O ṣoju mi koro (Apa Keji)

Kin ni Tọpẹ Alabi n fẹdi ara rẹ sita bayii fun

Olorin ẹmi gidi ni Arabinrin Tọpẹ Alabi, ọpọlọpọ awọn Krisitẹni ati awọn ti ki i tilẹ ẹ ṣe Krisitiẹni rara, ni wọn fẹran orin rẹ, wọn aa si maa kan saara si i bo ba n kọrin ẹmi fun wọn. Awọn mi-in a maa sọ paapaa pe orin rẹ a maa yi awọn ni ọkan pada, a si maa tubọ mu awọn sun mọ Ọlọrun. Bi Tọpẹ ti kọrin fun ọba lo n kọrin fun ijoye, Ọlọrun si ti bu kun un lẹnu iṣẹ naa gidigidi. Ṣugbọn ko si bi ẹda kan yoo ti wa laye yii ti ko ni i ni awọn ohun to ti ṣe sẹyin ko too de ile ati ipo ọla, awọn ohun ti a maa n ṣe sẹyin nigba mi-in ki i dara rara. Idi ni pe nnkan abamọ ni wọn maa n jẹ! Boya ni ẹda aye kan wa ti ko ti fi igba kan ṣe nnkan abamọ ri, nitori nibi awọn nnkan abamọ bayii ni a ti maa n ri ọgbọn pupọ kọ, awọn ọgbọn ti a oo pada fi ṣe aye wa nigba ti o ba dara fun wa. Ki Tọpẹ Alabi too di olokiki, o ti lọkọ kan ri, o si ti bimọ fun un, wọn si jọ wa fungba diẹ ko too di pe ina ko wọ mọ, ti kaluku si ba tirẹ lọ. Ki lo buru ninu iyẹn! Gbogbo aye lo n ṣe bẹẹ! Bi a si ko eeyan mẹwaa kalẹ lawujọ wa loni-in, mẹfa si meje ninu wọn ni iru eyi ṣẹlẹ si laye daadaa. Ṣugbọn eyi ti ko dara ni ki a maa fi ọrọ ẹnu bo eleyii mọlẹ, ki a maa fẹẹ fi irọ bo ootọ, tabi ki a ro pe a ti de ipo kan pataki ti a fi le yan awọn eeyan mi-in jẹ. Baba meji ki i bimọ, baba kan naa ni yoo bi i, koda ko jẹ oun kọ lo tọ ọ. Ilakaka Tọpẹ lati fi irọ bo ootọ fun ọmọ to bi ninu, debii pe ọmọ to bi ninu jade lati maa sọ pe ki i ṣe baba oun lo bi oun, ohun to buru gbaa ni, paapaa fun ẹni to ba n pe ara rẹ ni ojiṣẹ Ọlọrun. Tọpẹ bi akọbi ọmọ rẹ fun Ọlaoye Oyegoke, akọbi ni ọmọ yii si jẹ fun Oyegoke funra rẹ, ko sẹni ti i fẹ komi ajipọn oun danu, ko si sẹni ti i fẹ ki igi akọṣẹ oun ma sun iṣu fun oun jẹ. Bi ija ba de ti Tọpẹ gbe ọmọ lọ, Tọpẹ ko kuku jiyan pe ki i ṣe Oyegoke lo lọmọ, bẹẹ ni Alabi to ṣẹṣẹ fẹ ko sọ pe oun ko mọ pe ọmọ yii ki i ṣe ọmọ toun, ki waa ni wahala, ki waa ni Tọpẹ faaye gba ọmọ rẹ lati maa lọọ bu baba rẹ si, to waa n tu idi ara rẹ sita lori nnkan aṣiri aye rẹ. Iyẹn ko sọ pe ki i ṣe Oyegoke lo bi i, koda, ko jẹ ẹlomi-in lo tọ ọ. Lati faaye gba ọmọ lati maa lọọ sọrọ si baba to fi nnkan ọmọkunrin rẹ bi i ni gbangba ki i ṣe iwa abiyamọ, nitori iru awọn ọrọ bẹẹ a maa ni egun lori lẹyin ọla. Aya ọlẹ la n gba, ko sẹni to le gba ọmọ ọlẹ, boya Oyegoke lowo, boya ko ni, oun lo lọmọ rẹ, nitori ki i ṣe pe o fi ipa ba Tọpẹ sun nigba ti yoo fi loyun, wọn jọ sọro adehun, wọn jọ ṣe lọkọ-laya, wọn si jọ gbe pẹlu ara wọn. Tọpẹ ti wọ ile ọkọ mi-in, o si ti bimọ mi-in, Oyegoke ti fẹyawo mi-in, oun naa si ti bimọ, ki waa ni lati maa fi ori ọmọ kekere ti ko dakan mọ fọ agbọn! Kin ni yẹ ko fa ariwo ninu pe baba rẹ niyi, maa lọọ ri i nigba ti o ba fẹ. Bi ọmọ ba gbọn, yoo mọ baba rẹ, funra rẹ ni yoo si mọ iru iwa ti oun yoo hu si baba oun. Tabi angẹli ni Tọpe nigba to wa lọdọ ọkunrin yii ni! Oun ko ni iwa kankan to hu ti ko dara rara! Bi ija ba wa laarin awọn agbalagba meji, ko yẹ ki wọn fi tọmọ wọn saarin, bii ẹni to n ko awọn ọmọ bẹẹ sita ni. O dara bi Tọpẹ ko ṣe sọrọ yii o, ko yaa dakẹ ẹnu rẹ jẹẹ. Ṣugbọn o gbọdọ wa ọna lati lọọ jokoo pẹlu awọn ẹbi ọmọ yii, ko si mu Alabi paapaa dani, ko si fi ọmọ han baba rẹ, ko si jẹ ki ọmọ naa tọrọ aforiji lọwọ baba to bi i. Eyi ni yoo tun ile rẹ ṣe, ti yoo si fi i han gẹgẹ bii ojiṣẹ Ọlọrun to n pe ara rẹ. Tabi ko mọ pe oun ti pe akọbi oun yii ni ọmọ ale nile Alabi ni! Bi ọrọ naa ko ba jade loni-in, to ba di lọjọ iwaju, yoo jade pe Ayọmikun yii ki i ṣe ọmọ Alabi, ki i ṣe ọmọ baba wa. Ki leeyan n gbe ohun ti ko ṣee gbe pamọ pamọ si! KI leeyan n fẹdi ara rẹ sita si lori ọrọ to yẹ ko wọlẹ ṣin-in. Olorin ẹmi ni Tọpẹ Alabi, ojiṣẹ Ọlọrun si ni. Ko tete yaa tun ọọkan ibi yii ṣe o, ko ma funra rẹ ba oore Ọlọrun to ti wa ninu aye rẹ jẹ, nitori ẹni to ba fẹdi ara ẹ sita, aye aa  ba a fẹ ẹ ju bẹẹ lọ. Ọlọrun ko ni i ba wa lorukọ jẹ, ṣugbọn ki awa naa tọju orukọ wa o!

