O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Ta lo ji awọn ọmọleewe Kakara gbe gan-an!

Nigba ti ariwo sọ pe wọn ji awọn ọmọleewe ojilelọọọdunrun ati mẹta lọ ni Kankara, nipinlẹ Katsina, lọsẹ to lọ lọhun-un, awọn Boko Haram ni wọn kọkọ sare jade, wọn ni awọn lawọn ji awọn ọmọ naa gbe, ati pe idi ti awọn fi ji wọn gbe ni pe wọn n kọ wọn ni ẹkọ iwe ni ileewe ti wọn n lo yii, awọn ko si fẹ bẹẹ rara. Ko pẹ lẹyin ti awọn Boko Haram yii sọ eyi ni wọn tun gbe fidio mi-in jade, nibi ti awọn ọmọ ti wọn ji gbe yii ti n sọrọ, ti wọn si fẹnu ara wọn sọ pe awọn Boko Haram lo ko awọn, awọn ko si fẹ ki ijọba ran awọn ṣọja wa, wọn fẹ ki wọn waa gba wọn silẹ ni, ki wọn fun wọn ni ohun ti wọn ba n fẹ. Ṣugbọn nigba ti wọn ri awọn ọmọ yii, Gomina ipinlẹ Katsina, Masari, lo kọkọ sọrọ, o ni ki i ṣe awọn Boko Haram ni wọn ji awọn ọmọ naa ko, pe awọn mi-in ni. Nigba ti awọn ọga ṣọja naa n sọrọ pẹlu, awọn naa ni ki i ṣe awọn Boko Haram lo ji wọn gbe, wọn ni awọn Boko Haram kan fẹẹ fi ọrọ naa gba iyi lasan ni. Bo ṣe n ṣe niyẹn ki i jẹ ki awọn eeyan mọ ọjọ iku abiku gan-an, nitori bo ba daku, awọn ti wọn ba wa nibẹ yoo ni bo ṣe maa n ṣe niyẹn, ko ni pẹẹ ji dide pada. Ohun ti wọn yoo si maa sọ titi ti yoo fi kọja si odikeji aye niyẹn. Bẹẹ lọrọ awọn ọga ṣọja wọnyi ati awọn ti wọn n ṣejọba, irọ buruku kun ẹnu wọn, o si maa n ṣoro lati gba wọn gbọ nigba ti wọn ba n sọ tẹnu wọn yii. Ọrọ ti wọn sọ yii ko dun lẹnu, ko tiẹ dun lẹnu rara! Bẹẹ ni ko ṣee gbọ, nitori ọrọ mejeeji lo buru! Bo ba jẹ Boko Haram lo ji wọn ko, iyẹn buru, nitori o fi han pe apa awọn ologun wa ti wọn n pariwo kiri lati ọjọ yii pe awọn ti kapa awọn Boko Haram yii ko ti i ka wọn, irọ buruku ni wọn n pa fun araalu, awọn Boko Haram yii lọga wọn. Bẹẹ lo takubu fun ijọba Buhari naa pe awọn Boko Haram ti wọn fi n yangan pe awọn ti yanju ko ri bẹẹ, opurọ ni wọn. Iyẹn bo ba jẹ Boko Haram lo ji wọn ko. Bo ba waa jẹ loootọ ni pe ki i ṣe Boko Haram lo ji wọn, iyẹn buru jai, nitori ewu buruku niyẹn. Idi ni pe bi awọn janduku kan ba fi lagbara, ti wọn si ni ọmọ ogun ati irinṣẹ to le mu wọn ji awọn ọmọ ti wọn le ni ọgọrun-un mẹta lẹẹkan naa, awọn yii fẹrẹ le ju Boko Haram gan-an lọ. Nibo ni wọn ti wa? Nigba wo ni wọn debẹ? Nibo ni wọn ti ri awọn irinṣẹ ti wọn n lo? Bawo ni wọn ṣe ni awọn ọmọ-ogun ati owo to to lati fi ṣe ohun ti wọn ṣe yii? Ohun to yẹ ki awọn ọga ologun wa gbogbo ṣalaye fun araalu ree, to si yẹ ki wọn sọ orukọ iru ẹgbẹ afẹmiṣofo buruku to tun fẹẹ le ju Boko Haram lọ fawọn ọmọ Naijiria. Nitori pe awọn eeyan ko ridii awọn ọrọ wọnyi ni wọn ṣe n sọ pe ọrọ awọn ọmọ ti wọn ji gbe yii, o ṣee ṣe ko jẹ ijọba Naijiria funra wọn ni wọn n dọgbọn eyi, tabi ko jẹ awọn eeyan wọn nilẹ Hausa ni wọn n ṣe eleyii lati fi ko owo kuro lapo ijọba, nitori owo buruku ni iru eleyii yoo na, bẹẹ lawọn kan sọ pe o le jẹ awọn ṣọja funra wọn ni wọn ṣe eyi, ki ọmọ Naijiria le sọ pe wọn ti n ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ. Eyi o wu ko jẹ, ọrọ ohun to ṣẹlẹ ru awọn ọmọ Naijiria loju gan-an ni o, Buhari ati awọn ti wọn jọ n ṣẹjọba yii si gbọdọ sọ bi ọrọ ti ri gan-an. Ohun to le gbe ijọba wọn niyi ree, ootọ nikan ni! Bi wọn ba purọ bayii, ọrọ naa yoo lo diẹ, ṣugbọn ko ni i pẹ ti  okun irọ naa yoo fi ja, orukọ wọn yoo si pada bajẹ ju bo ti wa bayii lọ. Ta lo ji awọn ọmọ ileewe Kankara yii ko? Gbogbo awọn ọmọ Naijiria fẹẹ mọ o!

