O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Awọn ọmọ Yoruba lawọn o ṣe mọ, abọran ni

Awọn Yoruba ti wọn wa ni Kogi ni awọn fẹẹ darapọ mọ awọn eeyan awọn ni ilẹ Oodua. Awọn ọmọ Oodua ti wọn wa ni Kogi naa ni awọn n bọ nilẹ Yoruba lọdọ awọn ọmọ baba awọn. O ti fẹẹ di ojoojumọ ti gbogbo ẹya loriṣiiriṣii n sọ bayii pe awọn ko ṣe Naijiria mọ. Bẹẹ ki i ṣe ijọba ta a kọkọ ni ni Naijiria niyi, a ti ni awọn kan ṣaaju ijọba Buhari yii jare. Ọrọ agba, bi ko ṣẹ lowurọ, yoo ṣẹ lalẹ, bẹẹ ni ọmọde to ba n tẹle ti agba, yoo mọ ọna ti yoo gba lati koju iṣoro to ba ba a. Ọrọ aarẹ ana, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, leeyan yoo ro debẹ, ati awọn mi-in ti wọn ti sọrọ lori bi ijọba Buhari to wa nita yii ṣe n sọ awọn ọmọ Naijiria di ọta ara wọn. Awọn nnkan kan wa ti ijọba yii ṣe ti ko dara, ṣugbọn awọn ti wọn wa lẹgbẹẹ Buhari ko ni ba a sọ ootọ ọrọ, kaka bẹẹ, wọn yoo maa tan an, wọn yoo maa ni awọn n gbeja rẹ, wọn yoo si maa purọ fun un. Bi Buhari ba tilẹ fẹẹ si ẹsẹ gbe, tabi to ba fẹẹ ṣiwa-hu, kin ni anfaani awọn amugbalẹgbẹẹ, awọn abanidamọran ti Aarẹ ko jọ, nigba ti wọn ko ba le sọ ododo fun un. Tabi ninu gbogbo awọn yii, ta ni yoo sọ  pe oun ko mọ pe ko si igba kankan ti awọn ẹya Fulani di ologomu-gomu si Naijiria lọrun, ti wọn n paayan, ti wọn n jiiyan gbe, ti ijọba ati awọn ọlọpaa ko si ṣe bii ẹni to fi taratara kọju si ọrọ wọn, to fi di pe gbogbo aburu to wu wọn ni wọn n ṣe. Ẹgbẹ Miyetti Allah wa niluu yii, ti wọn yoo ni awọn lawọn ni Naijiria, ko si baba ẹni to le le awọn ni oko oloko, ni ilẹ onilẹ, ni ilu oniluu, pe ko si ohun ti awọn ko le ṣe. Awọn ẹgbẹ Arewa ọmọ kekere wa nibẹ ti wọn ni awọn yoo ṣe ijọba ati olori Naijiria titi aye, ẹni ti ko ba si gba ko lọọ pokunso, ẹni to ba si koju awọn, awọn yoo pa tọhun rẹ. Loju ijọba yii lawọn ẹya yii ṣe n bu Yoruba, ti wọn n bu Ibo, ti ijọba Buhari ko si mu wọn. Ṣugbọn bo ba ṣe Ibo lo sọrọ bẹẹ, wọn yoo dẹ ṣọja si i, bo ṣe Yoruba lo wi kinni kan, wọn yoo dẹ DSS si i. Gbogbo eleyii lo fi han pe ijọba yii n gbe si ẹyin ẹni kan, ohun to si n bi awọn ẹya mi-in ninu ree. Tabi ti ka gba iṣẹ lọwọ Yoruba, ka gbe e fun Ibo tabi Hausa leeyan yoo sọ ni, tabi ti awọn ofin oriṣiiriṣii, bii kaa fẹẹ gba gbogbo ilẹ awọn mi-in fun Fulani, bii ka fẹẹ gba gbogbo eti omi fawọn Fulani lorukọ ijọba apapọ, ko si ẹya kan ti inu rẹ yoo dun si eyi nigba ti wọn ba mọ pe ijọba apapọ ko ṣiṣẹ fawọn, awọn ẹya awọn ti wọn n ṣejọba ni ijọba apapọ n ṣiṣẹ fun. Ohun ti kaluku ṣe n pariwo awọn fẹẹ kuro ni Naijiria ree. Ọjọgbọn Banji Akintoye, olori awọn ẹgbẹ ọmọ Yoruba, ti sọrọ, o ni Yoruba gbọdọ kuro ni Naijiria lai si itajẹsilẹ kan, tabi ifarapa ẹni kan. Ọpọ ọmọ Yoruba lo jọ pe o fara mọ ohun ti baba yii n sọ, ko si ohun meji to fa a ju iwa ijọba ati awọn ti wọn n ṣejọba yii lọ. Ṣe bi wọn yoo ti maa ṣejọba naa ree, bo ba ṣe bi wọn yoo ti maa gbe Fulani gori awọn ẹya to ku ni Naijiria niyi, ki wọn jẹ ki kaluku ṣe tirẹ lọtọ, ki ẹni to ba fẹẹ lọ maa lọ, ki kaluku gba ile lbaba rẹ lọ. A ki ba ni tan ka fa ni nitan ya, bi Naijiria ko ba gbe wa mọ, ẹ jẹ ka maa ba tiwa lọ. Abi ọran ni!

