Ọkọ mi mu awọtẹlẹ mi lọ sile oniṣegun, o fẹẹ fi ṣoogun owo- Fatima

Ọlawale Ajao, Ibadan

Igbeyawo oọdun meje to wa laarin tọkọ-tiyawo kan, Azeez Akinyẹle ati Fatima Akinyẹle ti fori ṣanpon. Iyawo lo mu ẹjọ ọkọ rẹ lọ si kootu, o ni gbogbo ọna lati pa oun ṣoogun owo lọkọ oun n wa, o si ti figba kan mu nnkan oṣu oun lọ sile oniṣegun lati ṣetutu ọla.

O waa rọ ile-ẹjọ ibilẹ Ọjaba to wa ni Mapo, n’Ibadan, lati fopin si igbeyawo ọdun mẹfa to wa laarin oun ati olujẹjọ.

Afeez naa ko jẹ ki ọrọ olupẹjọ tutu, o loun paapaa fara mọ kile-ẹjọ tu igbeyawo awọn ka nitori iyawo oun ki i ṣe abiamọ gidi, kaka ko maa kọ ọmọ niwa ọmọluabi gẹgẹ bii awọn abiamọ gidi, gbogbo ọna ti aye ọmọ naa yoo gba bajẹ lo n san.

“Nṣe lo mu ọmọkunrin kan ṣoṣo ta a bi kuro nileewe, to si n fi ọmọ ṣọ ile ọti to n ta, ko fẹ ki ọmọ mọ nnkan gidi, afi ọti ati igbo mimu”, bẹẹ lọkunrin oniṣẹ ọwọ naa ṣalaye niwaju igbimọ awọn adajọ.

Ṣaaju lolupẹjọ ti ṣapejuwe ọkọ ẹ gẹgẹ bii ọdaju eeyan, ati pe ki i ṣe ojuṣe ẹ gẹgẹ bo ṣe yẹ lori oun atọmọ awọn.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “O fẹẹ fi mi ṣoogun owo. Awọn awọtẹlẹ mi ti mo rẹ sinu omi lọjọ kan lo gbe lọ sile oniṣegun. Nigba ti mo lọ sidii aṣọ yẹn lati fọ ọ ni mi o ba a nibi ti mo gbe e si mọ, ataṣọ ati bọ́kẹ́ẹ̀tì, ko si eyi ti mo ri nibẹ. Nibi ti ọrọ yii ti n ṣe mi ni kayeefi lọwọ ni mo ri ọkọ mi lọọọkan to n gbe ike ti mo rẹ awọn awọtẹlẹ mi si ninu bọ lọọọkan. Nigba ti ma a wo inu ike, ko si aṣọ kankan ninu ẹ.

“Njẹ awọn aṣọ ti mo rẹ sinu ike yii n kọ, o loun ko mọ nipa aṣọ kankan ni toun o, omi to wa ninu bọ́kẹ́ẹ̀tì loun lọọ danu, oun ko si kiyesi aṣọ kankan ni toun.”

“Iṣẹ abẹ ni mo fi bi ọmọ kan ṣoṣo ti mo bi fun un. Ti emi atọkọ mi ba ti waa ja, ki i ri ibomi-in lu lara mi ju oju ibi ti wọn ti ṣiṣẹ abẹ fun mi lọ. Gbogbo wahala yẹn naa lo jẹ ki n kuro nile ẹ ko too pa mi.

“Ko jẹ ki n mọ ileewe ti ọmọ mi n lọ. Ko tun fun mi lanfaani lati maa ba a sọrọ. O ni ki n ra foonu fọmọ ti mo ba fẹẹ maa ba a sọrọ. Mo ra foonu fọmọ tan, o tun gba foonu lọwọ ọmọ, o fun ọkan ninu awọn iyawo ẹ to n fẹ.

“Lọjọ ti mo lọ sile ẹ pe ki n tiẹ le ri ọmọ mi. niṣe lọkọ mi o jẹ ki n wọle. Nigba ti mo yari mọ ọn lọwọ lo tu bẹliiti nidii pe oun maa fi lu mi. Iyẹn lo jẹ ki emi naa lọọ pàgò pe mo maa gun un nigo pa ni.’’

Nigba to n fara mọ ọrọ iyawo ẹ pe kile-ẹjọ tu igbeyawo awọn ka, Azeez, ẹni to ta ko ẹsun oogun owo ti iyawo ẹ fi kan an, sọ pe oniwahala eeyan kan lobirin naa, igo lo maa n pa lati fi ba oun ja nigbakugba ti ọrọ ba ṣe bii ija laarin awọn, eyi ko si fi gbogbo ara jọ oun loju nitori ki i ṣe iṣẹ gidi lo n ṣe, ọti lo n ta. Ọti yẹn naa lo si fẹẹ fi baye ọmọ jẹ to fi mu ọmọ kuro ni sukuub to fi i ṣọ ilẹ ọti.

O waa rọ ile-ẹjọ lati ma ṣe gba olujẹjọ laaye lati mu ọmọ kan ṣoṣo to so igbeyawo wọn pọ sọdọ, o ni obinrin naa yoo kan ba aye ọmọ ọhun jẹ ni, bo tilẹ jẹ pe oun naa lo bi i.

Ṣugbọn lẹyin ti Oloye Ọdunade Ademọla ti i ṣe ọga awọn adajọ kootu ọhun, pẹlu awọn igbimọ rẹ, Alhaji Suleiman Apanpa ati Alhaji Rafiu Raji, ti fopin si igbeyawo naa, olupẹjọ ni wọn papa yọnda itọju ọmọ kan ṣoṣo to wa ninu igbeyawo ọhun fun. Wọn si paṣẹ fun olujẹjọ lati maa fi ẹgbẹrun marun-un Naira (N5000) ranṣẹ si olupẹjọ loṣooṣu lati maa fi tọju ọmọ naa.

Leave a Reply