Ibrahim Alagunmu
Ile-ẹjọ Magistreeti kan niluu Kaiama, nipinlẹ Kwara, ti sọ Arakunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Ayuba Ẹnupe, sẹwọn ọdun mẹta fẹsun pe o lọọ ji apo saka-saka bọndu marun-un niluu Kaiama.
Ajọ ẹṣọ alaabo sifu difẹnsi nipinlẹ Kwara, lo wọ ọdaran naa lọ si kootu kan niluu Kaiama, fẹsun ole jija ati awọn ẹsun miiran to fara pẹ ẹ.
Agbefọba, Mumini Tanba, sọ fun ile-ẹjọ pe afurasi naa lọọ digun ja Ọgbẹni Jimoh Adigun, to n gbe ni Opopona ileewosan jẹnẹra, niluu naa lole, to si ko apo saka-saka ti wọn fi n di ẹru to n lọ bii bọndu marun-un. O tẹsiwaju pe iwadii fihan pe Ayuba ko ṣẹṣẹ maa lọọ kole onile. Mumini sọ pe afurasi naa ti lọọ ji foonu meji nile Ọgbẹni AbdulRazaq, to n gbe ni agbegbe Kuokuo, fun idi eyi, ẹlẹṣẹ kan ko yẹ ko lọ lai jiya, ati pe yoo kọ awọn eeyan bii tiẹ lọgbọn.
Onidaajọ Abdullahi Ahmed Boro, paṣẹ pe ki wọn sọ Ayuba sẹwọn ọdun mẹta pẹlu iṣẹ aṣekara, o ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii atawọn ẹri to daju, Ayuba jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.