Nnkan de! Aṣẹwo wọ Mọrufu lọ si kootu, o lo ji owo oun

Florence Babaṣọla

Yinkun yinkun ti Sikiru Mọrufu, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ṣe fun obinrin aṣẹwo kan ti sọ ọ dero kootu bayii. O ti foju ba kootu Mapo, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, lori ẹsun ole jija.

Gẹgẹ bi agbefọba to n ṣe ẹjọ naa, Inspẹkitọ Salewa Ahmed, ṣe ṣalaye ni kootu, o ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni Mọrufu huwa naa lagbegbe Idi-Aro, niluu Ibadan.

Ahmed sọ pe ṣe ni olupẹjọ, Ẹniọla Ọpẹyẹmi, kegbajare lọ si agọ ọlọpaa to wa ni Idi-Aro, pe ọkan lara awọn kọsitọma oun yan oun jẹ.

Ẹniọla sọ fun awọn ọlọpaa pe lẹyin ti oun tẹ Mọrufu lọrun tan, ti oun si gba owo iṣẹ ti awọn jọ ṣe adehun ni ọmọkunrin naa dọgbọn pada sinu yara oun lai jẹ ki oun mọ, to si ji ẹgbẹrun mẹta Naira ti oun ko pamọ pẹlu foonu Infinix oun, ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna mẹrindinlaaadọta Naira.

Inspẹkitọ Ahmed sọ fun kootu pe iwa ti olujẹjọ hu ọhun lodi, bẹẹ lo si nijiya labẹ ipin irinwo o din mẹwaa (390) abala ikejidinlogoji ofin iwa ọdaran ti ọdun 2000 nipinlẹ Ọyọ.

Nigba ti wọn ka ẹsun kan ṣoṣo ti wọn fi kan an si i leti, Mọrufu sọ pe oun ko jẹbi.

Ninu idajọ rẹ, Adajọ Majisreeti naa, O. O. Latunji, faaye beeli silẹ fun olujẹjọ pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira ati oniduuro meji ti wọn jẹ mọlẹbi rẹ ni iye kan naa.

Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.

Leave a Reply