 

Funra yin naa lẹ oo lu APC Ekiti fọ pata

Ṣe ẹyin naa ri oriṣiiriṣii idan to lọ lọsẹ to kọja. Awọn kan dide ninu APC ipinlẹ Ekiti, wọn ni awọn ti yọ awọn kan kuro ninu ẹgbẹ naa. Wọn darukọ Babafẹmi Ojudu ati awọn mi-in bẹẹ. Ẹni to ba ti gbọ awọn orukọ ti wọn da yii yoo ti mọ pe ọrọ naa yoo mu wahala dani. Babafẹmi Ojudu ki ṣe ẹni yẹpẹrẹ ninu APC l’Ekiti, bẹẹ lo tun jẹ oludamọran fun Aarẹ. Ko si bi iru ipinnu bẹẹ ti awọn kan ṣe yii ko ṣe ni i mu wahala dani. Ki ilẹ si too ṣu lọjọ yii kan naa, awọn yii ti ni awọn naa yọ Fayẹmi ninu ẹgbẹ wọn, n lọrọ ba di rudurudu. Ohun ti awọn eeyan maa n beere bi iru nnkan bayii ba ṣẹlẹ ni pe ki lo maa n fa ija ajadiju laarin awọn ti wọn maa n pe ara wọn ni ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa. Ki lo maa n de ti wọn ki i lee yanju ọrọ to ba ṣẹlẹ laarin wọn funra wọn. Ohun tawọn yii ṣe maa n beere bẹẹ ni pe bi eeyan ba jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa, o yẹ ki ọrọ awọn olori ẹgbẹ wọn le dọgba, ki ipinnu ti wọn ba si fẹẹ ṣe le jẹ ọkan. Ṣugbọn ki i ri bẹẹ ni ọdọ tiwa nibi, paapaa nilẹ Yoruba yii, nitori awọn oloṣelu wa ko si nibẹ nitori pe wọn fẹran araalu, tabi pe wọn kuku loore kan pato ti wọn fẹẹ ṣe fun wọn, nitori tara wọn ni wọn ṣe n ṣe e, ija buruku to si maa n ṣẹlẹ nidii ẹ, ija ẹni ti yoo ṣakoso ẹgbẹ ni. Ṣebi ẹni to ba ṣakoso ẹgbẹ ni nnkan yoo maa dun fun, oun ni yoo maa paṣẹ, ti yoo si maa ṣeto ipo ati owo nina, ohun ti gbogbo oloṣelu si n fẹ niyẹn. Kẹnikẹni ma ro pe ija awọn aṣaaju APC yii, nitori awọn ara Ekiti tabi ilọsiwaju APC funra ẹ ni, nitori tara wọn lasan ni. Bẹẹ o digba ti a ba jawọ ninu iru oṣelu bayii ki nnkan wa too dọgba nilẹ yii, nitori oṣelu ti a n ṣe lọwọlọwọ bayii, oṣelu ti ko ni i mu ilọsiwaju ba orilẹ-ede tabi ipinlẹ kankan ni.

 

