Nitori to ṣe agbere, wọn fun iyaale ile lẹgba ọgọrun-un

Ọbẹ ti baale ile ki i jẹ, iyaale ile ko gbọdọ se e ni ọrọ wọn lapa ibi kan ti wọn n pe ni Aceh, lorile-ede Indonesia. Wọn koriira agbere ṣiṣe, ẹni ti wọn ba si mu to dan an wo, atoori buruku ni tọhun ati ẹni ti wọn jo ṣe iṣẹkuṣe naa yoo jẹ.

Iru ẹ ni ti obinrin ti ẹ n wo fọto rẹ yii, iyawo ile ọkunrin kan ni, ṣugbọn wọn lo ba ọkọ ọlọkọ sun, oun naa si jẹwọ pe loootọ loun ati ọkunrin naa jọ gbadun ara awọn, ni wọn ba na an lẹgba ọgọrun-un kan.

Ọjọbọ to kọja yii ni wọn lu obinrin yii, ṣugbọn ọkunrin ti wọn ni wọn jọ gbadun ara wọn sọ pe oun ko ba a ṣe nnkan kan, irọ lo n pa mọ oun.

Ọkunrin naa ṣaa taku ni, pe oun ko ṣe nnkan kan pẹlu obinrin yii, koda, o gba kootu lọ lori ẹ, nni wọn ba ni ko si boun naa ko ṣe ni i jẹgba, tiẹ kan le ma to ọgọrun-un kan ni. Ẹgba mẹẹẹdogun ni wọn pada na ọkunrin naa.

Gbogbo bi wọn ṣe lu wọn yii lawọn eeyan ka silẹ ti wọn si gbe e sori ayelujara.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ajafẹtọọ ọmọniyan koro oju si iwa yii, wọn ni titẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọlẹ ni, sibẹ, ilu Aceh ko yi ofin Sharia to ti n lo tipẹ pada,wọn si n lo o lọ.

Olori orilẹ-ede Indonesia, Joko Widodo, ti pe fun fifi opin si ofin yii naa titi, ṣugbọn awọn Aceh ko yee ṣe bẹẹ, afẹni ti ko ba ji kinni ẹlomi-in jẹ lo kogo wọn ja.

Leave a Reply