O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

O daa bẹ ẹ ṣe tu awọn ọlọpaa apaayan ti wọn n pera wọn ni SARS yii ka

Ohun meji pere naa ni wọn maa n tori ẹ gbe nnkan pataki dide, tabi da ẹka ileeṣẹ kan silẹ, boya ileeṣẹ aladaani tabi ti ijọba. Ọhun akọkọ ni ere ti yoo mu wa fawọn ti wọn da a silẹ, ekeji si ni bi kinni naa yoo ti wulo fun awọn araalu tabi awujọ to. Ohun mejeeji yii ni ẹka awọn ọlọpaa ti wọn n pe ni SARS ti kuna nibẹ: wọn ko mu rere kankan wa fawọn ti wọn da a silẹ mọ, kaka bẹẹ, ibanilorukọjẹ ni wọn n ko ba wọn, bẹẹ ni wọn ko wulo faraalu kankan, kaka bẹẹ, ibanujẹ, adanu ati ofo ni wọn n mu wa. Nidii eyi, ko si idi kankan ti awọn SARS ṣe tun gbọdọ wa lawujọ wa, o daa bi wọn ṣe ko wọn kuro nilẹ, ki wọn ṣe atunṣe gidi si wọn, ki wọn si fi wọn ṣe nnkan mi-in laarin awọn ọlọpaa, ṣugbọn ki wọn ma jẹ ki wọn ni ohunkohun lati ṣe pẹlu awọn araalu mọ. Nigba ti wọn da SARS silẹ ni 1991 l’Ekoo, nitori adigunjale kan ti wọn n pe ni Shina Rambo ni. Adigunjale yii ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ lo ko awọn araalu ni papamọra, ti wọn si n daamu wọn, koda, wọn n yinbọn fun ọlọpaa. Nibẹ ni awọn Mike Okiro ti da ikọ ọlọpaa SARS silẹ, pe ki wọn ma wọ aṣọ, ki wọn gbebọn, ki wọn si maa duro si kọrọ, bi wọn ba gbọ ariwo ole, ki wọn fo jade si wọn. Bi SARS ṣe bẹrẹ l’Ekoo niyi, afi bi kinni naa ṣe di taja-tẹran, to waa di pe awọn kan yoo gbe igi dana, wọn ko ni i wọ aṣọ ọlọpaa, ṣugbọn wọn yoo gbebọn dani, wọn yoo kan maa da awọn eeyan duro. Bawo leeyan ṣe n mọ iyatọ laarin ọlọpaa ati adigunjale lasan, nigba ti awọn mejeeji ko ba wọṣọ. Ohun gbogbo tilẹ waa bajẹ nigba ti aye di aye awọn