Nnkan ti daru mọ Buhari atawọn eeyan ẹ lọwọ – Gani Adams lo sọ bẹẹ

Aderounmu Kazeem

Lanaa, ọjọ Aiku, Sannde, ni ile ijọsin kan, Saviour’s Ministries fi Aarẹ Ọnakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, jẹ oye Apositeli ijọ naa.

Ni kete ti wọn ti fun un loye ọhun tan, ti awọn oniroyin bọ siwaju ẹ lati ba a sọrọ, ọrọ Buhari ni Iba Gani Adams, sọrọ le lori, nibi to ti sọ pe, eto aabo orilẹ-ede yii ko ye Aarẹ Muhammadu Buhari, mọ.

O ni, ohun itiju nla gbaa ni bi wọn ti ṣe ji awọn ọmọleewe ti wọn fẹẹ to ẹgbẹta (600) ji ko nipinlẹ Katsina ti i ṣe ibi ti Aarẹ Buhari ti wa, ati pe olori orilẹ-ede yii paapaa wa niluu ẹ nipinlẹ ọhun nigba ti awọn janduku ajinigbe ọhun ya wọ ileeewe ti wọn ti lọọ ko awọn ọmọ-ọlọmọ.

O lohun to foju han bayii ni pe Buhari ko lagbara lati koju iṣoro eto aabo to n da wahala silẹ ni Naijiria bayii, ati pe nibi ti ọrọ orilẹ-ede yii de lasiko yii, o ṣe pataki ki atunto gidi waye, paapaa bi ọrọ ti ṣe daru mọ awọn Buhari lọwọ yii.

O fi kun un pe bawo leeyan ṣe le ṣalaye bi wọn ti ṣe ji awọn ̀ọmọleewe bii ẹgbẹta ko lẹẹkan naa. Eyi fi han daju pe eto aabo ti mẹhẹ patapata, ati pe lasiko ti Buhari lọ siluu ẹ fun isinmi ọsẹ kan gan an ni ikọlu naa waye, eyi to fi ijọba ẹ atawọn ti wọn jọ n ṣeto akoso han gẹgẹ bi awọn eeyan ti wọn ko mo ohun ti wọn n ṣe rara.

Siwaju si i, o ni nibi ti ọrọ Naijiria de loni-in, o fi han wi pe iya nla lo n jẹ awọn eeyan, paapaa bi ohun gbogbo ṣe wọn gogo, ti owo naira paapaa ko ribi duro si mọ lẹgbẹẹ owo dọla ilẹ Amẹrika.

 

Leave a Reply