Bẹẹ bo ṣe yẹ ko ri ni Akeredolu wi yii o

Arakunrin Rotimi Akeredolu sọrọ kan. Nigba ti wọn n sọrọ lori Amọtẹkun ni. Asiko ti wọn n halẹ mọ ọn pe ti ko ba jawọ ninu kinni naa, wọn ko ni i fa a kalẹ ninu ẹgbẹ APC ko ṣe gomina lẹẹkeji ni. O sọrọ akin nigba naa, ọrọ naa ni awọn kan si n gbe kiri bayii pe o fi ri awọn ara Ondo fin. Ohun to wi ni pe ki ẹru ma ba ẹnikẹni, ki ẹnikẹni ma ṣe bẹru mọ, tabi ṣe ojo, bo ba jẹ nitori Amọtẹkun yii ni wọn o ṣe ni i dibo foun, ki wọn ma dibo foun o, o loun ko ni i tori ọrọ ibo pa Amọtẹkun ti oun pẹlu awọn gomina to ku n ṣe ti. Awọn kan ti gbe ọrọ yii jade lasiko yii, ohun ti wọn si fẹẹ fi ṣe ni lati fi han awọn eeyan pe Akererdolu ko ka awọn oludibo ipinlẹ Ondo si, o n sọrọ si wọn kaṣakaṣa, bẹẹ ọrọ naa ki i ṣe ti awọn ara Ondo rara. Ṣugbọn ọrọ naa ko pada ja si ibajẹ fun Arakunrin yii, oriyin lawọn mi-in n gbe fun un. Wọn n gbe oriyin fun un fun iru ọrọ bẹẹ, nitori bo ṣe yẹ ki nnkan ri lo sọ ọ yii. Bo ṣe yẹ ki oloṣelu to fẹẹ du ipo ronu lo ṣe yii, iyẹn pe ti awọn eeyan ba waa ri i pe oun kun oju oṣuwọn, ki wọn dibo foun, bi wọn ko ba si dibo foun, oun yoo pada sidii iṣẹ ti oun n ṣe tẹlẹ. Nibi ti nnkan ba ti dara, ki i ṣe oloṣelu to fẹẹ dupo ni yoo maa ko owo oṣelu kalẹ lati na, awọn araalu ti wọn ba fa a kalẹ gbọdọ da si i, eyi ni yoo fi i han pe awọn araalu yii lo funra wọn fa tọhun kalẹ. Oloṣelu to ba ni ohun to n ṣe tẹlẹ, to ni iṣẹ gidi lọwọ, ko gbọdọ bẹru pe wọn dibo foun tabi wọn ko dibo foun, nigba ti ko ba ti jẹ gbese, to si ni iṣẹ to n ṣe tẹlẹ ki ọrọ idibo too waye. Ohun ti gbogbo oloṣelu gbọdọ fi kọra ree, ati Akeredolu funra rẹ. Ọrọ ti Akeredolu sọ lasiko ọrọ Amọtẹkun yii naa ni ko lo lasiko yii, ki oun ati awọn ẹlẹgbẹ ẹ to ku ma fi ọrọ ibo gomina to n bọ yii ṣe bo-o-ba-a-o-pa-a, bo-o-ba-o-bu-u-lẹsẹ, iru ibo ti wọn di ni Edo la fẹ ni Ondo, nibi ti ohun gbogbo yoo ti lọ wọọrọ, ti ẹni ti awọn araalu dibo fun yoo si wọle, ti inu wọn yoo si dun pe awọn lawọn dibo fun. Bo ṣe Akeredolu funra ẹ, bo jẹ ẹlomi-in, ẹni ti yoo ṣe ipinlẹ Ondo daadaa, ti yoo si mu idẹrun ba gbogbo eeyan la fẹ o.

 

Ẹ so fun Gbenga Daniel ko ma fowo ẹ jona o

Afi keeyan beere ohun ti gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ n wa bayii o. Bi ẹ ri i bayii nile Olugbọn, ẹ oo ri i nile Arẹsa, gbogbo ọdọ awọn agbaagba ilẹ Yoruba lo si n rin si kaakiri. Nigba ti oloṣelu ba ti bẹrẹ si i rin iru awọn irin wọnyi, o n ba kinni kan bọ ni. Ko pẹ ti Buruji Kasamu ku ti Daniel kede pe gbogbo irinṣẹ ati agbekalẹ eto oṣelu olowo-nla naa lo ti ko foun Daniel, ohun ti yoo si fi iru irinṣẹ ati agbekalẹ bẹẹ ṣe ko yeeyan. Akọkọ ni pe PDP ni Kaṣamu, Daniel si ti kuro ninu ẹgbẹ naa nigba kan, to ni ibi ti awọn ọmọlẹyin oun ba n lọ loun n lọ, bẹẹ awọn ọmọlẹyin ẹ to n wi yii ti gba inu APC lọ nigba naa. Ko sẹni to si gburoo oun naa sinu PDP taara mọ, nitori gbogbo ohun ti wọn n ṣe, ko si eyi to ba wọn da si. Wọn ko ri i ninu APC naa taara, bo tilẹ jẹ awọn pupọ ni wọn gba pe ohun to n ṣe niyẹn. Ṣugbọn ju gbogbo ẹ lọ, Daniel n mura kinni kan bayii, nigba ti ko si ti le ṣe gomina kankan mọ, afaimọ ko ma jẹ ipo to ga ju bẹẹ lọ lo n wa. Bi ọrọ awọn oloṣelu ti ri nu-un, nigba ti wọn ba fẹẹ gbawin ẹba ni wọn n ṣoju aanu, bi wọn ba yo tan, wọn yoo di ọkọ ẹni to ta ounjẹ lawin fun wọn. Ohun yoowu ti Daniel ba fẹẹ ṣe, bo ba jẹ nigba to n ṣe gomina ati awọn ipo mi-in to ti di mu, to ba ṣe e daadaa, awọn araalu yoo jade si i, wọn yoo si ni ẹni ti awọn fẹ niyi. Ṣugbọn to ba ṣe igberaga ati itapakaka lo n ba kiri nigba to wa nipo, ti ẹnikẹni ko si jọ ọ loju, to jẹ eyi to ba ti wa ninu ẹ ni yoo ṣe, asiko ti yoo gbẹsan ẹ naa lo n bọ yii, nitori ohun ti kaluku ba ṣe ni yoo gbẹsan. Eyi ni ki Daniel ro ko too bẹrẹ inawo, eyi ni ko ro ko too maa kiri ile Ọbasanjọ, lọ sile Faṣoranti tabi ile Adebanjọ, bi bẹẹ kọ, bii ẹni to fowo jona lasan ni. Ẹyin tẹ ẹ ba si mọ ọn, ẹ gba a nimọran, ko ma fowo ẹ jona o.

