Aderounmu Kazeem
Ija buruku lo n ṣẹlẹ lọwọ laarin Sẹnetọ Abiọdun Olujimi ati gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ọgbẹni Peter Ayọdele Fayoṣe. Ohun to si n dija ọhun silẹ ko ju ipo ẹni ti yoo duro gẹgẹ bi olori ẹgbẹ PDP ni ipinlẹ naa lọ.
Gomina to dari akoso ipinlẹ Ekiti lẹẹmeji ọtọọtọ ni Ayọdele Fayoṣe n ṣe, bẹẹ lọkunrin ọhun gbagbọ wi pe, ti wọn ba n sọ nipa oloṣelu to ri ẹsẹ fi mulẹ daadaa nipinlẹ ọhun, paapaa laarin awọn mẹkunnu atawọn ko-la-ko-ṣagbe to maa n dibo, ọrẹ araalu loun n ṣe. Fun idi eyi, akoso ẹgbẹ oṣelu PDP, ko yẹ ko sẹni to gbọdọ ba oun du u.
Ni ipinlẹ Ekiti loni-in, eeyan nla ni Sẹnetọ Abiọdun Olujinmi naa n ṣe, bẹẹ oun naa lo ṣe igbakeji Fayoṣe nigba akọkọ tiyẹn ṣe gomina. Ni bayii, ilu Abuja lo ti n ṣofin, ati pe awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lo n ṣoju fun nibẹ.
Bo ti ṣe wa ninu ijọba lasiko yii, bẹẹ loun naa ni ero lẹyin daadaa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP l’Ekiti.
Obinrin yii lo wa si Ekiti, niluu ẹ ni Omuo, ohun to si sọ fawọn eeyan ẹ ni pe, bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ki ẹgbẹ oṣelu naa ma tun padanu ibo gomina lọdun 2022.
O fi kun un pe gbogbo wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa ni yoo fa ijakulẹ ọhun, ti gbogbo kudiẹ-kudiẹ ti awọn kan ti wọn n pe ara wọn ni aṣaaju ẹgbẹ naa n fa, yoo si koba ẹgbẹ ọhun gidigidi.
O ni, gbogbo aṣemaṣe to waye lasiko iyansipo awọn oloye ẹgbẹ ni wọọdu ati nijọba ibilẹ ati eyi ti wọn ṣe fawọn oloye ti yoo maa ṣoju nipinlẹ naa ti sọ ẹgbẹ oṣelu PDP l’Ekiti di korofo, ti ẹgbẹ si ṣe bẹẹ pin si yẹlẹyẹlẹ.
Nigba to n ba awọn agbaagba ẹgbẹ ọhun sọrọ lo fidi ẹ mulẹ wi pe oun ko ni i kaarẹ ọkan lori akitiyan oun lati ri i pe awọn aṣaaju ẹgbẹ naa loke ṣe ohun to yẹ, ki PDP le bọ lọwọ eeyan kan pere to fẹẹ sọ ọ di tiẹ nikanṣoṣo, ki ẹgbẹ ọhun le wa nipo to yẹ.
Sẹnetọ yii tẹ siwaju pe o ṣe pataki ki irẹpọ wa nitori pe, nigba mejeeji ọtọọtọ ti Fayoṣe jawe olubori ibo gomina, gbogbo ẹgbẹ pata lo ṣiṣẹ fun un, ṣugbọn ni bayii ti ẹyọ enikan ṣoṣo n ṣe bii ẹni pe dukia oun lẹgbẹ oṣelu ọhun, ijakulẹ ni yoo mu ba PDP l’Ekiti.
Ṣa o, Olujimi fi kun ọrọ ẹ pe, oun ko ba Ayọdele Fayoṣe ja rara, ṣugbon ohun to ṣe pataki si oun ni bi oun yoo ṣe gba ipinlẹ naa kalẹ lọwọ alagbara to n ri ẹgbẹ oṣelu PDP gẹgẹ bi dukia, to si n ṣe bii alfa ati omega ẹgbẹ awọn.