Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọlọkada kan, Ọgbẹni Kabiru, to n na agbegbe Iwo Road si Mọkọla, n’Ibadan, pẹlu ero to gbe lẹyin, ti riku ojiji he. Waya ina to ja lu awọn mejeeji lo ṣeku pa wọn.
Ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, niṣẹlẹ ọhun waye nigba ti ọlọkada yii pẹlu ero to fẹẹ gbe jọ n dunaa-dura lọwọ.
Ina ilẹtiriiki to wa lara waya ọhun lo gbe wọn, ti awọn mejeeji si gan pa loju ẹsẹ.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, gbese ẹgbẹrun kan Naira (N1,000) ti awakọ kan jẹ obinrin to maa n kiri ounjẹ yii lo lọọ sin onimọto to ra ounjẹ àwìn lọwọ ẹ ni garaaji awọn awakọ naa laduugbo Iwo Road, to fi ba iku ojiji pade nibi to ti n gbiyanju lati gun ọkada pada si ṣọọbu to ti wa.
Ẹgbẹrun kan Naira ọhun ti onibaara rẹ fun un lowo to tobi ju lọ ti wọn ba lọwọ obinrin olounjẹ naa nigba to ku tan.
Ọkan ninu awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣalaye fakọroyin wa pe awọn oṣiṣẹ Federal Road Safety Corps, FRSC, iyẹn, ẹṣọ alaabo oju popo ni wọn gbe oku awọn mejeeji kuro loju titi.
Oludari ajọ FRSC ni ipinlẹ Ọyọ, Abilekọ Uche Chukwura, fidi ẹ mulẹ pe ileewosan Adeọyọ, n’Ibadan, ti i ṣe ileewosan ijọba ipinlẹ Ọyọ lawọn lọọ tọju awọn oku ọhun pamọ si.