O ṣẹlẹ, awọn tọọgi ya wọ ile-igbimọ aṣofin Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn tọọgi kan ya bo ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti wọn si kọ jalẹ lati fun awọn aṣofin kan laaye lati wọ ọgba ile-igbimọ ọhun.

Ọsẹ bii meji sẹyin n’ile-ẹjọ giga kan niluu Akurẹ fagi le iwe gbele-ẹ ti wọn ja fun igbakeji abẹnugan ile, Ọnarebu Irọju Ogundeji, atawọn mẹta mi-in.

Adajọ ọhun ni ki wọn da wọn pada saaye wọn loju lẹyẹ-o-ṣọka, o ni ohun to lodi sofin patapata ni bi wọn ṣe n di awọn aṣofin naa lọwọ ati ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bii aṣoju awọn to dibo yan wọn.

Igbakeji abẹnugan ni wọn kọkọ ti geeti mọ lọsẹ to kọja, ti wọn si kọ lati jẹ ko wọle sinu ọgba ile-igbimọ ọhun lọjọ naa.

Ọsẹ yii kan naa ni wọn fẹsun kan Gomina Rotimi Akeredolu pe o pin ọkọ jiipu tuntun fun gbogbo awọn aṣofin to jẹ alatilẹyin rẹ, ṣugbọn ti ko ra fun awọn aṣofin mẹsan-an to kọ lati buwọ lu iwe iyọnipo Ajayi Agboọla.

Awọn tọọgi ọhun ni wọn si wa layiika ile-igbimọ aṣofin naa ni gbogbo asiko ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ.

Leave a Reply