ọmọ Yahoo, awọn ọlọpaa yii ko le adigunjale kiri mọ, awọn ọmọ Yahoo ni wọn n wa. Nitori bẹẹ, ti wọn ba ti ri ọdọ kan ninu mọto to dara, wọn yoo da a duro, wọn yoo ni ọjọ ori ẹ ko to lati gun mọto bẹẹ. Wọn ko mọ ọjọ ori ẹ o, wọn ko mọ ibi to ti n ṣiṣẹ, bẹẹ ni wọn ko mọ baba ẹ tabi ile ibi to ti wa. Bi wọn ba ti da a duro ni wọn yoo bẹrẹ si i fi ibọn halẹ mọ ọn, ti wọn yoo ni awọn yoo yinbọn pa a ti kinni kan ko ni i ṣe, ti ko ba ti fun awọn lowo. Bi ọdọ kan gbe kọmputa dani to n lọ, wọn yoo da a duro, bi wọn ri foonu to daa lọwọ ọdọ kan, wọn yoo gba foonu ẹ, wọn yoo maa yẹ ẹ wo, owo ṣaa ni wọn n wa kiri ni tiwọn, ki i ṣe adigunjale mọ, bẹẹ ni ki i ṣe ohun ti wọn tori ẹ da SARS silẹ, ohun ti awọn ọlọpaa yii yoo jẹ lawọn n wa, tiwọn si buru ju ti awọn adigunjale lọ. Meloo meloo ni awọn ọmọ ọlọmọ ti wọn ti pa, iṣẹ ti ko kan wọn ni wọn n da si, adigunjale ni wọn ni ki wọn maa mu, awọn ọmọ Yahoo ni wọn maa n le kiri. Ki lo kan SARS pẹlu ọmọ Yahoo! Ko si ohun to kan wọn nibẹ. Nitori awọn Yahoo ati awọn ka ṣebajẹ mi-in ni EFCC ṣe wa, ọrọ wọn ko kan awọn SARS yii rara. Ṣugbọn wọn ti gba iṣẹ naa kanri, nitori wọn n ri owo biribiri nibẹ, wọn n ja awọn eeyan lole nibẹ, wọn n lo aṣọ ọlọpaa lati rẹ awọn araalu jẹ ni. Ohun to mu ki awọn eeyan rọ jade ree, ti wọn si n sọ pe awọn ko gba mọ, o ti to gẹẹ, ki SARS yee pa awọn lọmọ, ki wọn yee sọ ibanujẹ sile aladun, ki wọn dojukọ iṣẹ ti wọn gbe fun wọn gan-an. SARS ko wulo fun araalu mọ, ijọba paapaa ko si ri ere wọn jẹ. Ki ijọba yii tete tu wọn ka, araalu lawọn ko fẹ mọ, ohun ti araalu ko ba fẹ, ijọba kankan ko gbọdẹ fẹ ẹ. Ẹ tu SARS ka o, gbogbo aye lo sọ pe awọn ko fẹ wọn.

