O ṣẹlẹ, awọn Fulani rẹpẹtẹ ti tun ya wọ Igangan, aṣọ bii tawọn Amọtẹkun ni wọn wọ

Faith Adebọla

Ko jọ pe iṣoro iwa ọdaran, ijinigbe, ipakupa ati biba ire oko awọn agbẹ jẹ lagbegbe Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, yoo lọ bọrọ pẹlu bi wọn ṣe lawọn Fulani rẹpẹtẹ kan ti tun ya wọ agbegbe naa laarin ọsẹ yii.
Igbakeji kọmandanti Amọtẹkun ti Ariwa Ibarapa, Kọmureedi Ishiau Adejaren ba ALAROYE sọrọ laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, o fidi ẹ mulẹ pe olobo ti ta awọn pe awọn Fulani ọhun gba ọna Imẹkọ, nipinlẹ Ogun, wọnu igbo to wa lẹbaa ilu Igangan.
O ni iṣoro nla kan to tiẹ tun yọju ni pe aṣọ pupa bii ti awọn ẹṣọ Amọtẹkun lo wa lọrun awọn afurasi ọdaran Fulani naa, wọn si ti n ṣe awọn agbẹ to n lọ soko wọn lẹṣe.
O ni lati Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, ni iṣẹlẹ buruku ti n waye, tawọn Fulani naa n yinbọn lu awọn agbẹ lọna oko. O lo tun ṣẹlẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, omi-in si tun ṣẹlẹ lọjọ Abamẹta, Satide, bo tilẹ jẹ pe ori ko awọn agbẹ naa yọ.
Ọgbẹni Wasiu Mukaila toun naa jẹ ara ẹṣọ Amọtẹkun kin ọrọ ọhun lẹyin, o ni ibọn AK-47 gidi lawọn to kofiri awọn Fulani naa ko dani, ti wọn si pin ara wọn kaakiri awọn agbegbe bii Alagbaa, Kajọla, lọọ de Konko, titi de Oke-Ayinṣa. O ni niṣe lawọn Fulani naa fẹẹ yii gbogbo awọn ilu Oke-Ogun po.
O lawọn Fulani wọnyi mura ija gidi ni, wọn ko da maaluu rara, ko si maaluu kankan pẹlu wọn, ẹmi igbẹsan lo jọ pe o wa ninu wọn.
Ni bayii, gẹgẹ bi Adejare ṣe wi, awọn agbẹ ko le lọ soko eyikeyii, atoko etile, ati tọna jinjin, niṣe lo da bii pe awọn Fulani naa se gbogbo wọn mọle. Aarun ilu nikan lawọn eeyan ti n rin.

Leave a Reply