Nitori tiyẹn loun ko fẹ ẹ mọ, Bamiyọ pa ololufẹ rẹ l’Ode-Irele

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ ọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Ayara Bamiyọ, lori ẹsun pe o mọ nipa iku ololufẹ rẹ, Abilekọ Ọlakanye, niluu Ode-Irele, nijọba ibilẹ Irele.

Ọkan ninu mọlẹbi Oloogbe Ọlakanye, to ba akọroyin wa sọrọ sọ pe o ti lọkọ kan ri tẹlẹ, koda awọn ọmọ mẹta to bí fun ọkọ aarọ rẹ ti dagba daadaa, akọbi rẹ ti wa ni fasiti, nibi ti to ti n kawe, nigba tawọn meji yooku si wa nile-iwe girama.

A ko le sọ pato ohun to fa ipinya laarin oun ati ọkọ aarọ rẹ to bimọ fun ki iyẹn too ku, ṣugbọn ALAROYE gbọ pe abilekọ naa ti n fẹ ẹlomi-in lẹyin to kuro nile ọkọ akọkọ.

Nigba ti baba awọn ọmọ rẹ ku, to si lọọ supo ọkunrin naa ni ibamu pẹlu àṣà ati iṣe ilẹ Yoruba ni wọn lawọn ẹbi afẹsọna rẹ tuntun yari kanlẹ pe ọmọ awọn ko ni i fẹ ẹ mọ latari opo to lọọ su.

Laarin asiko yii, iyẹn ni nnkan bii osu mẹfa sẹyin lo pade Bamiyọ toun naa ti bimọ mẹta tẹlẹ, ti wọn si jọ n fẹ ara wọn.
Wọn ní ohun ti Bamiyọ sọ fun oloogbe ki wọn too bẹrẹ si i fẹra ni pe oun ko niyawo tabi afẹsọna Kankan. Kayeefi lo waa jẹ fun iya ọlọmọ mẹta ọhun nigba tawọn obinrin kan n pe e sori aago, ti wọn si n halẹ, ti wọn n bu u pe ọkọ awọn lẹni to ṣẹṣẹ n fẹ naa.

Idi ree to fi pinnu ati pada sọdọ ololufẹ rẹ atijọ, iyẹn ẹni ti wọn jọ pinya latari pe o lọọ supo niwọn igba ti ọkunrin naa kuku ti n bẹ ẹ tẹlẹ.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja lọhun-un, ni wọn lo pe Bamiyọ sori aago lalẹ, to si sọ fun un pe ọrọ ifẹ awọn ko ni i le tẹsiwaju mọ nitori ọkan-o-jọkan ipe ijaya ti oun n gba lati ọwọ awọn mi-in to n fẹ. Oloogbe naa ko si fọrọ sabẹ ahọn sọ, o jẹwọ fun un pe oun fẹẹ pada sọdọ ololufẹ oun atijọ.

Ọrọ yii ka Bamiyọ lara, bẹẹ lo tun ba a lojiji, ohun to fi da a lohun ni pe ko si iyọnu, o ni ko duro de oun sile rẹ nitori pe oun ti n bọ waa ba a ki awọn le jọ sọrọ naa kunna, ko ma jẹ ọrọ ori foonu lasan, ṣugbọn oloogbe ni ko ma wulẹ yọ ara rẹ lẹnu ati wa nitori ilẹ ti su.

Ko pẹ ti wọn sọrọ tan ni wọn lobinrin naa n gbọ ti Bamiyọ n kanlẹkun yara rẹ, to si ni dandan ni ko waa si i foun koun le wọle. Arọwa to n pa fun un pe ko pada wa nigba ti ilẹ ba mọ lọjọ keji ko da bii ẹni wọ ọkunrin tara rẹ ti gbona sodi ọhun leti rara, nitori gbogbo ohun to wa lọkan rẹ ni pe ọkunrin mi-in to wa lọdọ rẹ ni ko fi waa silẹkun foun.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: