Faith Adebọla
Titi dasiko yii lawọn eeyan n fibinu bu epe rabandẹ ṣọwọ si baale ile kan, Nurudeen Amao Ariya, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o lu iyawo rẹ, ẹni ọgbọn ọdun, Abilekọ Mujidat Ademọla, lalubami, wọn ni niṣe lọkunrin naa fẹẹ pa iyawo rẹ tabi ko fọ ọ loju patapata.
Ilu Ṣaki, to wa nijọba ibilẹ Ṣaki West, nipinlẹ Ọyọ, la gbọ pe iṣẹlẹ yii ti waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja. Ọmọ mẹrin ni wọn lobinrin naa ti bi nile ọkọ.
Atẹjade kan ti Ọgbẹni Lawal Adekunle, oludasilẹ Ajọ Saki First, fi lede lọjọ Aje, Mọnde yii, ṣalaye pe:
“O dun wa pe a maa ṣiṣọ loju eegun iṣẹlẹ yii, tori a ro pe ka yanju ẹ labẹle tẹlẹ ni, a o fẹẹ ba orukọ ilu Ṣaki jẹ, ṣugbọn ọrọ nipa ẹmi eeyan la n sọ yii, a o si le dakẹ lori ẹ.
‘‘Ariyanjiyan kan lo bẹ silẹ laarin Mujidat Ademọla ati ọkọ ẹ, Nurudeen Amao Ariya, ni nnkan bii aago mọkanla alẹ Ọjọruu, Wẹsidee. Ọkọ fẹsun kan iyawo ẹ pe o n fọbẹ ẹyin jẹ oun niṣu, pe o ti n nasẹ sita, lọrọ naa ba dija laarin wọn, ọkunrin yii si luyawo ẹ bii kiku bii yiye, o lu u kọja aala patapata.
‘‘Wọn sare gbe Mujidat digbadigba lọ sileewosan aladaani kan nitosi fun itọju. Afurasi ọdaran yii ṣi n bẹ nọọsi naa pe ko da aṣọ aṣiri bo oun, o loun ko mọ pe oun ti ṣeyawo oun leṣe to bẹẹ, ṣugbọn nigba ti itọju obinrin naa ko fẹẹ gba oju ọwọ mọ, tori ẹjẹ to n jade loju obinrin naa ko duro, wọn ni ki wọn tete maa sare gbe e lọ sileewosan nla UCH (University College Hospital), ẹka wọn to wa niluu Ṣẹpẹtẹri, nibẹ ni wọn ti ṣayẹwo fun un ti wọn si bẹrẹ itọju pajawiri.
Latigba ti Nurudeen ti gbe iyawo rẹ de ọsibitu UCH yii loru ọjọ naa lo ti sọ pe oun fẹẹ lọọ wa owo ya lati sanwo itọju, o si n bẹ awọn oniṣegun pe ki wọn ṣaanu oun, ki wọn ma jẹ ki obinrin naa ku mọ oun lọwọ. Ṣugbọn alọ rẹ la ri, a o ri abọ, ko tun sẹni to foju kan an mọ latigba naa, o sa lọ ni.
‘‘Nigba ta a reti ẹ titi ta o ri i, emi (Adekunle) pe e lori aago lalẹ ana (ọjọ Sannde), tori ko ki i gbe aago ẹ, ko si fesi sawọn atẹjiṣẹ ta a fi ṣọwọ si i latẹyinwa, ṣugbọn o gbe e nigba ti mo pe, mo si ba a sọrọ, kaka ko bẹbẹ, niṣe lo tun n sọrọ buruku si mi lori foonu, ko si ṣetan lati san ẹgbẹrun lọna ọgọfa (N120,000) ti wọn ni ko san fun itọju iyawo ẹ ni UCH. Ọpẹlọpẹ ọrẹ ẹ kan lo ba a san ẹgbẹrun lọna aadọta (N50,000) ninu ẹ.
‘‘O daju pe afurasi ọdaran yii ko mọ bi iwa ọdaran toun hu ṣe tẹwọn to, ko si ṣetan lati tuuba, idi niyi ti a fi ni lati pariwo ẹ faraye.
‘‘Ati pe ọpọ awọn eeyan lagbegbe Ṣaki ni wọn o mọ pe iwa ọdaran pọmbele ni aṣa lilu iyawo ẹni jẹ. Ọsẹ meloo kan sẹyin lẹnikan ṣi lu iyawo ẹ lalubami debii pe obinrin naa dakẹ mọ ọn lọwọ. Ojumọ kan, ilukulu kan ni wọn fi aṣa naa ṣe.
‘‘A rọ awọn agbofinro lati san ṣokoto lori ọrọ yii, ki wọn ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ, ki wọn le dẹkun aṣa palapala ti ko bofin mu yii. Ki wọn ri i pe awọn ti wọn n lọwọ ninu iwa ẹranko yii fimu kata ofin, ki wọn ma baa san aṣọ iru iwa bẹẹ ṣ’oro mọ.”
Bẹẹ ni atẹjade naa wi, wọn si fi awọn fọto tọkọtaya naa lede pẹlu, to ṣafihan bi Nurudeen ṣe fi ilukilu ba ẹwa iyawo ẹ to ri reterete jẹ.