 

Arẹgbẹ pẹlu Oyetọla, agba ki i wa lọja

Ni ọsẹ to kọja, idunnu lo jẹ fun ọpọ awọn ara Ọṣun, paapaa, awọn oloṣelu APC, lati ri i pe Rauf Aregbẹṣọla to ti ṣe gomina ibẹ ri, ati Gboyega Oyetọla to n ṣe gomina ibẹ lọwọlọwọ bayii kọja si ile Oloye Bisi Akande, nibi ti wọn ti ba Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu. Ko sẹni ti ko mọ pe ija ni wọn lọọ pari nibẹ, ija laarin Arẹgbẹ ati gomina naa ni. Arẹgbẹ ko fẹẹ gba pe oun kọ ni gomina mọ, tabi pe agbara oun ko pọ lori Oyetọla bii tigba ti ọkunrin naa jẹ ọmọọṣẹ oun. Wọn ti yọ ọwọ kilanko Arẹgbẹ ninu eto oṣelu Eko, nitori rẹ loun naa si ṣe n ja raburabu lati di baba isalẹ fun gbogbo oloṣelu Ọṣun. Ki i ṣe pe eleyii ko ṣee ṣe, ṣugbọn ọgbọn lo gba, ati suuru rẹpẹtẹ, kinni naa ko le mu girigiri dani rara. Ohun ti Arẹgbẹ le ṣe ti yoo sọ ọ di olori oloṣẹlu Ọṣun ko ju ko lo gbogbo agbara rẹ lati kin Oyetọla lẹyin lọ, ko lo gbogbo ọgbọn ati imọ rẹ lati fi ran ọkunrin naa lọwọ ninu ijọba rẹ. Bi Arẹgbẹ ba n bọ l’Ọṣun, ile Oyetọlọ lo n bọ, ibẹ naa ni yoo sun, nibi ti tọhun yoo ti ṣalaye awọn ohun to ba n lọ fun un. Bi ọkunrin gomina yii ba ri awọn ohun ti Arẹgbẹ n ṣe foun, to si ri i pe pẹlu ifẹ lo fi n ṣe e, funra rẹ ni yoo fi i han gbogbo aye pe aṣiwaju awọn ree, oun ni baba isalẹ fawọn. Amọ bi Arẹgbẹ ba n lọọ, to n ṣe giragira, to n ṣe  bii ẹni pe oun lọ si oko oun, nibi ti lebura oun wa to ti n ṣiṣẹ, ohun ti yoo maa ba pade naa lo ba pade lọsẹ to kọja lọhun-un yii, bẹẹ ni awọn ti yoo si ba a pari ija naa ni wọn jokoo yii, Tinubu ati Akande, awọn mejeeji ko si ni i si lẹyin rẹ ninu ohun to n ṣe. Agba ki i wa lọja ki ori ọmọ tuntun wọ, awọn agbaagba ti ọrọ yii kan ko ju awọn ti wọn jokoo yii naa lọ, o si daju pe wọn ti fi ori ọrọ naa ti sibi kan. Ki Oyetọla mọ pe oun nilo ọgbọn ati iriri Arẹgbẹ, ki Arẹgbẹ naa si mọ pe oun nilo atilẹyin Oyetọla lati di baba isalẹ fawọn oloṣelu Ọṣun. Saaba de saaba, bi aja ba n saaba ẹkun, ki ẹkun naa maa saaba aja, iwajọwa ni i jẹ ọrẹjọrẹ o.

