O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Kin ni ijọba Buhari yii fẹ gan-an?

Ijọba Naijiria gbe ofin tuntun kan jade, ofin to n ṣeto idasilẹ ileeṣẹ aladaani, ẹgbẹ alaaanu, ẹgbẹ ajijagbara ati awọn ile-ijọsin gbogbo ni. Ọjọ keje, oṣu yii, ni Aarẹ Muhammadu Buhari si fọwọ si ofin yii, lati ọjọ naa lo si ti mu wahala rẹpẹtẹ dani. Bo ba ṣe pe ni ilu to dara la wa ni, ko si ohun ti yoo buru ninu iru ofin bayii, nitori ofin ti wọn n lo n l’Amẹrika ati United Kingdom ni ijọba Naijiria gbe lodidi, ti wọn si ko o jọ lati fi ṣe ofin tuntun fun wa. Ohun to fa wahala ninu ofin yii ni pe ijọba Naijiria le gba ileeṣẹ ti ẹni kan da silẹ, wọn le gba ileeṣẹ ti ọpọ eeyan da silẹ, ki wọn si yan awọn ti yoo maa paṣẹ ileeṣẹ bẹẹ, ki ileeṣẹ naa si di tiwọn. Ijọba tilẹ le pa ileeṣẹ naa rẹ pata lai wulẹ lọ si kootu fun ohun kan. Bakan naa, ijọba le gba ṣọọṣi lọwọ awọn to ni in, ti yoo si di tiwọn, bo si jẹ mọṣalaasi naa ni, tabi ile-ijọsin. Eyi tumọ si pe bi awọn ile ijọsin bii Ridiimu, Winners, Mountain of Fire, Nasfat, tabi awọn mi-in bẹẹ ba ṣe ohun ti ko tẹ ijọba lọrun, kia ni wọn yoo gba wọn lọwọ awọn to ni wọn, ti wọn yoo si sọ ṣọọṣi bẹẹ, tabi mọṣalaaṣi di tiwọn. Awọn eeyan yoo maa jọsin nibẹ loootọ o, ṣugbọn ijọba ni yoo yan pasitọ tabi lemọọmu fun wọn, ti wọn yoo si maa gba gbogbo ohun to ba tọ si ile-ijọsin naa. Bo ba waa jẹ awọn ẹgbẹ ajijagbara bii OPC, Agbẹkọya, tabi Afẹnifẹre, Ohaneze, ati awọn ẹgbẹ alaaanu loriṣiiriṣii naa ni wọn huwa ti ko tẹ ijọba yii lọrun, wọn yoo le awọn ti wọn n ṣe ẹgbẹ naa kuro, wọn yoo si ko awọn adari mi-in si i, ẹgbẹ naa yoo si di tiwọn. Ohun to fa wahala tawọn eeyan n ba wọn fa lori ofin naa ree o. Ko si ohun to buru bi ijọba ba ṣe ayipada si ofin lati jẹ ki ohun gbogbo lọ deede, ṣugbọn ayipada to ba lọwọ kan abosi ninu bii iru eleyii, to jẹ pe awọn ti wọn n ta ko ijọba, awọn ẹgbẹ to n sọ ootọ funjọba, awọn ti wọn n ba ijọba ja nitori pe ijọba ko ṣe daadaa ni wọn tori ẹ ṣe ofin lile yii, ko si ki ọrọ naa ma la ariwo lọ. Ṣebi awọn ofin kan ti wa nilẹ tẹlẹ, ofin pe bi ẹgbẹ tabi ileeṣẹ kan ba ṣe aidaa, ki wọn gbe e lọ si kootu, ki ile-ẹjọ da sẹria to ba yẹ fun un. Tabi bo jẹ ile-ijọsin, tabi olori ijọ kan, lo ṣe ohun ti ko dara naa, ofin ti wa pe ile-ẹjọ yoo dajọ to ba ba iwa ti wọn hu mu. Ewo waa ni ki ijọba ni oun yoo gba ileeṣẹ ti awọn eeyan mi-in ti da silẹ lati ogun, ọgbọn ọdun, kuro lọwọ wọn. Tabi ewo ni ki wọn gba ileejọsin ti awọn ẹni ẹlẹni ṣe wahala lati ko jọ kuro lọwọ wọn. Iru ofin yii ko ni i jẹ ki ọkan araalu balẹ, nitori awọn ti wọn ba mọ ododo ko ni i le sọ ododo. Bẹẹ ni ko ni i sẹni ti yoo sọ ododo kan fun ijọba yii mọ, koda ki ijọ̣ba naa maa wọgbo lọ, awọn eeyen yoo maa wo o ni. Eleyii ko dara fun Naijiria, koda, ko dara fun orilẹ-ede to ba n mura lati ṣe rere fawọn eeyan rẹ. Loootọ ni ijọba Buhari ti n ṣe kan-un kan-un tẹlẹ, ṣugbọn eyi ti wọn waa ṣe yii, ifasẹyin gbaa ni wọn n wa lati fun Naijiria, rogbodiyan ti yoo si ti idi rẹ yọ lọjọ iwaju yoo kọ sisọ. Ẹ tete ba wọn sọrọ o, ki wọn yaa yi ofin naa pada kiakia.

