O ṣoju mi koro (Apa keji)

Nibo la oo gbe eleyii gba o

Aarẹ Ona Kakanfo ilẹ Yoruba, Aarẹ Gani Adams, sọrọ kan ninu atẹjade ọsẹ to kọja yii pe awon ọmọ ogun afẹmiṣofo, ISIS, ti wọn wa lati Iraq ati Syria to le ni ẹẹdẹgbẹta tiwa ni agbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyo, bayii o. O ni maṣinni ara ọtọ ni wọn n gun tibọn-tibọn nla lọwọ wọn. Lẹyin ipade pajawiri to pe lori ọrọ aabo ilẹ Yoruba lo ti sọ bẹẹ ninu atẹjade wọn. O ni bi awọn eeyan wa ko ba tete mura, nnkan le ṣẹlẹ, ki awọn eeyan ibi naa ti yi wa ka ka too mọ nnkan kan. Ohun to mu ọrọ yii tubọ ba ni lẹru ni pe olori awọn Amọtẹkun ipinlẹ Ọyọ, Ọgagun Kunle Toogun, sọ bẹẹ pe ariwo ti oun ti n pa lati ọjọ pipẹ wa niyi, pe awọn afẹmiṣọfo Fulani lati ilẹ okeere wọnyi ti de Naijiria, wọn si wa l’Oke-Ogun ti wọn n kiri tẹnikan ko mu wọn. Bẹẹ ni tootọ, ki i ṣe akọkọ niyi ti ọrọ bayii yoo jade. Ọpọlọpọ aburu ati iwa ipaniyan to n lọ lagbegbe naa, awọn afẹmiṣofo yii lọwọ ninu rẹ daadaa. Ohun to wa n yaayan lẹnu ni ti ijọba apapọ ti ko da si i, ti wọn ko si ṣe bii ẹni pe wọn gbọ. Bi ọrọ si ti n ri ree to jẹ awọn araadugbo naa yoo ṣeto aabo wọn funra wọn. Ṣugbọn ti wọn ba fẹẹ ṣe bẹẹ, ijọba yoo sare dide, wọn yoo ni gbogbo agbara ati aabo ilu, ọwọ awọn lo wa, awọn lawọn yoo mojuto o. Iṣẹ akọkọ to wa fun ijọba yoowu lati ṣe ni orilẹ-ede yoowu naa ni eto aabo ẹmi ati ohun-ini awọn eeyan. Ijọba-kijọba ti ko ba ti ri eyi ṣe, iru ijọba bẹẹ ko yẹ nibi kan. Tabi kin ni wọn n ṣejọba le lori. Nitori ẹ ni ijọba Buhari yii ṣe gbọdọ tun ero ara wọn pa. Ki wọn jokoo, ki wọn si ronu eto aabo ti wọn yoo ṣe fun gbogbo ilu yikayika. Ki wọn ma fi ọrọ naa ṣe ẹlẹyamẹya tabi ti oṣelu, eto aabo ilu ki i i ṣe ohun ti wọn n fi ẹlẹyamẹya tabi ti oṣelu ṣe, nitori gbogbo eeyan lo kan patapata. Ṣugbọn ọṣelu ati ẹtan fọ awọn ijọba tiwa yii lori, Ọlọrun nikan ni yoo pada ko wa yọ lọwọ wọn.  

 

