Nitori to fẹẹ ṣoogun owo, ọmọkunrin yii pa ọrẹbinrin rẹ, o ba oku rẹ lo pọ fun odidi ọjọ mẹfa

Ọrẹoluwa Adedeji
Epe rabandẹ rabandẹ, lawọn eeyan ti wọn gbọ nipa iwa ọdaju ti ọmọkunrin kan ti wọn n pe ni Ifeanyi Njoku hu, pẹlu bo ṣe pa ọrẹbinrin rẹ, Precious Okeke, ẹni ọdun mẹrinlelogun si ile ti wọn rẹnti ni ni Opopona Oke, Ẹsiteeti Badore to wa niluu Ajah, nipinlẹ Eko. Lẹyin to pa a tan lo n ba oku rẹ lo pọ fun odidi ọjọ mẹfa gẹgẹ bi babalawo to fẹẹ ba a ṣoogun owo ṣe sọ. Ọjọ keje lọwọ tẹ ẹ.
Awọn araale ti wọn n gbọ oorun buruku to n jade lati inu yara rẹ ni wọn lọọ fọrọ naa to awọn alaṣẹ ẹsiteeti ọhun leti gẹgẹ bi akọroyin iweeroyin Punch ṣe ṣalaye.
A gbọ pe ọrẹbinrin Njoku ni Precious to ṣeku pa yii, abule wọn lo ti lọọ mu un wa ti wọn si ti jọ n gbe ni ile to ṣẹṣẹ rẹnti to wa ni Badorẹ, niluu Ajah ọhun.
Ọmọkunrin yii la gbọ pe o fẹẹ ṣoogun owo, ohun ti babalawo to n ran an lọwọ lati ri eleyii ṣe si sọ fun un ni pe ko lọọ wa ọmọbinrin kan, lẹyin ti ọmọ naa ba ku, o ni lati ba oku rẹ lo pọ fun ọjọ meje, lẹyin ọjọ meje yii ni yoo ni owo to n dẹruba oṣi lọwọ.
Eyi ni ọmọkunrin yii gbọ to fi ṣeku pa ọrẹbinrin rẹ ti wọn jọ n gbe yii, lẹyin to pa a tan lo bẹrẹ si i ba oku rẹ lo pọ gẹgẹ bi babalawo naa ṣe paṣẹ fun un.
Odidi ọjọ mẹfa lo fi ba oku ọrẹbinrin rẹ yii lo pọ, ṣugbọn oorun buruku lo n ti inu yara rẹ jade nitori oku naa ti n jẹra ni awọn araale ṣakiyesi. Oorun ti ko jẹ ki awọn araale gbadun yii lo mu ki wọn lọọ sọ ọrọ Njoku fun alaga ẹsiteeti naa.
Awọn eeyan naa ni wọn lọọ fọrọ yii to wọn leti ni teṣan Langbasa, lẹyin to jẹwọ fun wọn pe loootọ loun pa ọrẹbinrin oun, ti oun si n ba oku rẹ lo pọ nitori pe oun fẹẹ lowo.
Niṣe lo ni ki awọn eeyan adugbo naa ma mu oun lọ si agọ ọlọpaa, o ṣi ṣeleri pe oun yoo fun wọn ni miliọnu mẹfa Naira bi wọn ba ba oun ṣe ọrọ naa ni oku oru.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni awọn meji lọwọ awọn ti tẹ lori iṣẹlẹ naa, Ifeanyi Njoku ati Mbam Atunmufor. O fi kun un pe wọn ti ko wọn lọ si ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si iwa ọdaran to wa ni Yaba niluu Eko.

Leave a Reply