 

Iru ọrọ rirun wo niyẹn

Iyawo Aarẹ orile-ede wa, Aisha Buhari, de lati Dubai lọsẹ to kọja yii. Pẹlu ainitiju ati iwa ki-le-fẹẹ-ṣe-fun-mi to ti mọ awọn eeyan ti wọn n ṣejọba wa lara lobinrin naa fi sọ pe loootọ loun lọ si Dubai lati lọọ ṣetọju ọrun to n dun oun. Ọrọ naa run leti, o si tiiyan loju pe iru ede aika awọn ọmọ orilẹ-ede yii si bẹẹ yoo ti ẹnu ẹni to pe ara rẹ ni iyawo olori orilẹ-ede wa jade. Ọrun n dun Aisha, o tori ẹ lọ si Dubai, ki waa  ni ki awọn ti gẹgẹ yọ lọrun wọn ti wọn ko rowo ra parasitamọọ lasan ṣe. Tabi to ba ṣe pe oun ki i ṣe iyawo olori ijọba, nibi ti wọn ti n ri owo ọfẹ bayii na, oun waa le gbe iru aiyaara bẹẹ lọ si Dubai ndan! Ṣugbọn owo ọfẹ wa, ọkọ-ofurufu ọfẹ wa, bi wọn ba fẹẹ ṣe igbọnsẹ, ti igbọnsẹ naa ba le ju, wọn le ni ki wọn sare gbe awọn lọ siluu oyinbo ki awọn lọọ ṣe gaa sọhun-un, nitori ki wọn ma baa ku. Iru iwa yii ko daa, o si baayan ninu jẹ pe Buhari to tan gbogbo ọmọ Naijiria pe oun n mu ayipada rere bọ si iru awọn iwa ibajẹ bayii lo waa jẹ oun ati idile rẹ gan-an ni wọn n fi iwa ibajẹ yii ṣe ayọ, ti wọn si n gba gbogbo ọmọ Naijiria loju. Eleyii ko daa! A waa wi tan, iyawo Aarẹ ni ki awọn oniṣegun to ni ileewosan, iyẹn awọn dokita ti wọn ni ileewoṣan tiwọn, ki wọn tun wọn ṣe daadaa, ki awọn eeyan ti wọn n lọọ gba itọju ni ilu oyinbo le dinku, ki wọn yee lọ sibẹ mọ. Ohun ti obinrin yii n sọ ni pe oun naa mọ pe eto ilera ati iwosan ilẹ yii ko daa. Ṣugbọn ko le ba ọkọ rẹ sọrọ pe ko tun awọn ileewosan to jẹ tijọba ṣe, awọn ileewosan ti wọn wa ni yunifasiti to jẹ tijọba, ati awọn ileewosan ti ijọba apapọ n fi orukọ wọn yọ owo nla lọdọọdun. Ko le sọ pe ki wọn tun awọn yii ṣe, ko si le beere bi awọn ti wọn n gba owo lori ọsibitu Aso Rock ṣe n nawo naa lọdọọdun ti ibẹ ko fi ṣee lo fun Aisha ati ọkọ rẹ, to si jẹ biliọnu lo n lọ sibẹ lọdun kọọkan. Obinrin yii ko le beere bẹẹ, ohun kan ṣoṣo to le gba awọn ọmọ Naijiria nimọran le lori ni ki awọn dokita to ni ọsibitu tiwọn lọọ tunbẹ ṣe. Iru iwa agabagebe ati ọrọ rirun wo niyẹn. Ki lawọn eeyan yii n fi awọn ọmọ Naijiria pe na! Tabi wọn sọ gbogbo wa di ọlọpọlọ kiku ni. Awọn ti wọn n ṣejọba n gba wa loju, wọn si fi n han wa. Beeyan ko mu wọn, ṣe Ọlọrun ko ni i mu wọn ni. Ẹ sọ fun wọn ki wọn mura si i o, idajọ Ọlọrun n bọ lori gbogbo wọn.

