Faith Adebọla
Ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrin, oṣu Kejila ta a wa yii, awọn agbebọn lugọ de kọmiṣanna fun eto sọgbẹ-digboro ati ile gbigbe nipinlẹ Benue, Oloye Ogbu Ekpe, wọn si ji i gbe lọ.
Yatọ si kọmiṣanna yii, wọn tun ji awọn mẹta mi-in pẹlu ẹ, eyi ti Ọnarebu Agbo Ode, ti i ṣe ana kọmiṣanna ọhun ati awakọ rẹ, wa ninu wọn.
Ba a ṣe gbọ, kọmiṣanna naa, to ti figba jẹ alaga ijọba ibilẹ Ado, nipinlẹ ọhun, atawọn ti wọn jọ wa ninu ọkọ rẹ, n dari re’le rẹ lati ibi eto isin kan ti wọn ṣe ni ṣọọṣi Saint Augustine Catholic Church, to wa ni Otukpo, lẹyin ti wọn ṣe ifilọlẹ eto ipolongo ibo Sẹnetọ Abba Moro, laimọ pe awọn agbebọn ti lugọ pamọ si ikorita Adankari, nitosi oko David Marks, to wa laduugbo Akpa Otobi, lọna marosẹ Otukpo si Ado, nijoba ibilẹ Ado. Bi ọkọ ti ọkunrin naa wa ninu rẹ ṣe tẹ siloo lati yi kọna ikorita naa lawọn ajinigbe naa yọ si i, wọn si fipa dari ọkọ rẹ gba ọna mi-in lẹsẹkẹsẹ.
Nigba to ku diẹ ki wọn wọlu Otukpo, wọn paaki, wọn si wọ kọmiṣanna naa bọ silẹ ninu ọkọ Hilux to wa, wọn gbe e wọnu igbo lọ.
Oludamọran pataki si Gomina Samuel Ortom lori eto aabo, Ajagun-fẹyinti Paul Hemba, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.
O lawọn ọlọpaa ti ri ọkọ Hilux ti wọn ji kọmiṣanna naa gbe ninu rẹ, wọn si ti gbe e kuro lẹgbẹẹ titi ti wọn gbe e si.
O lawọn agbofinro atawọn ọlọdẹ ti bẹrẹ si i tọpasẹ awọn ajinigbe ọhun lati doola ẹmi kọmiṣanna atawọn mi-in to ṣee ṣe ki wọn wa lakata awọn ajinigbe naa.
Titi dasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ, o lawọn ajinigbe naa ko ti i kan sawọn mọlẹbi Oloye Ogbu lati sọ ohun ti wọn fẹ, ṣugbọn o ni ireti wa pe wọn yoo ri i gba pada laipẹ.