Dada Ajikanje
Pẹlu ibanujẹ ni ajọ to n ṣamojuto eto isinlu awọn agunbanirọ, NYSC, fi kede pe ko si ootọ kankan ninu ọrọ tawọn kan n gbe kiri pe wọn ti ji agunbanirọ mẹtadinlogun gbe, ati pe loootọ lawọn janduku kọ lu wọn, ti ọkan ninu wọn, Bomoi Suleiman Yusuf, si ba iṣẹlẹ ọhun lọ.
Lori ikanni abẹyẹfo ajọ naa ni wọn ti fidi ẹ mulẹ pe awọn agunbanirọ ti wọn waa sin orilẹ-ede yii nipinlẹ Ọṣun, lawọn adigunjale kan kọ lu nigba ti wọn n pada si ilu wọn l’Oke-Ọya. Ati pe nigba ti awọn janduku ọhun n rọjo ibọn ni ọkan ninu awọn agunbanirọ ọhun pade iku ojiji nibi ti wọn ti yinbọn lu wọn, to si ku loju-ẹsẹ.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, lawọn agunbanirọ ọhun gbera kuro nipinlẹ Ọṣun lẹyin ti wọn pari eto isinjọba ọlọdun kan wọn, ti wọn si mori le Oke Ọya ti wọn ti wa. A gbọ pe bi wọn ṣe de agbegbe kan ti wọn n pe ni Jere, lojuna Abuja, ni wọn ṣe kongẹ awọn janduku ti wọn bẹrẹ si i yinbọn yii, ti Bomoi Suleiman Yusuf si ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ajọ to n mojuto awọn aginbanirọ sọ pe awọn mẹrindinlogun yooku ko si lọwọ awọn ajinigbe rara, kaluku lo ti gba ile wọn lọ, bẹẹ lo jẹ ohun ibanujẹ lori bi ọkan ninu wọn ti wọn jọ kuro nipinlẹ Ọṣun ṣe ba iṣẹlẹ buruku yii lọ.