Faith Adebọla
Olori ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye, ti ke si awọn ọmọ Yoruba nile loko ati loke okun lati dide lori ọrọ Oloye Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho tawọn agbofinro mu, o lawọn lọọya ti n baṣẹ lọ lori iṣẹlẹ ọhun, ati pe o ṣee ṣe ki ọkunrin naa gba ominira rẹ laipẹ.
Ninu atẹjade kan latọdọ agbẹnusọ rẹ, Maxwell Adelẹyẹ, eyi ti baba naa buwọ lu lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, Opitan Akintoye sọ pe:
“Ọkan mi daru nigba ti mọ gbọ pe wọn mu Oloye Sunday Adeyẹmọ ti wọn n pe ni Sunday Igboho ni papakọ ofurufu Kutọnu lalẹ ana (Mọnde).
Emi ati awọn ọmọ Yoruba atata kan ta a ri ara wa pe ti bẹrẹ iṣẹ bayii lati ṣeranwọ to yẹ, ka si ri i daju pe ẹnikẹni o ṣe aburu kankan fun un tabi ṣe ohun to lodi sofin nipa ẹ, a o si ni i jẹ ki wọn dọgbọn gbe e wa si Naijiria, tori a mọ pe ohun ti wọn fẹẹ ṣe niyẹn.
Inu wa dun pe Orileede Olominira Bẹnẹ (Benin) maa n bọwọ fun ofin, wọn si ṣee fọkan tan. A ti gba awọn lọọya to dantọ gidi, a si mọ pe wọn kaju ẹ lati boju to ọrọ yii.
Ohun to kan bayii ni kawa ọmọ Yoruba nile ati lẹyin odi wa niṣọkan, ka dide papọ, ka figbanu kan ṣoṣo ṣ’ọja, ka fohun kan sọrọ, pe a o ni i gba ki iya kan jẹ Sunday Igboho tabi ẹnikẹni nilẹ Yoruba, a o si ni i jẹ ki wọn ṣe aidaa sọmọ Oodua eyikeyii, tabi ki wọn ṣe e yankanyankan. Lagbara Ọlọrun, orileede to lagbara lawa Yoruba, a gbọdọ gbera lati fi okun ati agbara wa han.
Lakọọkọ, a gbọdọ ri i pe wọn fi Sunday Igboho silẹ, ko wa lominira pada, ko rin, ko yan fanda, tori a mọ pe ko dẹṣẹ kan.
A mọ pawọn eeyan kan ni wọn fẹẹ ko o ni papamọra, wọn fẹẹ pa a danu latari bo ṣe figboya dide nitori awọn eeyan ẹ, awọn obinrin, atawọn ọmọde tawọn olubi ẹda n pa nipakupa, ti wọn n fipa ba lopọ nilẹ baba wọn, ti wọn si ba ọrọ-aje wọn jẹ. Awọn eeyan ti wọn o mọ ju ki wọn pa ẹya kan run lọ, tabi ki wọn jẹgaba le ọmọlakeji lori, bẹẹ awọn to n dari wa lo n daabo bo wọn ti wọn fi raaye nayẹ apa wọn.
Bakan naa la si ti fi ọrọ akọlu ti wọn ṣe fun Sunday Igboho to ilẹ-ẹjọ agbaye to n ri si iwa ọdaran (International Criminal Court) leti, wọn ti n ṣagbeyẹwo iwe ẹsun ta a kọ.”
Bẹẹ ni Ọjọgbọn Akintoye kadii ọrọ rẹ ninu atẹjade naa.