Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni kootu alagbeeka kan niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, sọ pe ki awọn eeyan mẹfa kan ti wọn jẹ ọkunrin ati obinrin lọọ fẹwọn ọsẹ meji-meji jura. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn tapa sofin imọtoto ayika.
Ileeṣẹ to n ri si ọrọ ayika ni Kwara, eyi ti igbakeji Kọmiṣanna nileeṣẹ naa, Arabinrin Mustapha Mary, ṣoju fun lo wọ eeyan mẹfa lọ siwaju adajọ Majisireeti Aluko, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un yii, ti wọn si ṣalaye pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa, ni nnkan bii aago mẹjọ si mẹwaa alẹ, lagbegbe ikorita Fátè, ati agbegbe Wahab Fọlawiyọ, l’Opopona Unity, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu fun ipinlẹ naa, nibi ti wọn ti n da idọti soju popo.
Lẹyin ti Majisireeti Aluko gbe idajọ rẹ kalẹ tan lo ni ile-ẹjọ ni aṣẹ lati ran ẹnikẹni to ba tapa sofin imọtoto ayika lẹwọn, tabi ki wọn sanwo itanran. Fun idi eyi, ki wọn lọọ san ẹgbẹrun mẹwaa-mẹwaa (10,000) Naira gẹgẹ bii owo itanran.
Kọmiṣanna lẹka ileeṣẹ to n ri si ọrọ ayika, Arabinrin Rẹmilẹkun Bamigbe, sọ pe idajọ yii yoo jẹ ẹkọ fun gbogbo awọn kọlọransi ẹda ti wọn n tapa sofin imọtoto ayika nipa dida idọti soju agbara nigba ti ojo ba n rọ, ati awọn to n da idọti soju popo nipinlẹ Kwara.
O tẹsiwaju pe oniruuru ilanilọyẹ nijọba Kwara ti ṣe fun awọn araalu, ki wọn le mọ pe ko dara ki wọn da idọju soju agbara, ṣugbọn pabo ni gbogbo rẹ ja si. O ni ileeṣẹ to n ri si ọrọ ayika ti wa ni toju-tiyẹ bayii, ti wọn yoo si maa nawọ gan gbogbo awọn to ba tapa sofin yii.
Bamigbe ni awọn ti pese gooro idalẹsi sawọn aaye kan, ki awọn araalu le maa da idọti si i. O rọ gbogbo olugbe Kwara ki wọn maa samulo gooro naa nigba gbogbo, ki wọn dẹkun dida idọti soju agbara ati dida idọti soju popo.