 

Ewo ni Buhari n sọ yii, ẹ jẹ yaa ba awọn baba yin sọrọ

Awọn ọdọ ni wọn ṣewọde, awọn ni wọn binu ju lori ọrọ SARS yii, nitori awọn naa lo kan ju si ni. Gbogbo bi wọn ti n ṣe iwọde to yii, wọn kuku ṣi n dana iwa aburu wọn kiri, wọn yinbọn fawọn kan l’Ogbomọṣọ ti wọn ni iṣẹ ọwọ awọn SARS yii ni. Iyẹn lawọn ọmọde ilu ṣe tun tori ẹ gboro si i. Ninu awọn ọdọ ilu ni ọmọbinrin Aarẹ Buhari kan naa wa, iyẹn Sarah ati ọmọ Ọṣinbajo to n jẹ … Awọn mejeeji ni wọn lọ si ori ẹrọ ayelujara tiwọn naa, ti wọn si kọ ọ sibẹ pe ki wọn fopin si SARS kiakia, awọn naa ko fẹ wọn niluu mọ, iwa ika ni wọn n hu ni Naijiria. O fẹrẹ ma si ẹni ti ko ya lẹnu pe ọmọ Buhari ati ọmọ Ọṣinbajo yoo sọ pe ki ijọba ba awọn pa SARS rẹ. Ṣugbọn ko yẹ ko yaayan lẹnu, ọdọ ni awọn ọmọbinrin mejeeji yii, awọn naa si mọ ohun to n lọ, wọn mọ ohun ti SARS n foju awọn ẹlẹgbẹ wọn ti ki i ṣe ọmọ alagbara ri. Ṣugbọn ki i ṣe ori ẹrọ ayelujara lawọn mejeeji yii maa gba lọ, bo ba jẹ loootọ ni wọn fẹ ki SARS parẹ, pe ko ma si SARS mọ, awọn baba wọn ni ki wọn ba sọrọ. Ki ọmọ Buhari wọle tọ baba ẹ, ki ọmọ Ọṣinbajo naa wọle tọ baba ẹ, ki wọn lọọ ṣalaye ohun aburu ti awọn SARS n ṣe, ki wọn jẹ ki wọn mọ bi awọn ọlọpaa ole yii ṣe sọ ara wọn di alapata, ti wọn n pa awọn araalu kaakiri. Ki wọn si jẹ ki wọn mọ pe awọn mọ pe awọn ọdọ ilu ko le ṣe ki wọn ma binu, nitori bi ijọba Buhari yii ti ṣe n sọ lati bii ọdun mẹrin nilẹ yii ree. Wọn yoo ni wọn fi ofin de SARS lọdun yii, laarin oṣu kan, awọn SARS yoo ti tun pada saarin igboro. Wọn sọ bẹẹ ni 2017, wọn sọ bẹẹ ni 2018 pe awọn ti fi ofin de SARS, wọn sọ bẹẹ ni 2019, ki wọn too tun waa sọ eleyii lẹẹkẹrin yii. Buhari tiẹ ti ni awọn ko le pa SARS rẹ, bii ẹni pe awọn ti wọn sọrọ yii ko si ninu ijọba rẹ. Abi nigba ti ọga ọlọpaa pata ba ni oun pa SARS to wa labẹ oun rẹ, ti olori ijọba ba ni ko le pa wọn rẹ, ṣe nnkan mi-in ko si ninu ọrọ yii bẹẹ yẹn ndan! Atunṣe wo lawọn Buhari fẹẹ ṣe si SARS ti wọn ko ri ṣe lati ọdun kẹrin ti wọn ti n leri sẹyin. Ohun to han ni pe Buhari funra ẹ ko mọ ohun to n lọ, ko si wadii, irọ ti wọn ba ti pa fun un yii naa ni. Tabi iru eeyan wo ni yoo maa ṣejọba ti ẹkun awọn eeyan rẹ ko ni i wọ eti rẹ! Iru olori orilẹ-ede wo ni yoo ri awọn ọdọ ti wọn jade lọpọlọpọ bayii ti yoo ni ọrọ ti wọn sọ ko too tẹle, iru olori ijọba wo ni yoo maa sọ bayii pe ti araalu ko jẹ nnkan kan. O daju pe ko le jẹ Buhari lo n ṣe gbogbo eleyii, awọn ti wọn yi i ka ni ko jẹ ko mọ ohun to n lọ, wọn parọ fun un, oun naa n gbọ, awọn yii ko si ni oore tabi anfaani kan ti wọn fẹẹ ṣe e, wọn yoo ti i ṣubu, wọn yoo pada lẹyin ẹ ni. Meloo meloo olori ijọba ti awọn ti ṣe bẹẹ ba tirẹ jẹ, ti Buhari yii kan naa si ba jẹ, wọn yoo maa sọ kiri to ba ya wọn pe awọn sọ fun un, oun ni ko gbọ. Nitori rẹ lawọn ọmọ Buhari ati ti Ọṣinbajo ṣe gbọdọ ba awọn baba wọn sọrọ funra wọn, bi bẹẹ kọ, awọn ole onijẹkujẹ to wa ninu ijọba yii ni yoo ti awọn baba wọn pa, iya rẹ yoo si jẹ awọn naa bo ba ya. Iya gidi ni paapaa. Ẹ yaa ba awọn baba yin sọrọ o.

 

Iru inakuuna wo niyẹn, inakuuna ina apa!

