Nitori to kuro ninu ẹgbẹ wọn, PDP fẹẹ yọ igbakeji gomina Ọyọ nipo

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori bo ṣe fi ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), silẹ, ẹgbẹ oṣelu ọhun ti pinnu lati yọ Ẹnjinnia Rauf Ọlaniyan ti i ṣe igbakeji gomina ipinlẹ naa nipo.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, l’Ọlaniyan kede pe oun ko ṣe ẹgbẹ PDP mọ, ẹgbẹ All Progressives Congress (APC), loun n ba lọ wayi.

Ninu lẹta to fi ṣọwọ sawọn oniroyin lalẹ ọjọ keji, iyẹn ọjọ Aje, Mọnde, ana, Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ yii, Ẹnjinnia Akeem Ọlatunji, rọ igbakeji gomina yii lati rọra kọwe fipo rẹ silẹ wọọrọwọ, bi bẹẹ kọ, lile lawọn yoo le danu nile ijọba.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Orukọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ọlaniyan fi dupo igbakeji gomina ninu idibo ọdun 2019, orukọ ẹgbẹ yii naa lo si fi wọle ibo to fi depo yii, bo ṣe waa fi ẹgbẹ PDP silẹ yii, ohun to kan fun un naa ni ko fipo igbakeji gomina silẹ, nitori orukọ ẹgbẹ yii lo fi gori ipo yẹn.

“Ẹni to ba dibo wọle lorukọ ara rẹ nikan lo le lọ sinu ẹgbẹ oṣelu to ba wu u nigbakuugba to ba fẹ. Ṣugbọn beeyan ba lo orukọ ẹgbẹ oṣelu wọ ipo, to ba mọ-ọn-mọ kuro ninu ẹgbẹ yẹn, ko tun le maa janfaani ipo yẹn lọ mọ, nitori ibo ti awọn araalu di to gbe e depo yẹn, ẹgbẹ oṣelu rẹ ni wọn di i fun, ki i ṣe iwaju orukọ rẹ ni wọn tẹka si lọjọ idibo.”
Ẹgbẹ oṣelu PDP waa rọ Ẹnjinnia Ọlaniyan lati tete kọwe fipo naa silẹ wọọrọ ki awọn too yẹyẹ ẹ kuro lori aga igbakeji gomina, nitori niṣe lawọn yoo kanra le e kuro nile ijọba.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: