bimọ naa, ko too lọọ ju u sinu ile idalẹnu kan lẹyin tọmọ naa ti ku mọ ọn lọwọ tan.
‘‘O ti sọ ohun to sẹlẹ fun wa lori bi ọmọ naa ṣe ku ati idi to fi lọọ gbe e ju sori aatan, a gbọ ni, a ko gba a gbọ rara, a maa ṣewadii lori iṣẹlẹ naa daadaa ko too di pe a foju oun pẹlu ọkọ rẹ bale-ẹjọ, ki wọn le jiya ẹṣẹ wọn, bi wọn ba jẹbi gbogbo ẹsun ta a fi kan awọn mejeeji.