Ijọba apapọ kede isinmi ọjọ mẹta fun ayẹyẹ ọdun

Ni bayii, ọjọ mẹta gbako ni ijọba apapọ ti kede ki awọn ọmọ Naijiria fi sinmi ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun.

Minisita fun ọrọ Abẹle, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, lo sọrọ ọhun lorukọ ijọba apapọ pe ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu yii, ati ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, ati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ ki-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021, ni isinmi yoo fi wa fawọn eeyan lati fi ṣọdun.

Ninu ọrọ ẹ naa lo ti ki awọn Kristẹni ku ayẹyẹ ọdun, bẹẹ lo rọ wọn ki wọn lo ifẹ Olugbala lati fi wa iṣokan ni Naijiria. Bakan naa lo rọ wọn ki kaluku ma ṣe gbagbe ofin ati ilana to de itankalẹ arun Koronafairọọsi lasiko ti wọn ba n ṣayẹyẹ ọdun.

Ṣiwaju si i, o ni igbesẹ ijọba apapọ ni lati wa bi aye yoo ṣe rọrun fun eeyan bii ọgọrun-un miliọnu ni Naijria, ti a ba maa fi ri ọdun mẹwaa si i.

Bẹẹ lo tun ke sawọn eeyan orilẹ-ede yii lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati gbogun ti awọn ajinigbe atawọn aṣẹmi-eeyan-lofo ti wọn n da nnkan ru ni Naijiria bayii. O ni o ṣe pataki ki awọn to ba ni aṣiri bi ọwọ ṣe le tẹ awọn eeyan ọhun maa ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn agbofinro, ki wahala awọn janduku le dopin.

Arẹgbẹṣọla ti waa fi awọn eeyan orilẹ-ede yii lọkan balẹ pe ọdun 2021 yoo dara ju 2020 yii lọ, bẹẹ lo rọ awọn Kristẹni lati lo akoko yii fi gbadura fun ọjọ iwaju rere fun Naijiria.

Leave a Reply