Ki lo kan wọn ninu ọrọ wa

Oṣa bo o ba le gbe mi, ṣebi o o si ṣe mi bo o ṣe ba mi. Awọn ijọba ilẹ Yoruba beere eto aabo titi lọwọ ijọba apapọ, ṣugbọn o jọ pe ọwọ ijọba apapọ kun, wọn ko raaye tiwọn. Awọn eeyan yii si dide, wọn da Amọtẹkun silẹ lati pese eto aabo fawọn eeyan tiwọn. Ṣugbọn niṣe ni ijọba apapọ yii kan naa bẹrẹ si i fidi fọgba, ti wọn n pooyi, ti wọn n lọ ti wọn n bọ, ti wọn n fẹẹ gba Amọtẹkun yii lọwọ awọn ti wọn da a silẹ. Kin ni tiwọn, ki lo si kan wọn ninu ọrọ wa. Ohun to han ni pe eto aabo tabi ti ilọsiwaju agbegbe yii ko da bii pe o jẹ ijọba yii logun, nitori bo ba jẹ wọn logun, wọn yoo ṣe ju bi wọn ti n ṣe yii lọ. Akọọkọ ni pe wọn yoo ri i pe ko si ogun ajinigbe, ogun ipaniyan ati janduku loriṣiiriṣii ni awọn agbegbe yii, wọn yoo ko awọn ọlọpaa to kaju ẹ sibẹ, ibi ti apa ọlọpaa ko ba si ka, wọn yoo ko awọn ologuon sibẹ, nibi ti wọn yoo ti le awọn eeyan naa lọ kuro lọdọ wa. Ṣugbọn ijọba Buhari ko ṣe bẹẹ fun ilẹ  Yoruba, ẹnu lasan ni wọn yoo maa dan, ti wọn yoo si maa fi aaye gba awọn ọta lati doju ija kọ wa, ki wọn si ṣẹgun wa. Ka tilẹ waa sọ pe  ọwọ wọn kun, eto pọ lọwọ wọn, wọn ko si raaye ṣeto aabo to peye fun wa nilẹ Yoruba, ṣebi ohun to yẹ ki wọn ṣe ni lati ṣe atilẹyin fun iru ikọ Amọtẹkun yii, to fi jẹ wọn yoo lagbara lati koju ọdaran gbogbo. Tabi ki lo wa ninu ki ijọba apapọ Naijiria ṣe atilẹyin fun awọn ijọba ipinlẹ nil;e Yorua blat igbogun ti awo nọdaran to n pa wa. Ṣugbọn ijọba yii ko ṣe bẹẹ, kaka bẹẹ, wọn tun fẹẹ da kinni naa ru ni. Nitori kin ni! Ṣe nitori ẹlẹyamẹya tabi ti oṣelu yii naa! Abi nitori ki awọn Fulani le di ọba le wa lori nilẹ wa yii naa ni! Dajudaju, eleyii ko ni i ṣee ṣe, bo ba kọ logi, a o fọ ọ ni kọọrọ, kaka ki kinnihun si ṣe akapo ẹkun, kaluku yoo maa ṣe ọdẹ rẹ lọtọọtọ ni.

 

Ṣe ẹ ri ọrọ ti Oluwo, keeyan fi ṣenu ko dakẹ ni

Oluwo ilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi, ki i yee jade ninu iroyin, ohun ti ko kan daa to naa ni pe nigba yoowu to ba ti jade bayii, ọrọ to ba sọ yoo di ariyanjiyan ati awuyewuye ṣaa ni. Boya oun funra rẹ fẹ iru nnkan bẹẹ ni o, tabi o kan mọ-ọn-mọ ko maa fi ọrọ ẹnu rẹ wa wahala ṣaa ni, oun nikan lo ye. Ipari ọsẹ to kọja yii naa lo sọrọ kan, to ni Aṣiwaju Bọla Tinubu ni Awolọwọ asiko yii, ki gbogbo ọmọ Yoruba gba bẹẹ. Akọkọ ni pe awọn ọrọ kan wa ti ko yẹ ko maa ti ẹnu ọba jade, nitori ọba jẹ olori fun gbogbo ilu. Oloṣelu ni Bọla Tinubu, oṣelu rẹ ko si ba ọpọ eeyan lara mu nilẹ Yoruba nibi, ti ọba kan yoo ba si sọrọ rẹ, afi ko mọ bi yoo ti sọ ọ. Tinbu ko fijọ kan sọ fun wa ri pe oun fẹẹ huwa bii Awolọwọ, tabi oun n huwa bii Awolọwọ, tabi oun fẹẹ ṣe aṣaaju fun Yoruba nibi kan. Ohun ti Tinubu n wa ọtọ, bi yoo ti fi orukọ Yoruba adi aarẹ ilẹ yii ni. Ko si ohun to buru ninu iyẹn o, ohun ti eeyan ba fẹ laye rẹ naa ni yoo maa le, ko si si aidaa kan ninu ki eeyan fi ọjọ aye rẹ le ipo giga. Ṣugbọn awọn ti wọn ba wa n jẹ ijẹkujẹ nidii iru eto bayii ko ni i maa pe awọn araalu to ba ku ni ọbọ tabi apọda. Idi ni pe lasiko ti a wa yii, gbogbo eeyan lo n beere pe oore wo gan-an ni Tinubu ti ṣe fun ilẹ Yoruba yii ri. Ogun awọn Fulani lo yi wa ka yii, ọrọ Amọtẹkun lo n da wahala silẹ yii, ninu gbogbo ipinlẹ Yoruba, Eko lo n fa ṣẹyin ju lọ ninu ọrọ yii, wọn ko fẹẹ ba awọn to ku da si i. Ki i ṣe nitori ohun meji, nitori Tinubu ni. Ti iṣoro ba doju kọ Yoruba, ti Tinubu ko da si i; ti idaamu ba ba Yoruba, ti ko ṣe bii ẹni pe oun ri wa, ki lo waa de ti a oo sọ pe Tinubu ni Awolọwọ tuntun. Ohun ti Oluwo ko mọ (Boya o mọ o si n ṣe abosi ni) ni pe Awolọwọ kọ lo fi ara re ṣe aṣaaju, awọn eeyan ni wọn gba pe aṣaaju awọn niyi. Bẹẹ ni ki i ṣe pe wọn kọ kinni naa siwee, ninu ọkan awọn eeyan lo n gbe pe Awolọwọ ni aṣaaju awọn. Iṣẹ ọwọ rẹ lo fa a o, iwa to si hu si Yoruba lo fa a. Bi Oluwoo yoo ba fi Tinubu ṣe aṣaaju Yoruba, ko kọkọ sọ fun un pe ko tun iwa rẹ ṣe. Ko ju bẹẹ lọ!

