Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ẹgbẹ PDPipinlẹ Ekiti ti yẹgẹ ẹnu si gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde Fayẹmi, pẹlu bo ṣe ṣeleri pe oun yoo fopin si eto aabo to dẹnukọlẹ ti wọn ba dibo fun oun wọle lakooko to ṣabẹwo sipinlẹ Borno ati Yobe.
Gomina Fayẹmi to n dije dupo aarẹ ninu ẹgbẹ APC lo sọrọ yii lakooko to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ naa sọrọ nipinlẹ Borno ati Yobe. O ni oun ni ohun gbogbo to pe fun lati da alaafia pada si ipinlẹ mejeeji yii ati awọn ipinlẹ yooku lorilẹ-ede Naijiria.
Ẹgbẹ naa juwe ileri ti Fayẹmi ṣe gẹgẹ bii ohun ti ko le ṣe, ati ọna lati tun tan awọn eeyan jẹ.
Akọwe iroyin ati ipolongo ẹgbẹ PDP, nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Raphael Adeyanju, lo sọrọ yii ninu iwe kan to fi ṣọwọ si awọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii. O ni, “o jọ pe Gomina Fayẹmi ko ranti owe Yoruba kan to sọ pe ile ni a ti n ko ẹṣọ rode.”
Wọn ni o ya awọn lẹnu bi Fayẹmi ṣe ro pe oun yoo daabo bo apa kan lorilẹ-ede yii, lẹyin igba to padanu lati pese aabo to peye si gbogbo ipinlẹ Ekiti, ni pataki julọ, ilu abinibi rẹ, Iṣan-Ekiti, to ti di ile awọn ajinigbe ati awọn agbebọn.
Ẹgbẹ yii fi kun un pe gbogbo awọn eeyan ati olugbe ipinlẹ Ekiti ni ko le sun ki wọn di oju wọn mejeeji pẹlu bi awọn ajinigbe ṣe gba gbogbo ọna to wọ ipinlẹ Ekiti.
PDP waa kilọ pe ki gbogbo ọmọ Naijiria ma fi ara wọn silẹ fun ẹtan pe afi ki eeyan ni imọ tabi ẹkọ lori eto aabo ko too le jawe olubori ninu eto idibo, tabi ko ṣejọba daadaa.
Adeyanju ṣalaye pe gbogbo ọmọ Naijiria ni yoo ranti bi Arẹ Mohammadu Buhari ṣe ṣeleri pe oun yoo wa ojutuu si gbogbo iṣoro to n dojukọ Naijiria ni kete ti wọn ba dibo fun oun, ṣugbọn ko si nnkan kan ti Ọgagun yii ṣe lẹyin igba to de ori aleefa pẹlu bi awọn ajinigbe ṣe n ji eeyan gbe lojoojumọ ti wọn si n pa awọn ẹlomiiran.