Ọṣun 2022:Ọkan mi balẹ pe emi ni ma a jawe olubori  

Florence Babaṣọla

Gomina ipinlẹ Ọsun, to tun n dije dupo ninu idibo to n lọ lọwọ, Adegboyega Oyetọla ti ni oun ni igbagbọ ati igboya pe oun loun yoo jawe olubori lẹyin eto idibo to n lọ lọwo nipinlẹ ọhun.

Oyetọla sọrọ yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin to dibo tan ni ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ aarọ ni Wọọdu Kin-in-ni, Yuniiti Keji, to wa ni ileewe alakọọbẹrẹ LA, niluu Iragbiji.

O fi aidunnu rẹ han si bi eto ibo didi naa ṣe falẹ nitori aisi ẹrọ ti wọn fi n dibo to to, eyi to fa a ti ọpọ eeyan fi pọ lori ila. O waa rọ awọn eleto idibo naa pe ki wọn ko awọn ẹrọ idibo wa si agbegbe naa, ki awọn to fẹẹ dibo yii le lanfaani lati ṣe bẹẹ ki akoko too lọ.

Oyetọla sọ pẹlu idaniloju pe oun loun yoo jawe olubori lẹyin idibo naa.

Leave a Reply