Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Lẹyin bii ọdun mẹta o le to ti gori aleefa, Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti yi ohun pada pẹlu bo ṣe gba lati bẹbẹ, ko si ko gbogbo awọn tinu n bi ninu ẹgbẹ APC mọra.
Akeredolu sọrọ yii lasiko to n ki alaga igbimọ apẹtusaawọ ẹgbẹ ọhun to tun jẹ gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Bello, kaabọ si ọfiisi rẹ to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
Gomina ọhun rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ tinu n bi ki fọwọ wọnu, ki wọn si jọ ṣiṣẹ pọ ko baa le rọrun fun ẹgbẹ APC lati rọwọ mu ninu eto ibo to n bọ lọjọ kẹwaa, osu kẹwaa, ọdun yii.
O ni idi ree ti oun fi pinnu ati tọrọ idariji lọwọ gbogbo awọn ti oun ti ṣẹ lati ọdun 2017 toun ti de ori aleefa.
Alaga igbimọ olupari ija ọhun ni olori iṣẹ ti awọn asaaju ẹgbẹ gbe le awọn lọwọ ni lati yanju gbogbo ede-aiyede to ba wa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ patapata ki ọjọ idibo too pe.
O ni igbesẹ yii pọn dandan ti ẹgbẹ APC ba fẹẹ jawe olubori lasiko eto idibo naa.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, bii igba meji ọtọọtọ ni Aṣiwaju Bọla Tinubu ti gbe igbesẹ lati pari ija to n waye laarin Akeredolu atawọn agbaagba ẹgbẹ ọhun kan latari magomago ti wọn lo suyọ ninu eto idibo abẹle ti wọn ṣe lọjọ kẹta, oṣu kẹsan-an, ọdun 2016.