Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Lati le dẹkun itankalẹ arun Koronafairọọsi, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kan an nipa fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba lati gba abẹrẹ to n dena arun naa.
Ẹnikẹni to ba si kuna lati gba abẹrẹ naa laarin ọsẹ mẹta ko ni i lanfaani lati wọnu sẹkiteriati ijọba.
Oludamọran pataki fun gomina Oyetọla lori ọrọ ilera, Dokita Ṣiji Ọlamiju, lo sọrọ yii fawọn oniroyin. O ni ki gbogbo awọn oṣiṣẹ patapata lọ sileewosan ijọba to wa ninu sẹkiteriati lati gba abẹrẹ naa.
“A ti fun awọn oṣiṣẹ ijọba patapata ni ọsẹ mẹta pere lati lọo gba abẹrẹ naa. Olori awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ itaniji lori igbesẹ naa laarin awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn olori ileeṣẹ nla nla.
“Lẹyin oore-ọfẹ ọsẹ mẹta yii, ẹnikẹni to ba tun fẹẹ ya aletilapa, to kọti ikun si ikilọ yii, yoo ri pipọn oju ijọba. Gbogbo nnkan ti wọn nilo fun ayẹwo ati gbigba abẹrẹ yii lo ti wa nileewosan ijọba”
Bakan naa ni olori awọn oṣiṣẹ l’Ọṣun ti gbe atẹjade kan sita, ninu eyi to ti paṣẹ fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba, titi dori awọn oṣiṣẹ kaakiri awọn ile-ẹkọ giga lati lọọ gba abẹrẹ yii.
Atẹjade naa, eleyii ti akọwe agba lọfiisi olori awọn oṣiṣẹ ijọba, S. A. Aina, fọwọ si ṣalaye pe igbesẹ naa wa lati le fopin si itankalẹ arun naa nipinlẹ Ọṣun.