 

Ohun ti wọn ṣe fẹẹ ṣera wọ̣n leṣe nitori ọrọ ọlọrọ niyẹn

Kinni kan ni Naijiria yii dara fun, iyẹn naa ni ẹtan, ka maa tan ara wa jẹ. Ka maa tan ara wa jẹ, ka ro pe a n tan awọn araaye jẹ, iwa awọn ti wọn n ṣe olori wa nilẹ yii ni. Njẹ ẹ gbọ pe awọn ṣọja gbajọba lọsẹ to kọja ni orilẹ-ede Mali. Wọn gbajọba nibẹ, nitori rogbodiyan ti awọn oloṣelu ibẹ n ba ara wọn fa, ati bi wọn ṣe n ṣejọba orilẹ-ede naa baṣubaṣu. Kin ni ariwo ta pe wọn ti gbajọba ni Mali si ni, kia ni Naijiria ti bọ ẹwu silẹ ti wọn gbe apẹrẹ wọ, ti Olori ijọba wa, Ọgagun Agba Muhammadu Buhari, si n sọ pe oun ko ni i gba ki awọn ṣọja gbajọba ni Mali! Ibeere ti eeyan yoo beere ni pe kin ni ti Buhari ati awọn ti wọn jọ n ṣejọba ninu ọrọ yii o! Kin ni tiwọn! Ẹni ti yoo ba sọrọ yoo ni nitori orilẹ-ede Mali jẹ ọkan ninu awọn orilẹ-ede West Africa ni, ti wọn tun jẹ ọkan ninu awọn ti wọn jọ n ṣe ẹgbẹ ECOWAS pẹlu Naijiria. Ṣugbọn ki i ṣe iyẹn, ki i ṣe iyẹn rara. Iku to n pa ojugba ẹni, owe lo n pa fun ni ni Buhari n fi ọrọ naa ṣe. Awọn naa kuku mọ pe awọn ko ṣe ijọba Naijiria yii daadaa, wọn si mọ pe bi awọn ṣọja ba ṣe bẹẹ ni Mali ti wọn ba mu un jẹ, awọn ṣọja Naijiria naa le dan iru ẹ wọ. Olori awọn ṣọja ti wọn gbajọba ni Mali yii ni olori awọn ologun to n koju Boko Haram ni adugbo wọn, lara ẹsun to si fi kan ijọba ti wọn le danu ni pe wọn ko da si ọrọ Boko Haram yii bo ṣe yẹ, pe wọn kan n fi ẹmi awọn ṣọja to n jagun naa, ati tawọn araalu ṣofo ni. Ohun to fa a to jẹ niṣe lawọn eeyan tu jade, ti wọn n rẹrin-in, ti wọn n fo soke, ti wọn n ki ara wọn ku oriire, nigba ti wọn gbọ pe awọn ṣọja ti gbajọba lọwọ awọn alakọri oloṣelu ibẹ niyi. O han pe inu ọpọlọpọ ọmọ Mali lo dun si pe wọn gbajọba lọwọ awọn oloṣelu naa, ti ko si si ija tabi wahala kan lati ọjọ ti awọn ṣọja naa ti gbajọba ree, afi awọn olori ilẹ Afrika, paapaa Naijiria, ti wọn n da ara wọn laamu kiri. Aya wọn lo n ja, ẹru lo n ba wọn, pe ohun to ṣẹlẹ ni Mali le ṣẹlẹ ni Naijiria, nitori ọrọ naa jọ ara wọn ju. Ṣe bi awọn ijọba yii ṣe n ṣe ọrọ Boko Haram nibi naa ni wọn yoo wi ni tabi ti ọrọ aje to bajẹ. Ohun to n ba Buhari lẹru ree o. Ẹ sọ fun wọn ki wọn fi Mali silẹ, ki wọn ran tara wọn. Ki wọn ma bẹru mọ o, ẹtọ to ba yẹ ki wọn ṣe fawọn ọmọ Naijiria ni ki wọn tete ṣe fun wọn. Bi bẹẹ kọ, kọlukọlu to kọ lu ara Iwo le kọ lu ara Ẹdẹ o!