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ka bọjẹẹti, iyẹn owo iṣuna,  owo ti ijọba Naijiria yoo na ninu ọdun to n bọ yii. Owo naa, owo rẹpẹtẹ ni, ṣugbọn ti eeyan ba gbọ bi wọn yoo ti na owo naa, aanu orilẹ-ede yii yoo ṣe e, nitori ko jọ pe ilẹ wa yoo lọ sibi kan ti a ba n ṣe bayii nawo. Ninu gbogbo owo ti ijọba ṣẹ kalẹ pe awọn fẹẹ na yii, ti wọn ba ko ọgọrun-un Naira (N100) kalẹ lati na, Naira mejilelaaadọta (52.00) ni wọn yoo fi sanwo oṣu ati owo ele lori gbese ti wọn ba jẹ, iyẹn ni pe owo to ku ni wọn yoo pin fun awọn eka ijọba to ku, bi awọn aṣofin ati awọn mi-in bẹẹ. Ṣugbọn nigba ti eeyan ba yẹ awọn owo yii wo, inakuuna, ina apa wa ninu wọn. Bii apẹẹrẹ, biliọnu mẹsan-an ataabọ ni awọn aṣofin ilẹ wa yoo fi tun ile-igbimọ yii ṣe o. Ohun to bajẹ nibẹ ko ye ẹni kan, ṣugbọn lọdun to kọja naa, wọn gba biliọnu naira rẹpẹtẹ pe awọn yoo fi tun ile-igbimọ awọn ṣe. Ohun to n bajẹ lọdọọdun, to n gba biliọnu biliọnu bẹẹ, ko yeeyan o. Lọdọọdun yii naa ni wọn yoo ra mọto tuntun, biliọnu mejila naira ni wọn si fẹẹ fi tun awọn ẹronpileeni ti aarẹ n gun kiri ṣe lọdun yii, bẹẹ naa ni wọn fi biliọnu rẹpẹtẹ tun un ṣe lọdun to kọja, ki Aarẹ Buhari si too gbajọba lo n sọ fun wa pe inakuuna ni lati maa ko ẹronpileeni kan jọ ka pe e ni ẹronpileeni Aarẹ, pe iru iyẹn ko dara, oun ko si ni i ṣe bẹẹ ni toun. Ṣugbọn ohun to ni oun ko ni i ṣe yii, koda, o ṣe e buru ju ti awọn ti wọn wa nibẹ tẹlẹ lọ. Ọpọlọpọ inakuuna mi-in lo tun kun inu eto iṣuna yii, bẹẹ ni wọn ko ni i nawo gidi sidii eto ẹkọ, wọn ko ni i fi owo ṣeto ilera, awọn ohun ti ko ni i mu anfaani wa fun araalu, to jẹ awọn nikan ni anfaani ibẹ yoo wa fun, awọn ohun ti wọn maa n ṣe niyẹn. Awọn ohun ti wọn ṣe ti ilọsiwaju kan ko fi ba wa ree, inakuuna ina-apa pọ ju ibi ti wọn nawo gidi si lọ. Nibi ti ọrọ ilẹ yii de duro bayii, awọn kinni kan wa ti a ko gbọdọ maa fi jẹ ara wa niya, ko yẹ ki ijọba yii maa fi ifẹ ara wọn ati ti awọn diẹ ti wọn jọ n ṣejọba jẹ awọn araalu to ku niya. Iya n jẹ wa ki i ṣe kekere, nitori gbogbo awọn ohun amayedẹrun ilẹ wa ni ko dara. Ṣugbọn ijọba ko mojuto wọn, kaka bẹẹ, awọn yoo ra mọto nla nla nitori ọna ti ko dara, wọn yoo ra ẹronpileeni ki wọn le maa fo lofurufu nitori galọọpu, wọn yoo ra jẹnẹretọ olowo nla nitori igba ti awọn onina ba muna lọ, bẹẹ gbogbo owo ti wọn n na yii ki i ṣe owo wọn, nitori ki wọn si le maa ri owo wa ko bayii ni wọn ṣe maa n fẹẹ ku sidii oṣelu, ti wọn yoo maa purọ pe awọn fẹẹ tun aye awọn kan ṣe. Ijọba yii gbọdọ sinmi inakuuna ina-apa, ki wọn le jẹ ki aye awa paapaa daa. Abi aburu la ṣe ti a yan wọn sipo ni! Eleyii ko ma daa!