 

 

Oluwoo atawọn afọbajẹ ẹ, ẹni kan ni yoo rẹyin ẹni kan

Awọn afọbajẹ ilu Iwo ti jade, wọn lawọn o fẹ Oluwoo mọ. Ọsẹ to kọja ni wọn kede bẹẹ, ti wọn ni awọn ko fẹ Ọba Akanbi Adewale nipo ọba awọn mọ. Oriṣiiriṣii ẹsun ni wọn ka kalẹ si i lọrun, ọpọ awọn ẹsun yii ni awọn araalu si mọ tẹlẹ, wọn mọ pe ko si ọba Yoruba ti i ṣe ọpọ ohun ti ọba yii ṣe. Awọn ọdọ mi-in wa ti wọn ko mọ aṣa, ti wọn ko si mọ ohun to jẹ ti Yoruba, to jẹ aye oyinbo ati ọlaju-odi ti wọn ni ti da wọn ni laakaye ru, ti wọn n sọ pe Akanbi Adewale ki i ṣe ọba lasan, ọba to ni Swaga, ọba to ja si i, ọba to laroma, ati ọpọ oriṣii inagijẹ raurau bẹẹ ni ọba yii, ọba ti awọn ọdọ fẹran ni. Aṣa Yoruba ko gba eleyii, ipo ọba ki i ṣe eyi ti ẹnikan n fi wọlẹ, tabi to n sọ di yẹyẹ laarin awọn ọmọ Oodua gbogbo. Idi eyi ni pe ni ilu kọọkan, awọn ọba yii ni wọn di aṣa ati iṣe Yoruba mu, gbogbo ohun abalaye ati awọn nnkan baba-nla wa nilẹ Yoruba, ọwọ awọn ọba lo yẹ ka ti ba a. Awọn iwa ọmọluabi, awọn ohun to yẹ ki Yoruba ṣe ati eyi ti wọn ko gbọdọ ṣe, gbogbo awọn nnkan wọnyi lo wa lọwọ awọn ọba wa. Ọba to ba waa pa eleyii ti, ti wọn n pe e ni ọba to ni Swaga, iru ọba bẹẹ ko yẹ lori oye loootọ. Ṣugbọn ọrọ ko dun lẹnu iya ole! Awọn afọbajẹ ti wọn fẹẹ yọ Oluwoo yii, ṣe wọn ko ṣe iwadii daadaa ki wọn too fi i sori oye ni, tabi owo ni wọn gba lọwọ ẹ bi awọn kan ti wi. Ṣe wọn ko beere ọrọ naa lọwọ Ifa ni. Kin ni Ifa sọ fun wọn nigba naa. Ṣebi ojuṣe awọn afọbajẹ wọnyi ni lati wadii ẹni ti wọn fẹẹ fi sori oye daadaa ki wọn too gbe e debẹ, wọn yoo lo ọna Ifa ati awọn ọna mi-in lati ṣewadii onitọhun, ki wọn le mọ bi ẹni ti yoo yẹ loye ni tabi ẹni ti ko yẹ. Ọlọrun nikan lo mọ ohun ti Adewale gbe fun wọn, wọn gba tọwọ ẹ tan, wọn fi i jọba, wọn waa ni iwa rẹ ko daa. Bi wọn ba le Oluwoo, o yẹ ki wọn le awọn eeyan yii naa danu lori oye ni, nitori iwa awọn paapaa ko daa. Ju gbogbo ẹ lọ, bi ija yii ba ṣee pari, ki wọn yanju ẹ, awọn afọbajẹ yoo ti kọ ọgbọn lati idi eyi, wọn yoo le ṣe ojuṣe wọn daadaa ki wọn too fiiyan sipo ọba; Adewale Akanbi naa yoo ti kọgbọn, yoo mọ pe wọn le yọ oun, yoo si bẹrẹ si i huwa bii Oluwoo tootọ!

Leave a Reply