 

Wọn kuku tiẹ ti ni ki wọn jẹ ki gbogbo wa maa gbebọn rin

Ododo ọrọ, bii isọkusọ ni i ri nigba mi-in, ṣugbọn ninu ọrọ yoowu ti ọlọgbọn ba sọ, ko ṣee ṣe ki koko pataki kan ma wa ninu ẹ. Iyẹn ni ọrọ  ti Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, sọ ṣe gba apero gidigidi. Ọkunrin naa ni ki ijọba apapọ ṣeto ati ofin ti yoo jẹ ki awọn ti wọn ba jẹ eeyan gidi laarin ilu le maa gbebọn rin, ki awọn ajinigbe ati ọdaran to ku yee pa wọn bii ẹran. Ohun ti ọkunrin yii n dọgbọn sọ ni pe nigba ti apa ijọba yii ko ti ka eto aabo ilẹ yii mọ, ti wọn ko le daabo bo tolowo-ti-mẹkunnu, ki wọn kuku jẹ ki kaluku maa pese aabo funra ẹ, ki awọn ti wọn ba jẹ eeyan gidi maa gbebọn wọn rin kaakiri. Bẹẹ ni tootọ, ti eeyan ba wo awọn ti wọn maa n da awọn eeyan lọna yii, ati awọn ajinigbe yii, bi a ba ti yọwọ ibọn ati awọn ohun ija oloro ti wọn n mu rin kuro, ọpọ wọn ni ko to lati da alagbara mi-in lọna, nitori wọn yoo lu u pa lasan ni. Ṣugbọn nigba ti wọn ba ti gbe ibọn dani, ti wọn mu aake ati ada, ko si ẹni ti yoo le koju wọn, paapaa nigba ti tọhun ko ba ni kinni kan lọwọ. Iyẹn ni ọrọ ti Ortom sọ yii ṣe gbeṣẹ, to si tẹwọn daadaa. Bi ijọba yii ba mọ pe loootọ lawọn ko le gba wa lọwọ Boko Haram, ti wọn ko le gba awọn ọmọ Naijiria lọwọ awọn ajinigbe ati Fulani onimaaluu, ki wọn jẹ ki awọn eeyan gidi niluu ni ibọn tiwọn, ẹni ba yara ninu awọn ati ọdaran ni yoo si kọkọ mu ara wọn balẹ, ko si ni i si pe ọdaran kan n fi ibọn halẹ mọ ẹni kan mọ. Ẹ ronu si ọrọ ti Ortom sọ yii o, bo ba jẹ ohun ti yoo ṣe wa lanfaani ni, ka yaa tete ṣe e.

