Nitori wahala ọrọ ilẹ, ijọba kede konilegbele niluu Ilobu ati Ẹrin-Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede konilegbele oniwakati mẹrinlelogun bayii latari wahala to n ṣẹlẹ laaarin ilu Ilobu ati Ẹrin-Ọṣun.

Irọlẹ ọj ọ Abamẹta ni wahala ọlọjọ pipẹ naa tun bẹrẹ lasiko ti awọn oṣiṣẹ tijọba ni ki wọn yanju wahala aala ilẹ lagbegbe naa n ṣiṣẹ wọn lọwọ.

A gbọ pe agbegbe kan to n jẹ Ahoro Aafin, lo da wahala ọhun silẹ, bi awọn Ilobu ṣe n sọ pe awọn lawọn ni i, lawọn Ẹrin-Ọṣun naa n pariwo pe ori ilẹ awọn ni.

Bayii ni wahala yii burẹkẹ, bi wọn ṣe n fa ada yọ, ni wọn n lo aake, ko si pẹ ti wọn fi fa’bọn yọ, ti wọn si doju ẹ kọ ara wọn.

A gbọ pe awọn ẹṣọ Amọtẹkun atawọn ọlọpaa ṣiṣẹ pupọ nibẹ loru-mọju, lati pẹtu saawọ naa, ṣugbọn bi ilẹ tun ṣe mọ ni wọn tun bẹrẹ.

Lasiko ti a n ko iroyin yii, oku ọdọkunrin kan wa layiika aafin Olobuu, bẹẹ laimọye eeyan si fara pa niluu mejeeji.

Idi niyi ti Gomina Gboyega Oyetọla fi kede konilegbele naa. O ni eleyii yoo le jẹ ki alaafia pada siluu mejeeji. O si rọ gbogbo awọn araalu lati pa aṣẹ naa mọ.

Leave a Reply