Ọṣọba atọrẹ ẹ pa Buhari sinu ile akọku, ni wọn ba gbe ọkada ẹ lọ n’Ilogbo

Gbenga Amos, Abẹokuta

Awọn afurasi ọdaran meji yii, Yakubu Ọṣọba ati Ismail Hameed, ti jẹwọ fawọn ọlọpaa ẹka ileeṣẹ wọn to wa ni Sango, pe adigunjale gidi lawọn, ati pe loootọ lawọn ṣeku pa ọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn kan, Yusuf Buhari, tawọn si gbe ọkada rẹ lọ.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde, ogunjọ, oṣu Kẹta yii, o ni baba ọmọ ti wọn da ẹmi lẹgbodo ọhun, Ọgbẹni Saliu Buhari, lo waa fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii,  pe oun ri ọmọ oun lati ọjọ kẹrinla, oṣu naa, iṣẹ ọkada lo ṣe lọ, awọn o si mọ bo ṣe le dawati lojiji.

Ọjọ keji lawọn araalu ti wọn jọ n wa Yusuf lọọ kan oku rẹ nile akọku kan labule Ararọmi, niluu Ilogbo, oku rẹ nikan ni wọn ri, wọn o ri ọkada rẹ.

Kia lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti DPO Sango, SP Saleh Dahiru ṣeto, to lọ sibi iṣẹlẹ yii, wọn palẹ oku naa mọ, wọn si fa a le awọn mọlẹbi oloogbe lọwọ ki wọn le lọọ si ni ilana ẹsin Musulumi to n ṣe, lẹyin naa ni wọn fọnka saduugbo naa, awọn ati oṣiṣẹ fijilante atawọn oṣiṣẹ So-Safe si bẹrẹ si i fimu finlẹ lati mọ awọn to huwa ọdaju bẹẹ.

Ko pẹ tọwọ wọn fi ba Ismail Hammed ni tiẹ, wọn ba ọkada oloogbe naa lọwọ ẹ, oun lo si jẹ ki wọn tete ri ọrẹ rẹ, Ọṣọba, mu, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe wọn.

Awọn afurasi ọdaran naa jẹwọ pe o pẹ tawọn ti n digunjale, wọn lawọn maa n fọle, awọn si maa n ja ọkada ọlọkada gba.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti paṣẹ ki wọn taari keesi wọn, ati ọkada ti wọn ji ọhun, si ẹka to n tọpinpin iwa ọdaran, ki wọn le tubọ ṣalaye ara wọn daadaa, ẹyin naa ni wọn maa foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply