O ṣẹlẹ, Pasitọ James fipa ba ọmọ ijọ ẹ lo pọ ni Lekki, lo ba ni isẹ eṣu ni

Faith Adebọla, Eko

Ahamọ ni Pasitọ James wa bayii, awọn ọlọpaa ni wọn sọ ọ sibẹ nigba tọwọ tẹ ẹ nigba to n sa lọ latari ẹsun pe o fipa ba ọmọ ijọ ẹ ti ko ju ọmọ ọdun mejila lọ laṣepọ.

Ọgbẹni Titus Ọlawale to lọrọ ọhun ṣoju oun so f’ALAROYE pe ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, niṣẹlẹ naa waye, laduugbo Ologolo, lagbegbe Lekki, Ajah, nipinlẹ Eko.

Ọkunrin to loun jẹ oluṣọ-aguntan ninu ọkan lara awọn ṣọọṣi to wa lagbegbe naa ni pasitọ yii lo wawọ si ọmọbinrin ọhun nigba tiyẹn n kọja lọ, o ni ko ran oun lọwọ lati ko ẹru kan to di kalẹ, lọmọ naa ba tẹle e nigba to jẹ pasitọ ṣọọṣi to n lọ ni.

Wọn lọmọbinrin naa ṣalaye lẹyin iṣẹlẹ naa pe boun ṣe wọle, niṣe ni afurasi ọdaran yii ti oun lu bẹẹdi kan to wa nilẹẹlẹ yara naa, lo ba bẹrẹ si i bọ pata nidii oun. O ni boun ṣe bẹrẹ si i pariwo ni pasitọ naa fi ọwọ di oun lẹnu, igba to si ya lo yi aṣọ mọ oun loju ati ẹnu.

Ẹnikan laduugbo naa ni wọn lariwo ti ọmọ naa kọkọ pa ta si leti, onitọhun lo pe akiyesi awọn ọdọ to wa laduugbo sọrọ ọhun pe o da bii pe nnkan aburu kan n ṣelẹ ninu ile naa.

Wọn ni nigba tawọn ọdọ naa yoo fi de ile ọhun, Pasitọ James ti fipa ba ọmọ ọlọmọ yii sun, bo si ṣe kiyesi i pe awọn kan ti fura soun lo ba sa gba ọna odikeji ile jade.

Ṣugbọn awọn ọdọ naa lepa ẹ, wọn si ri i mu, ni wọn ba fokun so ọwọ ẹ sẹyin, ki wọn too tẹ teṣan ọlọpaa laago.

Titus loun naa gbọ finrin ariwo tọmọ naa n pa pe, ‘Dadi ẹ jọọ, Dadi ẹ jọọ, ṣugbọn oun ko mọ pe itosi ile oun niṣẹlẹ buruku naa ti n waye, ati pe oun kọkọ ro pe boya obi kan lo n ba ọmọ rẹ wi ni, igba toun fi maa yọju sibẹ, niṣe lẹjẹ n jade labẹ ọmọbinrin naa latari bi pasitọ yii ṣe ṣe e baṣubaṣu.

Pako ni wọn ni Pasitọ James n wo nigba tawọn ọdọ naa fokun so o lọwọ ati lẹṣẹ, o ni ki wọn dariji oun, pe iṣẹ eṣu ni.

Ko pẹ tawọn ọlọpaa fi de lati teṣan wọn to wa ni Jakande, wọn si fi pampẹ ofin gbe pasitọ naa de agọ wọn lati bẹrẹ iwadii. Wọn lawọn obi ọmọbinrin naa ti mu ọmọ wọn lọ sileewosan fun itọju.

A gbiyanju lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lọdọ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, ṣugbọn titi ti a fi ko iroyin yii tan, Ọgbẹni Muyiwa Adejọbi ko gbe aago rẹ, bẹẹ ni ko ti i fesi si atẹjiṣẹ ta a fi ranṣẹ si i.

Leave a Reply