Ọṣun 2022: Idajọ kootu tun da wahala silẹ laarin Adeleke ati Babayẹmi

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Titi digba ti a n ko iroyin yii jọ ni awọn ti wọn n ṣatilẹyin fun awọn oludije mejeeji ti wọn n ja si tikẹẹti ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun; Sen. Ademọla Adeleke, ati Ọmọọba Dọtun Babayẹmi, n bara wọn jiyan lori idajọ kan to waye lori wahala wọn.

Adajọ ile-ẹjọ giga ipinlẹ Oṣun to wa niluu Ijẹbu-jẹṣa, Onidaajọ Yinka Aderibigbe, lo dajọ pe ki ẹjọ ti Ọgbẹni Adedokun Ademọla atawọn mọkandinlọgbọn mi-in pe lọ sodo lọọ mumi lai fi asiko ti igbẹjọ naa yoo tẹsiwaju silẹ (Sine die).

Ṣaaju ni Onidaajọ Adeyinka Aderibigbe ti sọ pe awọn aṣoju, dẹligeeti, ti wọn dibo yan Babayẹmi lọjọ idibo abẹle ẹgbẹ naa jẹ ojulowo, wọn si ṣe bẹẹ nibaamu pẹlu idajọ ile-ẹjọ kan to waye lọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2021.

Idajọ yii, gẹgẹ bi Aderibigbe ṣe ṣalaye, lo fidi rẹ mulẹ pe awọn aṣoju okoolelugba o din marun-un kaakiri wọọdu nipinlẹ Ọṣun lẹtọọ lati dibo gẹgẹ bii dẹligeeti ninu idibo ti wọn yoo fi mu ọmọ-oye fun ibo gomina.

Bakan naa ni kootu paṣẹ fun ẹgbẹ PDP ati ajọ INEC lati ma ṣe fọwọ si idibo abẹle miiran yatọ si eyi ti wọn ti yan Babayẹmi.

Ṣugbọn nigba ti wọn tun pada de kootu l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, Aderibigbe ni oun ti ri iwe gba pe awọn olujẹjọ (Adeleke) ti gbe idajọ naa lọ siwaju ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, o si pọn dandan ki ile-ẹjọ giga kararo lori igbesẹ kigbesẹ to ba tun fẹẹ gbe.

Idi niyi to fi sọ pe ile-ẹjọ oun ko le ṣe ohunkohun tabi gbọ awuyewuye kankan mọ lori ọrọ naa.

Kia ni alakooso eto iroyin fun eto ipolongo Ademọla Adeleke, Mallam Ọlawale Rasheed, bọ sita, o ni ọrọ ti Onidaajọ Aderibigbe sọ ọhun ti yanju gbogbo wahala to wa nilẹ, o si tumọ si pe Sẹnetọ Ademọla Adeleke ni oludije kan ṣoṣo ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni l’Ọṣun.

Ọlawale ṣalaye pe ọjọ meje pere ni ofin faaye rẹ silẹ lati ka awọn alakooso apapọ ẹgbẹ (NWC) lapa ko lori ọrọ Adeleke, ọjọ meje naa si ti pe bayii, kootu si ti sọ pe ko le si igbesẹ kankan lori rẹ mọ, a jẹ wi pe idiwọ ati idena ti kuro lọna Adeleke.

O ni asiko ti to fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ PDP, paapaa, awọn ti inu n bi, lati fọwọsowọpọ pẹlu Ademọla Adeleke lati le koju ọta kan ṣoṣo ti wọn ni, iyẹn ẹgbẹ oṣelu APC, lasiko idibo oṣu Keje, ọdun yii.

Ṣugbọn agbẹjọro fun Babayẹmi, Edmund Biriomoni, sọ pe ki awọn Adeleke tete tẹti silẹ daadaa, Babayẹmi nikan ni oludije fun ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ọṣun, oun nikan si ni ofin da mọ.

Ninu atẹjade kan to fi sita lo ti ṣalaye pe iyalẹnu lo jẹ fun oun pe awọn Adeleke ko mọ itumọ idajọ ti Onidaajọ Aderibigbe gbe kalẹ lori ọrọ naa. O ni kikawọro ile-ẹjọ ko tumọ si pe ẹjọ naa ti pari.

Biriomoni sọ siwaju pe ohun ti ile-ẹjọ n sọ ni pe ki gbogbo nnkan wa bo ṣe wa ni abala mejeeji, eleyii to tumọ si pe idajọ to fọwọ si idibo Babayẹmi ṣi wa bo ṣe wa, ko si nnkan ti ẹnikẹni le ṣe si i.

O ni ayọ awọn alailoye ofin ni wọn n yọ nitori idajọ naa naa tumọ si pe ko si nnkan ti yoo yatọ titi ti ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun yoo fi gbọ ẹjọ ti wọn gbe lọ siwaju ẹ.

Leave a Reply