 

Owo reluwee lati Eko lọ si Ibadan

Bi reluwee awọn ọmọ Buhari ba bẹrẹ iṣẹ, ẹgbẹrun mẹta si ẹgbẹrun mẹfa lawọn eeyan yoo maa fi wọ ọkọ yii lati Eko lọ si Ibadan. Eyi ni pe ko si ẹni ti yoo wọ reluwee de Ibadan lati Eko tabi ko wọ ọ lati Ibadan wa si Eko bi ko ba ni ẹgbẹrun mẹta lọwọ. Ni gbogbo aye, relulwee ni ọkọ awọn oṣiṣẹ, nitori pe o rọrun, a si maa ko ero pupọ lẹẹkan ni. Reluwee a maa din iṣoro awọn eeyan ku gan-an ni, nitori oun ki i ni gosiloo, tabi ko ni ijamba rẹpẹtẹ bii ti mọto. Lara ohun to mu awọn ilu nla aye yii ga ko ju ọna reluwee ati awọn ọkọ oju irin ti wọn n lo lọ. Awọn orilẹ-ede keekeeke ti wọn ko to Naijiria rara ni wọn ni ọna reluwee to dara, nitori ẹ ni tirela ati awọn ọkọ elepo ko ṣe n paayan, tabi da sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ti awọn eeyan yoo maa fi lo wakati marun-un si mejia loju kan silẹ. Nidii eyi, awọn eeyan ti wọn gbọ pe Naijiria n mura ọna reluwee, niṣe ni inu wọn n dun lẹgbẹẹ kan, pẹlu igbagbọ pe to ba de, irọrun ni yoo mu ba awọn eeyan wa. Ṣugbọn ni bayii, irọrun wo lo fẹẹ wa ninu keeyan fi ẹgbẹrun mẹta wọkọ lati Eko si Ibadan. Tabi awọn eeyan yii ko mọ ohun ti wọn n wi ni. bi eeyan ba fẹẹ sare lọ si Ibadan ko bọ paa, iyẹn ni pe afi to ba ni ẹgbẹrun mẹfa lọwọ! Nitori pe owo ilu lawọn eeyan yii n na, ati pe ọpọlọpọ owo araalu ni wọn ti ko jẹ, wọn ki i mọ pe ara n ni araalu, ati pe ọpọ eeyan wa niluu ti wọn ko fi oju ri ẹgbẹrun kan naira laarin ọsẹ kan. Nitori pe wọn ro pe bi awọn ti n rowo naa ni gbogbo eeyan n ri i, eyi ni ko ṣe jẹ ki wọn laaanu awọn eeyan ilu rara. Nigba ti ijọba ba gbe reluwee kalẹ, to n gba ẹgbẹrun mẹta lọwọ awọn eeyan lati Eko si Ibadan, bo ba waa jẹ araalu lo ni reluwee yii nkọ! Bẹẹ ni ki i ṣe pe idaniloju wa pe reluwee naa yoo ṣiṣẹ bo ti yẹ ko ṣe e o, tabi ki i ṣe awọn ọkọ alugbagba ti wọn n daku daji sọna yii naa ni wọn yoo lo ni. Ijokoo yin ku ẹẹkan o! To ba jẹ Buhari lo paṣẹ bẹẹ, bo si ṣe minisita ni, ko si ẹni ti yoo san ẹgbẹrun mẹta lati Eko de Ibadan ninu reluwee, ẹ yaa tun kinni naa ṣe kiakia.

