Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Pẹlu ibinu lawọn eeyan agbegbe Okelisa, niluu Ondo, fi tu jade lọjọ Aje, Mọnde, oni lati fẹhonu han si bi awọn ole kan ṣe n fi igba gbogbo ji waya ina wọn ka lọ.
Irọlẹ ana lawọn eeyan agbegbe ọhun kọkọ ko ara wọn jọ si idi ẹrọ amunawa ti wọn ṣẹṣẹ ka waya rẹ lọ naa, nibi ti wọn ti jiroro lori igbesẹ to yẹ ki wọn gbe lati fopin si iru iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.
Gbogbo awọn agbaagba atawọn to mọ ọwọ yi pada to wa nibẹ ni wọn pa ẹnu pọ gbe awọn to n fi igba gbogbo sọ wọn sinu okunkun biribiri ọhun ṣepe ki wọn too lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa teṣan Ẹnuọwa leti.
Aarọ kutukutu oni ni wọn lọ si olu-ileeṣẹ BEDC to wa loju ọna marosẹ Ademulẹgun lati fi ẹdun ọkan wọn han awọn to n mojuto ina ọba niluu Ondo ọhun.