Nitori Tinubu, Atiku gba APC nimọran

Faith Adebọla

Oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar, ti takoto ọrọ si ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, bẹẹ lo sin wọn ni gbẹrẹ ipakọ, nitori oludije funpo aarẹ wọn, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu. Atiku ni asiko yii lawọn ọmọ Naijiria yoo mọ boya ẹgbẹ naa nitiju tabi wọn ko ni, tori bo ba jẹ ohun ti tawọn ọmọ Naijiria n ri nipa oludije wọn lawọn naa n ri, bo ba si jẹ ohun ti wọn n ro lawọn naa n ro, ko sohun meji to yẹ wọn, to si pọn wọn le ju ki wọn tete paarọ Tinubu lọ.

Ninu atẹjade kan ti Oludamọran pataki fun Atiku lori eto ibaraalu sọrọ, Ọgbẹni Phrank Shaibu, fi lede lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla yii, lorukọ ọga rẹ, lo ti sọrọ to nipọn bii awọ eerin ọhun.

Atiku ni yatọ si ti pe APC kọ lo maa tun ohun ti APC bajẹ ṣe, afi ti wọn ba tun maa ba a jẹ si i, bi Tinubu ṣe n fẹnu kọ lojoojumọ, to n fi dudu pe funfun ni gbangba walia yii ti-i-yan loju, o si fihan pe gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri naa ti darugbo kọja ẹni to yẹ ko dije funpo aarẹ lọdun 2023, o ni aarẹ agba ti n da a laamu, ko si sọgbọn teeyan le da si ọjọ-ori, tori ara agba ki i ro ka’dun.

Apa kan, atẹjade naa ka pe:

“Loootọ ni Tinubu le jẹ agba-ọjẹ oloṣelu to si ti wu u tipẹ lati ṣolori Naijiria, ṣugbọn ki i ṣe keeyan kan jẹ oloṣelu lo le mu-u-yan depo aarẹ. Ohun akọkọ ni keeyan jẹ oloootọ ti ko lẹbọ lẹru. Bi gbogbo nnkan to yẹ karaalu mọ nipa Tinubu ṣe di adiitu bayii ti fihan pe oludije APC ko ni i footọ dari Naijiria.

“Eyi to tiẹ ṣe pataki ju ni pe bi APC ṣe ṣejọba rakuruku yii, ajalu nla lo maa jẹ bi iru Tinubu ba tun gbajọba lọwọ Buhari. Lati tukọ Naijiria kọja keeyan ni awọn alatilẹyin to sọ p’oun ti fa wọn goke nigba kan, Naijiria nilo aarẹ ti ara rẹ le koko, to le rin ko yan fa-n-da, ti ọpọlọ ati laakaye rẹ ko yingin, to si jẹ ẹni tawọn orileede agbaye bọwọ fun, to mọ eto i ṣe, to si mu iṣọkan ba orileede yii, iru eeyan bii Atiku Abubakar.

Ka sootọ ọrọ, ọjọ-ogbo ti fihan pe Tinubu o yẹ nipo aarẹ ta a n sọrọ ẹ yii. Ninu aṣiwi o to aṣisọ ọrọ to sọ lasiko ipolongo ibo wọn to waye kẹyin l’Ekoo, Tinubu ni kawọn ọmọ Naijiria lọọ mu APV, ki wọn mu APC wọn, ki wọn le dibo fun APC, bẹẹ ọmọleewe pamari gan-an mọ pe PVC lorukọ kaadi idibo n jẹ.

“Bi ko ba sọ pe kaadi idibo ti ẹspaya loni-in, yoo sọ pawọn ọmọ Naijiria n tuiti lori Wasaapu lọla, tabi ki wọn gba aadọta miliọnu awọn ọdọ siṣẹ ologun, ki wọn maa fun wọn ni paki jẹ laaarọ ati agbado jẹ lalẹ, ẹ jẹ ka sọrọ sibi tọrọ wa, ṣe iru aarẹ ta a fẹ nibi taye laju de ree.

“Ẹgbẹ APC waa ṣeleri ‘Ireti Ọtun’ (Renewed Hope) fawọn ọmọ Naijiria, ṣe o ṣee ṣe lati fi aisan wo aisan ni, abi okunkun le mu okunkun kuro ni? Bawo ni APC yoo ṣe mu iṣoro ti APC da silẹ ti wọn fẹ loju si i kuro funra wọn? Iregbe ọrọ lasan niyẹn o.”

“Imọran temi le gba wọn ni ki wọn tete mọ bi wọn ṣe maa paarọ alawada ti wọn fi ṣe oludije funpo aarẹ wọn, tori gbogbo aye lo n wọn laworẹrin-in.”

Bẹẹ ni Atiku sọ o.

Leave a Reply