 

Wọn ni awọn ajinigbe yii ko gbowo, irọ mi-in tun niyẹn o

Purọ ki n niyi, ẹtẹ ni yoo kangun ẹ, bi yoo ti ri fun Gomina Masari ti ipinlẹ Katsina, ati awọn eeyan ijọba apapọ ree, nitori irọ mi-in ti wọn pa bayii yoo tun tuka bo ba ya, a oo si gbọ ohun to ṣẹlẹ gan-an. Lakọọkọ, ko sẹni to beere lọwọ Gomina Katsina boya wọn gba owo lọwọ rẹ ki wọn too fi awọn ọmọ ti wọn ji gbe yii silẹ, tabi wọn ko gbowo. Funra ẹ lo sọ pe wọn o gbowo lọwọ oun. Ṣugbọn gbogbo ọmọ Naijiria lo mọ pe irọ niyẹn, nitori awọn ti wọn waa ji awọn ọmọ yii ko ko wa lati ra aṣọ ọdun fun wọn, wọn wa lati gba owo, ki wọn le ri owo ra awọn ohun ija ati awọn nnkan mi-in ti wọn ba fẹẹ ṣe ni. Tabi bawo ni ijọba ṣe gba awọn eeyan yii lai sanwo, ti ẹni kan bayii ko si ku ninu awọn ọmọ ti wọn ji ko naa. Ko si ibi ti iru rẹ ti n ṣẹlẹ. Bi ṣọja ba pa awọn eeyan yii bi wọn ti wi, funra wọn ni wọn yoo fi idunnu gbe oku awọn ajinigbe naa sita, ti wọn yoo si sọ pe awọn ree, bi awọn ṣe pa wọn ree, ki awọn too gba awọn ọmọ ti wọn ji ko. O waa kere tan, ninu awọn ọgọrun-un mẹta o le ọmọ ti wọn ji ko yii, ẹyọ kan tabi meji yoo farapa bi wọn ko ba tilẹ ku. Ki gomina yii yee parọ fawọn araalu o, ko ṣẹni ti ko mọ pe owo ni wọn fi gba wọn, ohun ti wọn si n bẹru ti wọn fi n pariwo yii ni pe araalu yoo sọ pe ko daa. Loootọ ko daa, ohun buruku ni lati maa ko owo fun awọn janduku afẹmiṣofo, nitori iru iwa bẹẹ ko ni i jẹ ki ipaayan ati ijinigbe tan nilẹ wa. Sibẹ, a ko le ni ki awọn ọmọ ti wọn ji ko yii di ẹni anù, bo ba jẹ owo naa ni wọn yoo fi gba wọn silẹ, araalu ati awọn ti wọn bi wọn ko ni i lodi si i. Ṣugbọn ohun ti ijọba gbọdọ ṣe ni lati ri i pe iru rẹ ko tun ṣẹlẹ mọ, ki wọn jẹ ki eto aabo adugbo ati ti Naijiria lapapọ fẹsẹ mulẹ daadaa, ki ọkan araalu balẹ, ki gbogbo wahala yii si dopin. Ki wọn tiẹ kọkọ le awọn olori ologun yii kuro nipo wọn, ki wọn fi awọn mi-in si i fun iyipada eto aabo yii, ki araalu si le ri i pe ijọba yii n gbọrọ si wọn lẹnu. Ẹyin ti ẹ n ṣejọba yii, ẹ yee purọ faraalu mọ, aṣiri yin ko bo, gbogbo ohun ti ẹ n ṣe laraalu n ri o.   

