Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti mu awọn afurasi mẹta kan, Ọlamide Boluwatifẹ, Abbdusalam Abubakar ati Ọlayẹmi Ismail, ti wọn n lu awọn oni POS ni jibiti niluu Ilọrin ati Ọffa, nipa pipaarọ POS wọn pẹlu ayederu.
Agbẹnusọ ileeeṣẹ ọlọpaa, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, sọ pe lasiko ti awọn ẹsọ alaabo n yide kiri lagbegbe Budokọ Baruten, to wa ni Agric, niluu Ilọrin, ni ọwọ tẹ awọn adigunjale mẹta yii nibi ti wọn ti tun fẹẹ lu oni POS miiran ni jibiti.
O tẹsiwaju pe iwadii fidi ẹ mulẹ pe awọn afurasi naa ti parọ ẹrọ POS to n lọ si bii mẹtalelọgbọn ninu iluu Ilọrin ati Ọffa nikan, ti wọn si ti yọ owo to to miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin Naira (#1.7miilion), lakoto awọn oni POS ti wọn parọ naa.
Awọn afurasi naa jẹwọ pe loootọ lawọn maa n lu awọn oni POS ni jibiti, ati pe ti ẹnikan ba ti fẹẹ gbowo, ẹni keji yoo maa ta ọgbọn ti yoo fi paarọ ẹrọ ti ẹni naa n lo, wọn aa fi ayederu rọpo rẹ, ti wọn aa si lọọ gba gbogbo owo to n bẹ ninu POS ọhun
Ileeeṣẹ ọlọpaa ti rọ awọn olowo POS ki wọn maa wa ni oju lalakan fi n sọri nigba gbogbo tori awọn onijibiti, bakan naa lo fi gbogbo awọn olugbe Kwara lọkan balẹ pe ileeṣẹ naa ko ni i kaaarẹ ọkan lati maa pese aabo to peye fun wọn.