Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Lori ipaniyan to n waye lemọlemọ niluu Ikẹrẹ-Ekiti, ijọba ipinlẹ naa ti Ekiti ranṣẹ pe awọn ọba alaye mejeeji to wa niluu naa, Ọba Adejimi Adu ati Olukẹrẹ, Oloye Ganiyu Ọbasọyin, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii.
Ijọba sọ pe ki awọn ori-ade mejeeji waa ṣalaye nipa ipaniyan to ṣẹlẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ati eyi to ṣẹlẹ ni nnkan bii oṣu kan sẹyin niluu naa.
Ninu lẹta pajawiri kan ti Oludamọran lori eto iroyin igbakeji gomina ipinlẹ naa, Ọgbẹni Ọdunayọ Ogunmọla, fi sita lorukọ Oloye Bisi Ẹgbẹyẹmi lo ti sọ pe awọn ọba mejeeji to wa niluu naa gbọdọ gba alaafia laaye niluu naa.
Wọn fi kun un pe awọn ọba naa ko gbọdọ ba awọn araalu fa wahala kankan ti yoo mu ipaniyan tabi rogbodiyan dani niluu ọhun.
Bakan naa ni wọn tun fa awọn ọba mejeeji leti pe wọn ko gbọdọ ṣe ipade kankan tabi ipejọpọ kankan niluu titi digba ti rogbodiyan naa yoo fi rọlẹ.
Igbakeji gomina ni ijọba yoo fi imu awọn ọba ati oloye ilu naa danrin ti wahala mi-in ba tun ṣẹlẹ, tabi ti ija miiran ba tun bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun .
Bi ẹ ko ba gbagbe, Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni awọn ọdọ meji gba ọrun lọ lojiji ninu ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun. Bakan naa ni awọn ọdọ mẹfa ku lojiji ninu oṣu to kọja yii.
Ijọba ipinlẹ naa ṣekilọ pataki fawọn olori ati awọn olugbe ilu naa pe ki wọn sọwọ pọ pẹlu ijọba ati awọn agbofinro, ki wọn si maa fi ọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn ba kẹẹfin niluu naa to ijọba leti.