 

Wọn ni Magu n binu, ki lo ro pe o yẹ ko ṣẹlẹ tẹlẹ

Wọn ni igbimọ to n wadii ọrọ aṣẹmase olori  ajọ EFCC, Ibrahim Magu, ti gbajọba nimọran pe ki wọn tiẹ kọkọ le e danu lẹnu iṣẹ ọba ki awọn too maa ba eyi to ku lọ. Wọn ni iyẹn ni Magu gbọ, lo ba n fapa janu, to n fẹsẹ halẹ, to ni ki awọn lọọya oun maa ko iwe ofin jọ. Ohun ti ọkunrin yii fẹ ko ṣẹlẹ ko yeeyan! Ṣe o fẹ ki wọn tun fi oun ṣe olori EFCC pada lẹyin gbogbo ariwo to ti lọ yii ni, abi ki lo n fẹ gan-an. Tabi inu iṣẹ ọlọpaa ni ki wọn fi i si lẹyin to ti ba ilẹ jẹ to bayii. Kin ni Magu ro pe yoo ṣẹlẹ gan-an. Ṣugbọn ọkunrin naa ko lẹbi o, ko lẹbi rara, bi nnkan ṣe maa n ri ni Naijiria ni. Oun ati awọn baba isalẹ to ni ti rin si ọrọ yii debii pe bi awọn ti wọn n ṣewadii naa ko ba ṣọra, Magu yoo jare wọn nigbẹyin ni. Bẹẹ ki i ṣe pe ọwọ rẹ mọ, tabi pe ko ṣe awọn aṣemaṣe ti wọn lo ṣe yii, ṣugbọn nitori pe awọn agbalagba onibajẹ ni wọn yi Aarẹ ka, ati awọn ti wọn wa lẹyin Magu nitori ki aṣiri tiwọn naa ma baa tu ko ni i jẹ ki wọn ri ojutuu ẹjọ naa ni. Bẹẹ awọn ti wọn n ṣewadii yii leeyan yoo ba wi. Ka lọ sodo ka sun, kin ni araale yoo mu ka too de. Bawo leeyan yoo ṣe lọọ fi ọlọpaa mu ẹni ti wọn ko ti i wadii ọrọ rẹ debi kan, ti wọn yoo si bẹrẹ ariwo lori ẹ. Iru ẹjọ bẹẹ yẹn yoo dojuru gbẹyin ni. Ṣugbọn ẹjọ Magu yii ko gbọdọ daru, bo ba fi le daru, epe lawọn ọmọ Naijiria yoo fi pa gbo awọn ti wọn wa nidii ẹ, nitori pe kalukuku yoo ti mọ pe wọn gbabọde fawọn ọmọ orilẹ-ede yii ni. Ko si ibi ti wọn ki i ti i huwa ibajẹ, koda, wọn n huwa ibajẹ l’Amẹrika, ni London, ṣugbọn ohun ti awọn ijọba ibẹ n ṣe naa ni pe ẹni yoowu ti wọn ba ti mu, wọn ko ni i fi ọwọ bo ọrọ rẹ mọlẹ, ohun to mu orilẹ-ede wọn duro ṣinṣin ree. Ti Naijiria lo yatọ, to jẹ bi wọn ba mu ọdaran nibi, ati ọlọpaa ati adajọ ni yoo maa ba a rẹrin-in wẹnnẹ-wẹnnẹ, titi ti wọn yoo fi ni ko ṣe kinni kan. Bi ọrọ Magu yii ba fi le ri bẹẹ, epe gidi la oo maa gbe yin ṣẹ!

Leave a Reply