 

Ṣugbọn ki lo kan Miyetti Allah, ẹgbẹ awọn onimaaluu, ninu ọrọ yii o

Gomina Masari yii naa lo tun ja bọ, nitori ni gbogbo igba ti ọrọ yii n lọ, oun kan n ja bọ lọ ni tirẹ ni. Masari ni awọn Miyetti Allah lo n ba awọn ṣiṣẹ lati wa awọn ọmọ ti wọn ji gbe yii, iyẹn ni pe awọn ẹgbẹ onimaaluu yii ni ijọba n lo lati ba awọn Boko Haram ati awọn janduku mi-in sọrọ. Itumọ eyi ni pe ijọba yii mọ pe awọn Fulani ni wọn n ṣe iṣẹ ibi wọnyi ni orilẹ-ede wa, wọn si mọ pe awọn onimaaluu darandaran ti wọn n kiri inu igbo wa yii naa ni ọdaran to n yọ araalu lẹnu. Ohun to n fa igberaga ati iwa ta-ni-yoo-mu-mi ti awọn Fulani n hu nilẹ yii niyẹn. Iyẹn ni pe ẹgbẹ awọn Miyetti Allah wa lara awọn ti wọn mọ awọn Boko Haram ati janduku, ki lo waa de ti wọn ko le sọ fun ijọba ibi ti wọn wa, ki wọn ba awọn olori ologun wa sọrọ, ki wọn tu aṣiri awọn ẹni ibi yii, ki ijọba si lọọ ko wọn lọjọ kan. O han bayii pe iṣoro ti a ni nilẹ yii, iṣọrọ awọn Fulani ni. Fulani lo n ji awọn eeyan wa gbe, Fulani ni awọn afẹmiṣofo, Fulani naa la si n bẹ si wọn ki wọn tu awọn ti wọn ba ji gbe silẹ. Nidii eyi, ẹgbẹ Miyetti Allah ni yoo gba owo ti ijọba ba fẹẹ fun awọn Boko Haram, awọn ni wọn yoo si lọọ gbe e fun wọn laaye wọn. Bi owo ba ti waa tan lọwọ Miyetti Allah, bo si jẹ lọwọ awọn ajinigbe funra wọn, wọn yoo wa sigboro, wọn yoo ko awọn ọmọ wa, Miyetti Allah yoo si tun gbowo lọwọ ijọba ki wọn too ko awọn ọmọ silẹ. Iru ọran wo ni awọn ọmọ Naijiria kuku da lọwọ ijọba Buhari yii, ki la kuku ṣe ti nnkan fi ri bayii. Ṣe aṣiṣe ni awọn ọmọ Naijiria ṣe lati dibo fun Buhari ni, tabi ki lo de ti baba naa fi aaye gba awọn Fulani lati maa ni wa lara bayii! Gbogbo araalu lo pariwo pe awọn Fulani ni wahala wa, sibẹ, ọrọ naa ko kan Buhari, yoo ṣe bii ẹni pe oun ko gbọ ni. Bẹẹ lawọn Fulani n gbooro si i, wọn n da ẹgbẹ silẹ, wọn si ti sọ ijinigbe ati awọn iwa buruku mi-in di iṣẹ ojulowo wọn. Ẹyin aṣaaju APC tẹ ẹ ni Buhari n bọ waa ṣe rere fun Naijiria, ẹ ẹ si ba a sọro pe ko ma sọ orile-ede wa di ti Fulani, ko ma jẹ ki awọn Fulani run wa lọmọ tan. Ẹ sọ fun un ko tete wa nnkan ṣe sọrọ awọn Fulani yii, ki wọn too ba a lorukọ jẹ patapata!