 

Afi ki Tinubu jade nibi to ba wa o

Aṣiwaju Tinubu nikan lo le mọ idi to fi n ṣe awọn ohun to n ṣe. Ṣugbọn igba to ba ya, ko ni i si ẹni ti ọkunrin naa yoo da lẹbi ju ara re lọ. Awọn kan lọ ṣi ọfiisi nla kan si Abuja, wọn ni awọn eeyan Tinubu, ati pe ọfiisi ti awọn ṣi si Abuja yii, ọfiisi ti Tinubu yoo fi kampeeni ni, ṣugbọn Tinubu funra ẹ ko mọ, bẹẹ ni ko da si i, awọn lawọn ṣe e fun un. Iru ọrọ dindinrin ati ọrọ rirun wo niyẹn. Tinubu kọ lo ni ki wọn gba ọfiisi, awọn lawọn lọọ gba a fun un, kin ni itumọ iyẹn! Ṣe awọn ni araalu fẹẹ dibo fun ni abi Tinubu! Ti Tinubu ba fẹẹ ṣe aarẹ, ṣebi funra rẹ ni yoo jade wa, ti yoo ni oun fẹẹ ṣe aarẹ, ti yoo si sọ awọn ohun ti yoo ṣe fun araalu. Ṣugbọn awọn kan jade, wọn ni awọn lawọn gba ọfiisi fun un, ko ran awọn niṣẹ. Ọfiisi naa ki i ṣe ti olowo kekere o, ọfiisi nla ni, awọn oṣiṣẹ yoo si maa ṣiṣẹ nibẹ. Ṣe awọn naa ni wọn yoo maa sanwo awọn oṣiṣẹ ati inawo gbogbo to ba ni yoo jade lati ibẹ. Lara ohun to maa n bi awọn eeyan ti wọn ba ni laakaye ninu si awọn oloṣelu wa ree. Kin ni itumọ gbogbo raurau ti wọn n ṣe yii, ṣe ki wọn le sọ pe awọn eeyan lo waa bẹ Tinubu ni, pe ki i ṣe oun lo ni oun fẹẹ di aarẹ. Iru awọn irọ ati iwa arekereke bayii ko ta mọ, eyi to fi han pe awọn oloṣelu yii ko mọ ohun to n lọ laarin ilu rara. Ta lo wa ni Naijiria yii ti ko mọ pe ko si ero meji lọkan Tinubu mọ ju bi yoo ti ṣe di olori ijọba Naijiria ni 2023 lọ. Gbogbo ohun to n ṣe, gbogbo awọn iwa to n hu, ati bo ṣe di ọta awọn eeyan mi-in, ṣebi nitori ọrọ pe o fẹẹ di aarẹ ni 2023 yii ni. Ki lo wa n ba oun naa lẹru ti ko le jade pe oun fẹẹ du ipo aarẹ, ewo ni ti awọn abọbakogo, awọn abọbaku, ati awọn ẹru oloṣelu ti wọn n huwa ti awọn naa mọ pe irọ ati ẹtan ni. Bi Tinubu ba fẹẹ jẹ aarẹ ilẹ yii, ko le wa ni kọrọ ko maa tan araalu jẹ, tabi ko maa ran awọn ẹlẹtan kan si gbogbo ilu, ki wọn jọ maa purọ funra wọn, ki wọn ro pe awọn eeyan lawọn n tan jẹ. Aye ti gbọn ju bẹẹ lọ. Atiku ti jade, ko si fi bo pe oun yoo di aarẹ, bẹẹ lawọn eeyan ti n ro aṣọ tuntun fun Goodluck Jonathan lati gbe e jade bii eegun lẹẹkan si i. Tinubu wa ni kọrọ ibi kan ti wọn jọ n tan ara wọn jẹ. Ṣe ẹru Buhari lo n ba Tinubu ni abi tita ni! Afi ko jade si gbangba o, bi bẹẹ kọ, yoo fi ẹran ara ẹ yi yẹpẹ lasan ni.

Leave a Reply