 

Ẹyin ara Ondo, ṣe eyin naa ti gbọ

Ọga ọlọpaa patapata, Mohammed Adamu, lo sọrọ kan ni ọjọ Aiku, Sannde ijẹta, ọrọ naa si ba ni lẹru gidigidi. Ọga yii ni iwadii ti awọn ṣe lori ọrọ ibo ti wọn yoo di ni ipinlẹ Ondo ati Edo ninu oṣu to n bọ yii ti fi han pe awọn oloṣelu ti n ra awọn ohun ija oloro pamọ, o ni wọn ti n ko ibọn fun awọn tọọgi, bẹẹ ni wọn n pin wọn kaakiri adugbo gbogbo ti ibo naa yoo ti waye. Adamu ni ọrọ naa ki i ṣe ere, bẹẹ ni ki i ṣe ahesọ, nitori ẹka to n ṣewadii rogbodiyan to le ṣẹlẹ lasiko ibo lọdọ wọn lo gbe kinni naa jade. Eleyii yẹ ko bayaan lẹru, paapaa awọn ara Ondo, lọdọ tiwa nibi, nibi to jẹ ọmọọya kan naa ni gbogbo wa. Kin ni oloṣelu n ko ibọn kiri si, kin ni wọn n fun tọọgi lowo ati awọn ohun ija si, kin ni wọn fẹẹ gba nidii jagidijagan ti wọn fẹẹ da silẹ lasiko ibo naa. Awọn ibeere to yẹ ki awọn araalu maa beere lọwọ ara wọn ree, ki wọn maa wadii idi ti awọn oloṣelu ṣe fẹẹ da wahala bayii bolẹ lọdọ wọn. Bi wọn ba wadii daadaa, ohun kan naa ni yoo ja si wọn ninu, eyi si ni pe awọn oloṣelu to n ṣe bayii ko ṣe e nitori ohun meji, nitori ara wọn ni. Wọn fẹẹ fi tipatipa gba ijọba mọ ara wọn lọwọ, ẹni ti ko wọle ibo fẹẹ lo agidi ki wọn le sọ pe oun lo wọle, wọn ko kọ bi wọn paayan, wọn ko kọ ki wọn dana sun dukia tabi ki wọn ba aye awọn eeyan jẹ nitori ki wọn le wọle ibo yii ṣaa. Nidii eyi ni ki araalu ṣe mọ pe awọn eeyan yii ko tori wọn wa sode oṣelu, wọn ko wa lati tun aye araalu ṣe, wọn wa nitori ara wọn lasan ni. Ohun ti awọn yoo jẹ, bi owo ti wọn ni yoo ṣe maa pọ si i, ti wọn yoo wa titi aye ti arọmọdọmọ wọn yoo maa yii ninu owo lawọn n wa, ki i ṣe nitori araalu kankan. Ẹyin naa, ẹ ro o! Bi eeyan ba fẹẹ ṣe oṣelu, to jẹ nitori lati tun aye awọn eeyan ṣe ni, kin ni yoo maa haaya tọọgi si, kin ni yoo ni oun fẹẹ ko’bọn fawọn ọmọọta si! Dajudaju, nnkan mi-in wa nibẹ ni. Ṣugbọn awọn obi ni ki wọn ṣọra, ki wọn kilọ fun awọn ọmọ wọn, ẹni ti wọn ba fi ori rẹ fọ agbọn ko ni i jẹ nibẹ, ẹni to ba ti ku ti ku, koda, to ba jẹ nitori oṣelu yii lo ti ku sibi to ti n ṣe ọmọọta, epe ni aye yoo maa ṣẹ fun un lọna ọrun. Bẹẹ ni ki ẹnikẹni ma ba oloṣelu kan ko tọọgi kiri, ọpọ awọn oloṣelu to wa nita yii, ole ni wọn wa ja, ẹ yaa ṣọra fun wọn.