 

A ki wọn nile Awolọwọ, a ki wọn nile awọn Ṣeyi Makinde

O pẹ ti ilu Ibadan ti gba iru alejo to gba lọsẹ to kọja yii. O pẹ gan-an. Idi ni pe ohun kan naa lo ṣẹlẹ, ṣugbọn ọna meji lo ti ṣẹlẹ. Awọn obinrin meji ni wọn sin oku wọn: obinrin akọkọ jẹ akọbi obinrin Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ, Arabinrin Tọla Oyediran. Ẹni keji jẹ iya Gomina Ṣeyi Makinde, Arabirin …. Makinde. Ni awọn gomina kaakiri Naijiria ba ya wọ ilu Ibadan, awọn oloye ati awọn ọlọla gbogbo si jokoo si ilu naa fun ọjọ meji mẹta, ti wọn ko lọ. Ohun to mu ọpọ eeyan lọkan ju lọ ni awọn ọrọ ti wọn sọ nibi isinku awọn mejeeji yii. Awọn eeyan royin Tọla Oyediran, pe ki i ṣe nitori pe obinrin naa jẹ ọmọ Awolọwọ lo ṣe niyi, to si jẹ ẹni ti gbogbo eeyan fẹ, ṣugbọn nitori iwa rẹ to n hu ni. Wọn royin bo ti loju aanu to, ati bo ti ko ni mọra, ti ko si ni i fi igberaga ba ẹnikẹni lo. ‘Mọmi Ibadan’ ni ọpọ eeyan n pe e, paapaa awọn ti wọn mọ ọn dele, pupọ ninu awọn oṣiṣẹ Tribune, nibi ti iya naa ti jẹ alaga wọn ni wọn n sọ pe ki i ṣe ọga awọn, iya awọn tootọ ni, nitori bi awọn ba ti ri i, gbogbo iṣoro awọn ti tan niyẹn. Imura ọjọọbi ọgọrin ọdun rẹ ni wọn n mu, ko too waa di pe o ku ki ọjọ naa too pe. Ohun to si dun awọn mi-in niyi, nitori wọn ni awọn ti ya ọjọ naa sọtọ lati fi royin iṣẹ rere to n ṣe. Bakan naa lawọn ti wọn si sun mọ iya Gomina Makinde sọrọ tirẹ naa pe abiyamọ tootọ ni. Wọn royin aduroti to ṣe fawọn ọmọ rẹ ati bo ti jẹ si wọn, boya ni ko si jẹ eyi gan-an lo pa Gomina naa lẹkun nibi isinku yii, nitori bii igba ti oun naa sọ wura ẹ nu ni. Ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, awayeeku kan ko si mọ, bo ti wu ka pẹ laye to, a oo pẹ lọrun ju bẹẹ lọ. Tọla Oyediran ti lọ, bẹẹ ni iya Ṣeyi Makinde. Ṣugbọn awọn iṣẹ rere ti wọn ṣe silẹ ko tan, iṣẹ naa lawọn eeyan si n royin yii, oun naa ni wọn yoo si maa fi ranti wọn. A ki gbogbo ẹbi Awolọwọ ku irọju, wọn ku ara fẹra ku, Ọlọrun yoo si tẹ mama si afẹfẹ rere. Bakan naa ni a ki awọn ọmọ Iya Makinde pe wọn ku asẹyinde iya, ọjọ yoo jinna sira wọn. Ko si ẹkun tabi ibanujẹ nigba ti eeyan rere ba ku, ohun kan naa to yẹ ki kaluku maa ronu le lori ni bi igbẹyin tawọn naa yoo ṣe dara. Idi ni pe oku lo n sunkun oku, akaṣọleri lo n sunkun ara wọn: ko sẹni ti ko ni i ku, ki kaluku gbe ile aye ṣe rere nigba ti a ba wa nibẹ ni.

Leave a Reply