 

Eewọ ni, Lai Muhammed o le ṣe ko ma sọrọ

Nigba ti eeyan ba n gbọ ọrọ lẹnu awọn ti wọn n ba Aarẹ Muhammadu Buhari ṣiṣẹ, aanu orilẹ-ede yii yoo si ṣe ni titi. Ni gbara ti wọn ji awọn ọmọleewe Kankara yii gbe, ti wọn si sọ iye awọn ọmọ ti wọn ji ko, ti wọn ni o le lọgọrun-un mẹta, kia ni Garuba Shehu sare jade lorukọ Buhari ati ileeṣẹ Aarẹ, o ni irọ lawọn eeyan n pa, awọn ọmọ mẹwaa pere ni wọn ji ko nitori gbogbo awọn ọmọ ko to ku ni wọn ti pada sọdọ awọn obi wọn. Ṣugbọn nigbẹyin, wọn ko awọn ọmọ ojilelọọọdunrun ati mẹrin (344) de, loju Garba Shehu yii naa ni o. N lo ba tun jade, alainitiju, o ni ki awọn ọmọ Naijiria ma binu. O jade waa sọ ohun to n sọ yii nitori pe wọn ri awọn ọmọ yẹn ni o, to ba jẹ awọn ọmọ naa ṣe bẹẹ ra sinu igbo nibẹ, ohun ti yoo maa sọ naa niyẹn o, pe ọmọ mẹwaa pere ni wọn ji ko, bi gbogbo aye si n sọ pe ko ri bẹẹ, ohun ti yoo maa tẹnu mọ niyẹn, eyi to n sọ yii naa nijọba ati Buhari paapaa yoo si maa sọ, bẹẹ ni wọn yoo mu awọn ti wọn ba si sọ pe bẹẹ kọ lọrọ ri lọtaa, ti wọn yoo ni PDP tabi awọn alatako awọn ni. Eyi to buru ni pe awọn araalu kan yoo maa tẹle wọn lori irọ buruku ti wọn n pa yii, wọn yoo ni ootọ ni. Bi ijọba yii ti ri ree, ijọba awọn onirọ ati ẹlẹtan ni. Ni gbogbo igba ti ọrọ naa n gbona, Lai Muhammed ti i ṣẹ minisita iroyin mori mu, o fori ara rẹ pamọ, nitori wọn ko kuku jẹ ki oun paapaa mọ ohun to n lọ. Ṣugbọn ni gbara ti wọn ti ri awọn ọmọ naa, o sare jade, o ni loootọ ni Buhari lọ si Katsina, ti ko lọ sibi ti wọn ti ji awọn ọmọ ko, ṣugbọn o n ṣiṣẹ labẹlẹ pẹlu awọn ọga ologun, iṣẹ to si ṣe naa lo jẹ ki wọn ri awọn ọmọ naa gba pada. Nigba ti agbalagba ba lanu to ba n sọ iru awọn ọrọ kan jade lẹnu, eeyan ko le pe ẹni bẹẹ ni agbalagba, ọmọde lasan leeyan yoo pe e. Awọn ọrọ ti Lai Muhammed si maa n sọ fi i han pe loootọ lo wa ni ipo agba, ṣugbọn ọrọ ọmọdẹ lo maa n sọ lẹnu, nitori ọmọde lo maa n purọ ojukoju, ti yoo si ro pe awọn ti wọn wa nibẹ ko mọ pe irọ loun n pa. Ki lo de ti Lai Muhammed ko sọrọ nigba ti wọn ji awọn ọmọ naa ko, ojuṣe rẹ ṣaa ni lati sọrọ, ko si sọ ohun ti ijọba wọn n ṣe lori ọrọ wọn. Ki lo de ti Lai Muhammed ko sọrọ nigba ti Buhari lọ si Katsina ti ko de ibi ti awọn ọmọ yii wa, ti gbogbo araalu si n pariwo pe ohun to ṣe ko dara. Lai ko le sọrọ, nitori Buhari ko dagbere fun un, ko si mọ pe o n lọ sibi kan, oun naa kan gbọ bi gbogbo awọn ọmọ Naijiria to ku ṣe gbọ ni. Ṣugbọn ko le ṣe ko ma lanu sọrọ, eewọ ni. Kaka ki Lai sinmi, ko ma da si ọrọ ti ko ba mọ, yoo jade sọrọ, ki awọn ti wọn n lo o bii ẹru le mọ pe o n ṣiṣẹ fawọn. Tabi kin ni abọrọ lanu sọrọ ti ki i ṣe ododo si. Nibo ni Buhari ti ṣepade pẹlu awọn olori ologun? Ọrọ wo lo tẹnu Buhari funra ẹ jade ju pe inu oun bajẹ lọ, awọn eeyan kan ni wọn si kọ ikọkukọ bẹẹ jade. Ṣe dandan ni ki Lai Muhammed sọrọ ni! Ṣe dandan ni ko da si ohun ti ko ba mọ nipa ẹ ni! Tabi wọn ṣepe irọ pipa fọkunrin yii ni! Eleyii ma ti kuro loju lasan o!

Leave a Reply