 

Ni ti Fẹmi Fani Kayode, abuni-bi-ẹni-layin

Nigba  ti eeyan ba ri Oloye Fẹmi Fani-Kayọde lori fidio to kari aye, nibi to ti ki oniroyin kan mọlẹ, to n halẹ mọ ọn, to si n bu u pe arindin ati apọda ni, tọhun yoo mọ iru awọn eeyan ti wọn n kiri, ti wọn n pe ara wọn ni aṣaaju ilu, ti wọn si n pariwo pe oloṣelu lawọn. Fani-Kayọde, ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni, o si ti ṣe minisita ri lẹẹmeji, ọkan ninu awọn alagbara inu ẹgbẹ naa ni ki agbara to pada bọ lọwọ wọn. Ko ṣe kinni kan lati ọjọ yii yatọ si ẹjọ to ni niwaju awọn EFCC, ti ọrọ naa si di ariwo fun igba pipẹ. Lojiji lọkunrin naa gbera, lo ba bẹrẹ si i kiri awọn ipinlẹ gbogbo ti PDP ti n ṣe akoso wọn. O de Zamfara, o de awọn ipinle mi-in nilẹ Hausa ko too pada wa si ilẹ Ibo. Nibi ti o ti n ṣepade pẹlu awọn oniroyin ni akọroyin kan, Eyo Charles lati ileeṣẹ iwe iroyin Daily Trust, ti beere pe gbogbo irinajo ti Fani-Kayọde n rin kiri yii, ta lo n sanwo ẹ, nitori awọn ipinlẹ to n kiri yii pọ pupọ debii pe yoo la inawo pupọ lọ. Oniroyin naa ko kuku beere ju bayi lọ, afi bi Fani-Kayọde ṣe gbe omi pari. Eebu tan nile eleeebu, o ni ki lo n ṣe ọkunrin naa, ki lo ja mọ, ṣe ko mọ oun ni, ko mọ iru ẹni ti oun jẹ ni, ki lo de to n beere ibeere ọlẹ bẹẹ lọwọ oun, o ro pe oun ya ole bii awọn oniroyin ti wọn n gba owo lọwọ awọn eeyan kiri ni! Eebu naa pọ ju. Loootọ, Fani-Kayọde ti tuuba, o si ti tọrọ aforiji lọwọ oniroyin to bu yi ati awọn ti ọrọ kan, ṣugbọn ibeere kan ko ni i yee wa sọkan eeyan, iyẹn naa ni pe ki lo bi i ninu to bẹẹ. Ibeere ti wọn bi i yii ko buru, ṣe bi ẹnu ko sọ pe ko sẹni kan to n nawo irin-ajo yii, oun funra oun loun nawo ẹ ni. Ṣugbọn awọn ti wọn ti pẹ nidii oṣelu mọ pe oun kọ lo n nawo ẹ, ẹni kan wa nibi kan to n lu ilu fun un jo, o si ni ohun to fẹẹ fi irinajo to n rin naa ṣe, oṣelu si ni. Nibo lo waa ti ri owo, tabi o kan ji lọjọ kan, o ko awọn owo to wa lọwọ ẹ,  o ni oun fẹẹ fi yipo ipinlẹ gbogbo ni. Nitori kin ni, ati fun kin ni! Ta ni irinajo Fani-Kayọde ṣe anfaani fun. Ohun to n wa, iyẹn ohun to fẹẹ fi irin-ajo yii ṣe lo jẹ ko tọrọ aforiji, bi bẹẹ kọ, yoo ni ki oniroyin naa ṣe ohun to ba fẹẹ ṣe ni. Ọjọ n bọ o, ko tiẹ le pẹ ko le jinna, ti a oo fi mọ ohun ti Fẹmi n tori rẹ rin kiri, a oo si ri gbogbo awọn ti wọn wa nidii ẹ. Ṣe ẹ ri awọn oloṣelu wa nilẹ yii, awọn gangan ni baba yahuu-yahuu!

Leave a Reply