Nnkan de! Eeyan mẹtadinlogun tun ti lugbadi arun Korona nipinlẹ Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Lasiko yii to da bii pe awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun n fi ẹdọ le ori oronro lori ọrọ ajakalẹ arun Koronafairọọsi, gudugbẹ mi-in tun ja loni-in nigba ti wọn gbọ pe eeyan mẹtadinlogun lo tun ti lugbadi arun naa.
Kọmisanna fun eto ilera, Dokita Rafiu Isamọtu, sọ f’AALAROYE pe esi ayẹwo awọn eeyan naa lo fi han pe arun ọhun ti wa lara wọn.
O ni awọn araalu ti tu ara silẹ ju lori ọrọ ajakalẹ arun Korona, eleyii to si buru pupọ nitori arun naa ṣi wa larọọwọto ẹnikẹni to ba fi ọwọ yẹpẹrẹ mu un.
Isamọtu fi kun ọrọ rẹ pe ki i ṣe ilu kan pere ni wọn ti ri awọn eeyan naa, ṣe lo fọn kaakiri ipinlẹ Ọṣun.
O waa gba awọn araalu niyanju lati tẹra mọ awọn ilana ti ajọ eleto ilera agbaye la silẹ fun idena Korona, ki wọn si mu imọtoto ara ati agbegbe wọn lọkun-unkundun.

Leave a Reply