Adeoye Adewale
Ọrẹ ki i ya ọrẹ, akobani ki i yara wọn, bẹẹ lọrọ ri fun awọn baba agbalagba meji kan, Ademọla Idowu, ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin, to fipa ba ọmọ bibi inu rẹ to jẹ ọmọ ọdun meje sun.
Awọn ọlọpaa agbegbe Ijagun, niluu Ijẹbu-Ode, nibi ti baba naa n gbe lawọn ti fọwọ ofin mu baba agbaaya ọhun ati Oluwatobi Adebisi, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, to je araale ibi ti Idowu n gbe, toun naa n ba ọmọde naa sun nigba gbogbo.
ALAROYE gbọ pe lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, lawọn ọlọpaa lọọ fọwọ ofin mu awọn ọdaran mejeeji yii nile ti wọn n gbe, ti wọn si ti wa lahaamọ wọn bayii.
Ninu ọrọ Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, C.P Abiodun Alamutu, lori iṣẹlẹ ọhun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun yii, ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to wa ni Eleweran, niluu Abẹokuta, lo ti sọ pe awọn ara agbegbe ibi ti Idowu n gbe ti wọn mọ iru iṣẹ buruku ti baba naa ati ayalegbe rẹ n ṣe pẹlu ọmọ ọhun ni wọn waa fọrọ ọhun to awọn leti, tawọn si lọọ fọwọ ofin mu awọn mejeeji bayii.
Ọga ọlọpaa ọhun ni gbara tawọn ti gba ọmọ naa lakata awọn ọdaran yii lawọn ti mu un lọ si ẹka ileeṣẹ ijọba kan to maa ṣatunṣe si igbesi aye ọmọ ohun.
Bakan naa la gbọ pe kọmiṣanna yii ti ni ki wọn lọọ fa awọn ọdaran mejeeji ọhun le ikọ ọlọpaa kan ti wọn maa n ri sọrọ awọn ọdaran paraku nipinlẹ naa lọwọ, ki wọn le ṣewadi daadaa lori ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan awọn mejeeji.
O ni lẹyin iwadii tawọn ba ṣe lori ọrọ naa lawọn maa too foju awọn ọdaran naa bale-ẹjọ, ki wọn le jiya ẹṣẹ wọn.