Ọṣun 2022: Ẹnikẹni to ba da wahala silẹ lasiko idibo yii yoo ri ija Ogun ati Ṣango – TRWASO

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn aṣaaju ẹgbẹ ẹlẹsin abalaye, (Traditional Religion Worshippers Association), ẹka tipinlẹ Ọṣun ti ṣekilọ fun awọn oloṣelu lati ma ṣe da wahala silẹ lasiko idibo gomina ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii.

Ẹgbẹ naa sọ pe ẹnikẹni to ba ṣan aṣọ jagidijagan ṣoro lasiko idibo naa yoo ri ibinu Ṣango ati Ogun, idi si niyi ti wọn fi n ke pe ki gbogbo wọn yago fun ohunkohun to le fa hilahilo.

Ninu atẹjade kan ti Aarẹ Trwaso, Dokita Oluṣeyi Atanda, fọwọ si layaajọ ọdun kin-in-ni to ti n dari ẹgbẹ naa lo ti rọ gbogbo awọn ẹlẹsin to ku lati bẹrẹ adura gidigidi lori idibo naa.
Atanda ṣalaye pe wọn gbọdọ gbadura ta ko wahala, bẹẹ ni awọn oloṣelu atawọn ọmọlẹyin wọn gbọdọ bọwọ fun ofin lati ma ṣe ṣe ohunkohun to le da omi alaafia ipinlẹ Ọṣun ru.

O ni, “Ni bayii ti a ti n sun mọ gongo oṣelu nipinlẹ Ọṣun, awa ẹlẹsin yoo tẹsiwaju nipa gbigbadura si Ọlọrun Olodumare, bẹẹ la oo maa ṣipẹ fun awọn alalẹ lati ri i pe eto idibo naa lọ nirọwọ-rọsẹ.

“Ẹ jẹ ki n sọ gbangba pe o ṣee ṣe ki awọn alakatakiti oloṣelu kan gbiyanju lati ṣe eto idibo naa ni bo o ba a o pa a, bo o ba a o bu u lẹsẹ, ki ipinlẹ Ọṣun le daru, Ọlọrun Olodumare ko ni i faaye gba eleyii ko ṣẹlẹ.
“Mo fẹẹ rọ gbogbo awọn ẹlẹsin yooku naa lati bẹrẹ adura fun alaafia pipe nipinlẹ Ọṣun, mo si tun ke si awọn ti wọn ni ero jagidijagan ninu lati dawọ rẹ duro, lai jẹ bẹẹ, wọn yoo ri ibinu Ṣango ati Ogun. Ipinlẹ alaafia l’Ọṣun, a si fẹ alaafia fun gbogbo eniyan.
Nigba to n sọrọ nipa awọn aṣẹyọri ẹgbẹ naa laarin ọdun kan sẹyin, Atanda sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ kaakiri ijọba ibilẹ ni wọn ti jigiri, bẹẹ ni iṣẹ ti n lọ lọwọ lori sẹkiteriati ẹgbẹ naa.

Leave a Reply